Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Al-Hajj   Ayah:
أُذِنَ لِلَّذِينَ يُقَٰتَلُونَ بِأَنَّهُمۡ ظُلِمُواْۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ نَصۡرِهِمۡ لَقَدِيرٌ
A yọ̀ǹda (ogun ẹ̀sìn jíjà) fún àwọn (mùsùlùmí) tí (àwọn kèfèrí) ń gbógun tì nítorí pé (àwọn kèfèrí) ti ṣe àbòsí sí wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí àrànṣe wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
ٱلَّذِينَ أُخۡرِجُواْ مِن دِيَٰرِهِم بِغَيۡرِ حَقٍّ إِلَّآ أَن يَقُولُواْ رَبُّنَا ٱللَّهُۗ وَلَوۡلَا دَفۡعُ ٱللَّهِ ٱلنَّاسَ بَعۡضَهُم بِبَعۡضٖ لَّهُدِّمَتۡ صَوَٰمِعُ وَبِيَعٞ وَصَلَوَٰتٞ وَمَسَٰجِدُ يُذۡكَرُ فِيهَا ٱسۡمُ ٱللَّهِ كَثِيرٗاۗ وَلَيَنصُرَنَّ ٱللَّهُ مَن يَنصُرُهُۥٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَقَوِيٌّ عَزِيزٌ
(Àwọn ni) àwọn tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ìlú wọn ní ọ̀nà àìtọ́ àfi (nítorí pé) wọ́n ń sọ pé: “Allāhu ni Olúwa wa.” Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, wọn ìbá ti wó ilé ìsìn àwọn fadá, ṣọ́ọ̀ṣì, sínágọ́gù àti àwọn mọ́sálásí tí wọ́n ti ń dárúkọ Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.[1] Dájúdájú Allāhu yóò ṣe àrànṣe fún ẹnikẹ́ni tó ń ran (ẹ̀sìn ’Islām) Rẹ̀ lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí.
1. Ó ti rinlẹ̀ nínú sunnah Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pé àwa mùsùlùmí kò gbọdọ̀ da ilé ìsìn àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ wó lulẹ̀ ní àsìkò ogun ẹ̀sìn nítorí pé, àwọn ilé ìsìn náà rọrùn láti sọ di mọ́sálásí.
Arabic explanations of the Qur’an:
ٱلَّذِينَ إِن مَّكَّنَّٰهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ أَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَوُاْ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَمَرُواْ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَنَهَوۡاْ عَنِ ٱلۡمُنكَرِۗ وَلِلَّهِ عَٰقِبَةُ ٱلۡأُمُورِ
(Àwọn náà ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá fún wọn ní ipò lórí ilẹ̀, wọn yóò kírun, wọn yóò yọ Zakāh, wọn yóò pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì kọ ohun burúkú. Ti Allāhu sì ni ìkángun àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدۡ كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٖ وَعَادٞ وَثَمُودُ
Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, àwọn ìjọ Nūh, ìjọ ‘Ād àti ìjọ Thamūd kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ wọn ní òpùrọ́ ṣíwájú wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَقَوۡمُ إِبۡرَٰهِيمَ وَقَوۡمُ لُوطٖ
Àti pé ìjọ ’Ibrọhīm àti ìjọ (Ànábì) Lūt,
Arabic explanations of the Qur’an:
وَأَصۡحَٰبُ مَدۡيَنَۖ وَكُذِّبَ مُوسَىٰۖ فَأَمۡلَيۡتُ لِلۡكَٰفِرِينَ ثُمَّ أَخَذۡتُهُمۡۖ فَكَيۡفَ كَانَ نَكِيرِ
àti àwọn ará ìlú Mọdyan (àwọn náà ṣe bẹ́ẹ̀). Wọ́n tún pe (Ànábì) Mūsā ní òpùrọ́. Mo sì lọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!
Arabic explanations of the Qur’an:
فَكَأَيِّن مِّن قَرۡيَةٍ أَهۡلَكۡنَٰهَا وَهِيَ ظَالِمَةٞ فَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا وَبِئۡرٖ مُّعَطَّلَةٖ وَقَصۡرٖ مَّشِيدٍ
Nítorí náà, mélòó mélòó nínú ìlú tí A ti parẹ́ nígbà tí wọ́n jẹ́ alábòsí; àwọn ilé wọn dàwó lulẹ̀ pẹ̀lú òrùlé rẹ̀. (Mélòó mélòó nínú) kànǹga tí wọ́n ti patì (nípasẹ̀ ìparun) àti ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì oníbíríkì (tó ti dahoro)!
Arabic explanations of the Qur’an:
أَفَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَتَكُونَ لَهُمۡ قُلُوبٞ يَعۡقِلُونَ بِهَآ أَوۡ ءَاذَانٞ يَسۡمَعُونَ بِهَاۖ فَإِنَّهَا لَا تَعۡمَى ٱلۡأَبۡصَٰرُ وَلَٰكِن تَعۡمَى ٱلۡقُلُوبُ ٱلَّتِي فِي ٱلصُّدُورِ
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n sì ní àwọn ọkàn tí wọ́n máa fi ṣe làákàyè tàbí àwọn etí tí wọn máa fi gbọ́rọ̀? Dájúdájú àwọn ojú kò fọ́, ṣùgbọ́n àwọn ọkàn tó wà nínú igbá-àyà ló ń fọ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Al-Hajj
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close