Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (72) Surah: Āl-‘Imrān
وَقَالَت طَّآئِفَةٞ مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ ءَامِنُواْ بِٱلَّذِيٓ أُنزِلَ عَلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَجۡهَ ٱلنَّهَارِ وَٱكۡفُرُوٓاْ ءَاخِرَهُۥ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ
Igun kan nínú àwọn onítírà wí pé: “Ẹ lọ gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́, kí ẹ sì takò ó níparí rẹ̀, bóyá àwọn mùsùlùmí (kan) máa ṣẹ́rí padà (sẹ́yìn nínú ẹ̀sìn ’Islām).¹
1. Èyí jẹ́ ète kan nínú àwọn ète tí àwọn ahlul-kitāb ń lò. Ète náà ni pé, àwọn kan nínú wọn máa kó sínú ẹ̀sìn ’Islām ní àsìkò kan. Wọn kò sì níí ’Islām í ṣe nítorí pé àìgbàgbọ́ kò yé bá wọn fínra nínú ọkàn wọn, gẹ́gẹ́ bí Allāhu - subhānahu wa ta ‘ālā - ṣe fìdí èyí rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:61.
Àmọ́ tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, wọ́n kó sínú ’Islām ní àsìkò náà nítorí kí wọ́n lè padà kéde pé àwọn kò ṣe ’Islām mọ́. Irú àwọn wọ̀nyí ni wọ́n sọra wọn di “akéúgbajésù”. Ìjàǹbá kan nínú àwọn ìjàǹbá tí ahlul-kitāb ń ṣe fún àwa Mùsùlùmí ni èyí. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi ṣẹ́rí àwọn tí ìgbàgbọ́ òdodo wọn nínú Allāhu kò ì rinlẹ̀ dáadáa àti àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ gba ẹ̀sìn ’Islām. Kí irú àwọn wọ̀nyí lè máa wí pé: “Tí kò bá jẹ́ pé irọ́ wà nínú ’Islām ni, lágbájá àti tàmẹ̀dùn kò níí di akéúgbajésù.” Kò sì sí lágbájá àti tàmẹ̀dùn kan tó sọra wọn di akéúgbajésù bí kò ṣe àwọn oníjàǹbá. Àti pé, èdè ni kéú, ìmọ̀ ẹ̀sìn ni al-Ƙur’ān àti hadīth. Àwọn oníjàǹbá wọ̀nyí kì í ṣe onímọ̀ ẹ̀sìn. Ìdí nìyí tí ẹ̀yin kò fi lè rí akéúgbajésù kan tí ó lè ko mùsùlùmí onímọ̀ ẹ̀sìn lójú, kí ó sì lékè. Láéláé, kò lè ṣẹlẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe gbẹ̀tàn. ’Islām nìkan ṣoṣo ni òdodo. Ìṣìnà pọ́nńbélé ni gbogbo ẹ̀sìn yòókù pátápátá.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (72) Surah: Āl-‘Imrān
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close