Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (44) Surah: Āl-‘Imrān
ذَٰلِكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلۡغَيۡبِ نُوحِيهِ إِلَيۡكَۚ وَمَا كُنتَ لَدَيۡهِمۡ إِذۡ يُلۡقُونَ أَقۡلَٰمَهُمۡ أَيُّهُمۡ يَكۡفُلُ مَرۡيَمَ وَمَا كُنتَ لَدَيۡهِمۡ إِذۡ يَخۡتَصِمُونَ
Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi ìmísí rẹ̀ ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ kò kúkú sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ju gègé wọn (sínú odò láti mọ) ta ni nínú wọn ni ó máa gba Mọryam wò.¹ Ìwọ kò sì sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ṣe ìfàn̄fà (lórí rẹ̀).
1. Olúkùlùkù wọn kọ orúkọ rẹ̀ sára gègé rẹ̀. Wọ́n dá gègé wọn jọ, wọ́n dà wọ́n sínú odò. Odò gbé gbogbo gègé wọn lọ àfi gègé ti Zakariyā’ - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Wọ́n sì gbé Mọryam fún Ànábì Zakariyā’ - kí ọlà Allāhu máa bá a - gẹ́gẹ́ bí alágbàwò rẹ̀. Àwòrán ƙur‘ah ṣíṣe kan nìyí. Ẹ tún wo àwòrán mìíràn nínú Sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:140-141. Èyí ni à ń pè ní “ƙur‘ah”. Ṣíṣe ƙur‘ah máa ń wáyé nígbà tí òǹkà ènìyàn tí ó fẹ́ ṣe n̄ǹkan kan bá pọ̀ ju n̄ǹkan náà. Ƙur‘ah ṣíṣe sì jẹ́ sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ƙur‘ah kò sì ní n̄ǹkan kan ṣepọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ nípa kádàrá àwọn ènìyàn. Èyíkéyìí ọ̀nà tí àwọn ènìyàn bá lérò pé àwọn lè gbà mọ kádàrá ènìyàn ni Islām ṣe ní èèwọ̀ àti n̄ǹkan tí ó ń ba ẹ̀sìn jẹ́ mọ́ mùsùlùmí lọ́wọ́. Ẹ wo sūrah al-Mọ̄’idah; 5:3 àti 90. Ẹ tún wo àpèjúwe ƙur‘ah ṣíṣe nínú sūrah as-Sọ̄ffāt 37:139 - 142. “ƙur‘ah” yàtọ̀ sí aje mímu. Ìlànà èṣù ti wọ́n ń fi mú olè ni aje mímu. Wọn kì í fi “ƙur‘ah” mú olè rárá. Nítorí náà, “ƙur‘ah” àti aje mímu kò jọra wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (44) Surah: Āl-‘Imrān
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close