Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (29) Surah: Al-Fat'h
مُّحَمَّدٞ رَّسُولُ ٱللَّهِۚ وَٱلَّذِينَ مَعَهُۥٓ أَشِدَّآءُ عَلَى ٱلۡكُفَّارِ رُحَمَآءُ بَيۡنَهُمۡۖ تَرَىٰهُمۡ رُكَّعٗا سُجَّدٗا يَبۡتَغُونَ فَضۡلٗا مِّنَ ٱللَّهِ وَرِضۡوَٰنٗاۖ سِيمَاهُمۡ فِي وُجُوهِهِم مِّنۡ أَثَرِ ٱلسُّجُودِۚ ذَٰلِكَ مَثَلُهُمۡ فِي ٱلتَّوۡرَىٰةِۚ وَمَثَلُهُمۡ فِي ٱلۡإِنجِيلِ كَزَرۡعٍ أَخۡرَجَ شَطۡـَٔهُۥ فَـَٔازَرَهُۥ فَٱسۡتَغۡلَظَ فَٱسۡتَوَىٰ عَلَىٰ سُوقِهِۦ يُعۡجِبُ ٱلزُّرَّاعَ لِيَغِيظَ بِهِمُ ٱلۡكُفَّارَۗ وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ مِنۡهُم مَّغۡفِرَةٗ وَأَجۡرًا عَظِيمَۢا
Muhammad ni Òjíṣẹ́ Allāhu. Àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n le mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́, aláàánú sì ni wọ́n láààrin ara wọn. O máa rí wọn ní olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀ (lórí ìrun), tí wọ́n ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Àmì wọn wà ní ojú wọn níbi orípa ìforíkanlẹ̀. Ìyẹn ni àpèjúwe wọn nínú Taorāh àti àpèjúwe wọn nínú ’Injīl, (wọ́n dà) gẹ́gẹ́ bí irúgbìn kan tó yọ ẹ̀ka rẹ̀ jáde. Lẹ́yìn náà, ó fún un lágbára, ó nípọn, ó sì dúró gbagidi lórí igi rẹ̀. Ó sì ń jọ àwọn àgbẹ̀ lójú. (Allāhu fi àyè gba Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti àwọn Sọhābah rẹ̀) nítorí kí Ó lè fi wọ́n ṣe ohun ìbínú fún àwọn aláìgbàgbọ́. Allāhu ṣàdéhùn àforíjìn àti ẹ̀san ńlá fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere nínú wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (29) Surah: Al-Fat'h
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close