Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (34) Surah: Al-Ahzāb
وَٱذۡكُرۡنَ مَا يُتۡلَىٰ فِي بُيُوتِكُنَّ مِنۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ وَٱلۡحِكۡمَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ لَطِيفًا خَبِيرًا
Ẹ rántí ohun tí wọ́n ń ké nínú ilé yín nínú àwọn āyah Allāhu àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀.¹
1. Àwọn àkíyèsí méjì kan ń bẹ lára gbogbo gbólóhùn àṣẹ tí ó wà nínú sūrah yìí láti āyah 28 sí 34. Àkíyèsí kìíní ni pé, àwọn tí Allāhu - tó ga jùlọ - dojú àwọn àṣẹ náà kọ ni àwọn ìyàwó Ànábì - kí Allāhu yọ́nú sí wọn -, ṣùgbọ́n kò sí àṣẹ kan nínú rẹ̀ tí ó yọ àwọn mùsùlùmí lóbìnrin yòókù sílẹ̀. Ìdí ni pé, àgbékalẹ̀ àwọn àṣẹ náà dúró fún gbígbèrò gbogbogbò pẹ̀lú dídojú-ọ̀rọ̀ kọ aṣíwájú. Nítorí náà, ẹ wo ìṣerẹ́gí láààrin gbólóhùn yìí “Ẹ má ṣe fi ara àti ọ̀ṣọ́ hàn níta gẹ́gẹ́ bí ti ìfara-fọ̀ṣọ́-hàn ìgbà àìmọ̀kan àkọ́kọ́ (ìyẹn, ṣíwájú kí ẹ tó di mùsùlùmí)...” àti gbólóhùn yìí “Kí wọ́n má ṣe ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀…” èyí tí ó wà nínú sūrah an-Nūr; 24:31.
Àkíyèsí kejì ni pé, èdè Lárúbáwá jẹ́ èdè jẹ́ńdà. Èdè jẹ́ńdà ni èdè tó ni ìhun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún akọ àti abo. Ìyẹn ni pé, tí Lárúbáwá bá ń d’ojú ọ̀rọ̀ kọ ọkùnrin tàbí n̄ǹkan akọ tàbí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin tàbí n̄ǹkan akọ, èdè Lárúbáwá ti ní ìhun akọ fún akọ. Bákan náà, tí Lárúbáwá bá ń d’ojú ọ̀rọ̀ kọ obìnrin tàbí n̄ǹkan abo tàbí ó ń sọ̀rọ̀ nípa obìnrin tàbí n̄ǹkan abo, èdè Lárúbáwá ti ní ìhun abo fún abo. Irúfẹ́ àbùdá yìí kò sí fún èdè Yorùbá. Ìhun akọ kò yàtọ̀ sí ìhun abo.
Nítorí náà, gbogbo àwọn gbólóhùn àṣẹ tí Allāhu - tó ga jùlọ - mú wá nínú sūrah yìí láti āyah 28 sí 34 jẹ́ gbólóhùn àṣẹ fún ìhun abo nítorí pé, àwọn obìnrin ni Allāhu - tó ga jùlọ - ń sọ nípa wọn. Àwọn sì ni Ó ń dojú gbólóhùn àṣẹ náà kọ.
Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí a fẹ́ rí kọ́ nínú èyí ni pé, bí Allāhu - tó ga jùlọ - ṣe pàṣẹ ìjọ́sìn fún àwọn ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ náà ni Ó ṣe pàṣẹ rẹ̀ fún àwọn obìnrin. Àti pé èèwọ̀ ni ohunkóhun tí ó bá lè sọ mùsùlùmí lóbìnrin di aláìgbàgbọ́ nípasẹ̀ níní ọkọ nítorí pé, obìnrin ní ẹ̀sìn. ’Islām sì ni ẹ̀sìn rẹ̀, ẹ̀sìn Allāhu. Ẹ̀rí apayànjẹ (= ẹ̀rí tó ń pa iyàn jíjà jẹ / ẹ̀rí tí kò ṣe é jà níyàn) ni bí Allāhu - tó ga jùlọ - ṣe ń sọ nípa ẹ̀san àwọn olújọ́sìn; Ó ń sọ ọ́ pẹ̀lú ìhun akọ àti ìhun abo láì fi àwọn obìnrin ṣe olùjọ́sìn afarahẹ. Ẹ wo āyah 35 nínú sūrah yìí àti sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:195, sūrah an-Nisā’; 4:124, sūrah an-Nahl; 16:97, sūrah Gọ̄fir; 40:40 àti sūrah al-Hujurāt; 49:13.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (34) Surah: Al-Ahzāb
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close