Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Ghāfir   Ayah:
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا رُسُلٗا مِّن قَبۡلِكَ مِنۡهُم مَّن قَصَصۡنَا عَلَيۡكَ وَمِنۡهُم مَّن لَّمۡ نَقۡصُصۡ عَلَيۡكَۗ وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَن يَأۡتِيَ بِـَٔايَةٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ فَإِذَا جَآءَ أَمۡرُ ٱللَّهِ قُضِيَ بِٱلۡحَقِّ وَخَسِرَ هُنَالِكَ ٱلۡمُبۡطِلُونَ
Àti pé A kúkú ti rán àwọn Òjísẹ́ níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. Àwọn tí A sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àwọn tí A kò sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àti pé kò tọ́ fún Òjísẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Nígbà tí àṣẹ Allāhu bá sì dé, A máa fi òdodo dájọ́. Àwọn òpùrọ́ sì máa ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah ar-Ra‘d; 13:38 lórí ìtúmọ̀ “àmì”.
Arabic explanations of the Qur’an:
ٱللَّهُ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَنۡعَٰمَ لِتَرۡكَبُواْ مِنۡهَا وَمِنۡهَا تَأۡكُلُونَ
Allāhu ni Ẹni tí Ó dá àwọn ẹran-ọ̀sìn fún yín nítorí kí ẹ lè máa gùn nínú wọn. Ẹ ó sì máa jẹ nínú wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَكُمۡ فِيهَا مَنَٰفِعُ وَلِتَبۡلُغُواْ عَلَيۡهَا حَاجَةٗ فِي صُدُورِكُمۡ وَعَلَيۡهَا وَعَلَى ٱلۡفُلۡكِ تُحۡمَلُونَ
Àwọn àǹfààní (mìíràn) wà fún yín lára ẹran-ọ̀sìn. Àti nítorí kí ẹ lè dé ọ̀nà jíjìn tó wà lọ́kàn yín lórí (gígùn) wọ́n (kiri). Ẹ sì ń fi àwọn (ẹran-ọ̀sìn) àti ọkọ̀ ojú-omi gbé àwọn ẹrù.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَيُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ فَأَيَّ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ تُنكِرُونَ
(Allāhu) ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Nítorí náà, èwo nínú àwọn àmì Allāhu l’ẹ máa takò?[1]
[1] Kíyè sí i! Àwọn asòòkùn sẹ́sìn àti àwọn onibidiah yóò máa pe iṣẹ́ aburú ọwọ́ wọn nípasẹ̀ idán pípa àti bidiah ṣíṣe ní “àmì Allāhu” láti lè ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà. Kíyè sí i, ohunkóhun tí ó bá máa jẹ́ “àmì Allāhu / àmì Ọlọ́hun” kò níí fi ọ̀nà kan kan lòdì sí “āyah” kan kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé.
Arabic explanations of the Qur’an:
أَفَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَانُوٓاْ أَكۡثَرَ مِنۡهُمۡ وَأَشَدَّ قُوَّةٗ وَءَاثَارٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n pọ̀ (ní òǹkà) jù wọ́n lọ. Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀(fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà).
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّا جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَرِحُواْ بِمَا عِندَهُم مِّنَ ٱلۡعِلۡمِ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn, wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ nítorí ohun tó wà lọ́dọ̀ wọn nínú ìmọ̀ (ayé). Ohun tí wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí wọn po.
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّا رَأَوۡاْ بَأۡسَنَا قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَحۡدَهُۥ وَكَفَرۡنَا بِمَا كُنَّا بِهِۦ مُشۡرِكِينَ
Nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa, wọ́n wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. A sì lòdì sí n̄ǹkan tí a sọ di akẹgbẹ́ fún Un.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمۡ يَكُ يَنفَعُهُمۡ إِيمَٰنُهُمۡ لَمَّا رَأَوۡاْ بَأۡسَنَاۖ سُنَّتَ ٱللَّهِ ٱلَّتِي قَدۡ خَلَتۡ فِي عِبَادِهِۦۖ وَخَسِرَ هُنَالِكَ ٱلۡكَٰفِرُونَ
Ìgbàgbọ́ wọn kò sì ṣe wọ́n ní àǹfààní nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa. Ìṣe Allāhu, èyí tí ó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú sí àwọn ẹrú Rẹ̀ (ni èyí). Àwọn aláìgbàgbọ́ sì ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Ghāfir
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close