Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (144) Surah: Āl-‘Imrān
وَمَا مُحَمَّدٌ إِلَّا رَسُولٞ قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلِهِ ٱلرُّسُلُۚ أَفَإِيْن مَّاتَ أَوۡ قُتِلَ ٱنقَلَبۡتُمۡ عَلَىٰٓ أَعۡقَٰبِكُمۡۚ وَمَن يَنقَلِبۡ عَلَىٰ عَقِبَيۡهِ فَلَن يَضُرَّ ٱللَّهَ شَيۡـٔٗاۚ وَسَيَجۡزِي ٱللَّهُ ٱلشَّٰكِرِينَ
Kí ni (Ànábì) Muhammad bí kò ṣe Òjíṣẹ́, tí àwọn Òjíṣẹ́ kan ti lọ ṣíwájú rẹ̀.¹ Ṣé tí ó bá kú tàbí tí wọ́n bá pa á, ẹ máa pẹ̀yìndà (sẹ́sìn)? Ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìndà (sẹ́sìn) kò lè kó ìnira kan kan bá Allāhu. Allāhu yó sì san àwọn olùdúpẹ́ ní ẹ̀san rere.
1. Āyah yìí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ẹ̀rí àtamọ́-àtọmọ̀ lọ́dọ̀ àwọn tó gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti kú. Wọ́n ní ikú rẹ̀ ti jẹyọ nínú “Kí ni (Ànábì) Muhammad bí kò ṣe Òjíṣẹ́, tí àwọn Òjíṣẹ́ kan ti lọ ṣíwájú rẹ̀”
Èsì: Āyah yìí jẹ́ àpẹ̀ẹrẹ àwọn āyah tí àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ń pè ní nassun ‘āmmun maksūs “ọ̀rọ̀ gbogbogbò tó ní àyàfi”. Ìyẹn ni pé, wọ́n mú un wá bí ẹni pé gbogbo àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ ló ti kú, àmọ́ tí ó jẹ́ pé, Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - jẹ́ àyàfi nítorí pé, àwọn ọ̀rọ̀ (nusūs) mìíràn wá nínú hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tí ó fi rinlẹ̀ pé, kò ì kú, ó ń padà bọ̀. Kì í sì ṣe ohun titun kí ọ̀rọ̀ jẹ́ “ọ̀rọ̀ gbogbogbò tó ní àyàfi”. Àti pé, hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ló ń ṣàlàyé al-Ƙur’ān. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé āyah náà ń sọ̀rọ̀ nípa ikú àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - tó ṣíwájú Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, kò pọn dandan kí āyah náà yà lọ síbi ọ̀rọ̀ nípa àì tí ì kú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -.
Ẹ kíyè sí i, bí ọ̀rọ̀ bá wá ní àwòrán gbogbogbò nínú al-Ƙur’ān, kò túmọ̀ sí pé kò lè ní àyàfi nínú nínú āyah mìíràn tàbí nínú hadīth Ànábì tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀. Bí àpẹ̀ẹrẹ, nínú sūrah an-Nisā’; 4:117, Allāhu ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn n̄ǹkan tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Rẹ̀ pé, “Wọn kò pe kiní kan lẹ́yìn Allāhu bí kò ṣe àwọn abo òrìṣà.” Nínú ohun tí àwọn kan sì sọ di òrìṣà ni Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ṣé abo sì ni òun náà ni tàbí akọ? Ìsọkúsọ l’ó sì máa jẹ́ láti pe Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ní abo. Bẹ́ẹ̀ sì ni pé, Allāhu kò ṣe “àyàfi” nínú āyah “abo òrìṣà”, àmọ́ ó yé wa nínú àwọn āyah mìíràn pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - kì í ṣe abo. Akọ ni.
Àpẹ̀ẹrẹ mìíràn fún mímú “àyàfi” fún āyah al-Ƙur’ān wá nínú hadīth, òhun ni pé al-Ƙur’ān sọ pé kí á gé ọwọ́ olè lọ́kùnrin àti ọwọ́ olè lóbìnrin. Ọwọ́ sì lè dúrò fún gbogbo ọwọ́, bẹ̀rẹ̀ láti èjìká títí dé àtẹlẹwọ́. Hadīth ló yọ èjìká ọwọ́ títí dé ọrùn ọwọ́ sílẹ̀ níbi gígé.
Nítorí náà, kò sí ohun tó sọ ọ́ di dandan nínú āyah òkè yìí láti sọ pé “Kí ni (Ànábì) Muhammad bí kò ṣe Òjíṣẹ́, tí àwọn Òjíṣẹ́ kan ti lọ ṣíwájú rẹ̀ (àyàfi ‘Īsā ọmọ Mọryam).” Níwọ̀n ìgbà tí hadīth ti wà ní ipò àlàyé fún al-Ƙur’ān. Méjèèjì sì ni ìmísí láti ọ̀dọ̀ Allāhu, àmọ́ ipò ìmísí al-Ƙur’ān ju ipò ìmísí hadīth tó dára tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (144) Surah: Āl-‘Imrān
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close