Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Al-Kahf   Ayah:
وَلَقَدۡ صَرَّفۡنَا فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ لِلنَّاسِ مِن كُلِّ مَثَلٖۚ وَكَانَ ٱلۡإِنسَٰنُ أَكۡثَرَ شَيۡءٖ جَدَلٗا
Dájúdájú A ti ṣe àlàyé oníran-ànran sínú al-Ƙur’ān fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú gbogbo àkàwé. Ènìyàn sì jẹ́ olùjiyàn ju ohunkóhun lọ.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمَا مَنَعَ ٱلنَّاسَ أَن يُؤۡمِنُوٓاْ إِذۡ جَآءَهُمُ ٱلۡهُدَىٰ وَيَسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّهُمۡ إِلَّآ أَن تَأۡتِيَهُمۡ سُنَّةُ ٱلۡأَوَّلِينَ أَوۡ يَأۡتِيَهُمُ ٱلۡعَذَابُ قُبُلٗا
Kò sí ohun tó dí àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti gbàgbọ́ ní òdodo nígbà tí ìmọ̀nà dé bá wọn, (kò sì sí ohun tó dí wọn lọ́wọ́ láti) tọrọ àforíjìn Olúwa wọn, bí kò ṣe pé (wọ́n fẹ́) kí ìṣe (Allāhu nípa ìparun) àwọn ẹni àkọ́kọ́ dé bá àwọn náà tàbí kí ìyà dé bá wọn ní ojúkojú.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمَا نُرۡسِلُ ٱلۡمُرۡسَلِينَ إِلَّا مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَۚ وَيُجَٰدِلُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِٱلۡبَٰطِلِ لِيُدۡحِضُواْ بِهِ ٱلۡحَقَّۖ وَٱتَّخَذُوٓاْ ءَايَٰتِي وَمَآ أُنذِرُواْ هُزُوٗا
Àti pé A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ (lásán) àfi kí wọ́n jẹ́ oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń fi irọ́ ṣàtakò nítorí kí wọ́n lè fi ba òdodo jẹ́. Wọ́n sì sọ àwọn āyah Mi àti ohun tí A fi ṣèkìlọ̀ fún wọn di yẹ̀yẹ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن ذُكِّرَ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِۦ فَأَعۡرَضَ عَنۡهَا وَنَسِيَ مَا قَدَّمَتۡ يَدَاهُۚ إِنَّا جَعَلۡنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ أَكِنَّةً أَن يَفۡقَهُوهُ وَفِيٓ ءَاذَانِهِمۡ وَقۡرٗاۖ وَإِن تَدۡعُهُمۡ إِلَى ٱلۡهُدَىٰ فَلَن يَهۡتَدُوٓاْ إِذًا أَبَدٗا
Ta sì ló ṣàbòsí ju ẹni tí wọ́n fi àwọn āyah Olúwa rẹ̀ ṣèrántí fún, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀, tí ó sì gbàgbé ohun tí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì tì síwájú? Dájúdájú Àwa fi èbìbò bo ọkàn wọn nítorí kí wọ́n má baà gbọ́ ọ yé. A sì fi èdídí sínú etí wọn. Tí ìwọ bá pè wọ́n síbi ìmọ̀nà, nígbà náà wọn kò sì níí mọ̀nà láéláé.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَرَبُّكَ ٱلۡغَفُورُ ذُو ٱلرَّحۡمَةِۖ لَوۡ يُؤَاخِذُهُم بِمَا كَسَبُواْ لَعَجَّلَ لَهُمُ ٱلۡعَذَابَۚ بَل لَّهُم مَّوۡعِدٞ لَّن يَجِدُواْ مِن دُونِهِۦ مَوۡئِلٗا
Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́. Bí ó bá jẹ́ pé Ó máa fi ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ mú wọn ni, ìbá tètè mú ìyà wá fún wọn. Ṣùgbọ́n àkókò àdéhùn (àjíǹde) wà fún wọn. Wọn kò sì níí rí ibùsásí kan lẹ́yìn rẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَتِلۡكَ ٱلۡقُرَىٰٓ أَهۡلَكۡنَٰهُمۡ لَمَّا ظَلَمُواْ وَجَعَلۡنَا لِمَهۡلِكِهِم مَّوۡعِدٗا
Ìwọ́nyí ni àwọn ìlú tí A ti parẹ́ nígbà tí wọ́n ṣàbòsí. A sì fún wọn ní (àkókò) àdéhùn fún ìparun wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِفَتَىٰهُ لَآ أَبۡرَحُ حَتَّىٰٓ أَبۡلُغَ مَجۡمَعَ ٱلۡبَحۡرَيۡنِ أَوۡ أَمۡضِيَ حُقُبٗا
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Èmi kò níí yé rìn títí mo máa fi dé ibi tí odò méjì ti papọ̀ tàbí (títí) mo máa fi lo ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّا بَلَغَا مَجۡمَعَ بَيۡنِهِمَا نَسِيَا حُوتَهُمَا فَٱتَّخَذَ سَبِيلَهُۥ فِي ٱلۡبَحۡرِ سَرَبٗا
Nígbà tí àwọn méjèèjì sì dé ibi tí odò méjèèjì ti papọ̀, wọ́n gbàgbé ẹja wọn. (Ẹja náà) sì sọ ojú ọ̀nà rẹ̀ di poro ọ̀nà nínú odò.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Al-Kahf
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close