Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (1) Surah: Al-Isrā’

Suuratul-Is'raa'

سُبۡحَٰنَ ٱلَّذِيٓ أَسۡرَىٰ بِعَبۡدِهِۦ لَيۡلٗا مِّنَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ إِلَى ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡأَقۡصَا ٱلَّذِي بَٰرَكۡنَا حَوۡلَهُۥ لِنُرِيَهُۥ مِنۡ ءَايَٰتِنَآۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ
Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó mú ẹrúsìn Rẹ̀ ṣe ìrìn-àjò ní alẹ́ láti Mọ́sálásí Haram sí Mọ́sálásí Aƙsọ̄ tí A fi ìbùkún yí ká, nítorí kí Á lè fi nínú àwọn àmì Wa hàn án. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.¹
1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lérò pé àlá lílá ni ìrìn-àjò òru tí Allāhu - subhānahu wa ta ‘ālā - mú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -rìn, ohun tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ jùlọ ni pé, ìrìn-àjò òru náà jẹ́ ìrìn-àjò ẹ̀mí àti ara. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé Allāhu - subhānahu wa ta ‘ālā - kò sọ ọ̀rọ̀ ìrìn-àjò náà ní ìsọ àlá lílá páàpáà. Ẹ wo àgbékalẹ̀ āyah ìrìn-àjò ẹ̀mí àti ara yìí sí àgbékalẹ̀ àwọn āyah àlá lílá wọ̀nyí nínú sūrah Yūsuf; 12:4 & 43, sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:102 àti sūrah al-Fat-h; 48:27.
Bákan náà, ìrìn-àjò náà ìbá jẹ́ àlá lílá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbá tí ṣe àtakò sí i. Àti pé ṣíṣe àtakò sí ìrìn-àjò náà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ nípa bí ìró ìṣẹ̀lẹ̀ ìrìn-àjò òru náà ṣe ga tayọ òye wọn ló kó wọn sínú àdánwò tí Allāhu - subhānahu wa ta ‘ālā - sọ nípa rẹ̀ nínú āyah 60 nínú sūrah yìí.
Kíyè sí i, gbólóhùn “subhān-llathī” ìbá tí bẹ̀rẹ̀ āyah yìí, Tí ó bá jẹ́ pé ìrìn-àjò ojú àlá lásán ni.
Síwájú sí i, àwọn n̄ǹkan pàtàkì pàtàkì ni Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fojú rí nínú àwọn sánmọ̀ àti lókè sánmọ̀ keje lórí ìrìn-àjò òru rẹ̀ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - mú un rìn. Nínú ìrìn-àjò òru náà ni Allāhu sì ti fún un ní àwọn ìrun wákàtí = = márùn-ún. Àmọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò fojú rí Allāhu rárá - subhānahu wa ta‘ālā - ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ ìyá wa ‘Ā’iṣah - kí Allāhu yọ́nú sí i - tí ó sọ pé: “Dájúdájú òpùrọ́ ni ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ pé (Ànábì) Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fojú rí Olúwa rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìyá wa, ‘Ā’iṣah - kí Allāhu yọ́nú sí i - fi sūrah al-’An‘ām; 6:103 àti sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:51 ṣe ẹ̀rí ọ̀rọ̀ náà.” (al-Bukāriy)
Síwájú sí i, àwọn mùsùlùmí, wọ́n ti ń kí ìrun ṣíwájú ìrìn-àjò òru náà, àmọ́ kì í ṣe ìrun wákàtí márùn-ún, kódà kì í ṣe ìrun ọ̀ran-anyàn. Ìrìn-àjò òru àti ìgun-sánmọ̀-lọ Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ló bí ìrun ọ̀ran-anyàn àti ìrun wákàtí márùn-ún ojoojúmọ́.
Síwájú sí i, ọ̀rọ̀ yìí “bi ‘abdih” (ẹrúsìn Rẹ̀). Ẹrúsìn Rẹ̀ nínú āyah yìí kò dúró fún ẹnì kan bí kò ṣe Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Àpẹ̀ẹrẹ àyè mìíràn nìyí: sūrah al-Kahf; 18:1, sūrah al-Furƙọ̄n; 25:1, sūrah az-Zumọr; 39:36, sūrah an-Najm; 53:10 àti sūrah al-Hadīd; 57:9. Àyè ẹyọ kan péré tí “‘abdah” kò ti dúró fún un, Allāhu - subhānahu wa ta ‘ālā - kúkú dárúkọ ẹni tí “‘abdah” dúró fún níbẹ̀. Àyè náà ni sūrah Mọryam; 19:2.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (1) Surah: Al-Isrā’
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close