Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (32) Surah: Al-Mā’idah
مِنۡ أَجۡلِ ذَٰلِكَ كَتَبۡنَا عَلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ أَنَّهُۥ مَن قَتَلَ نَفۡسَۢا بِغَيۡرِ نَفۡسٍ أَوۡ فَسَادٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَكَأَنَّمَا قَتَلَ ٱلنَّاسَ جَمِيعٗا وَمَنۡ أَحۡيَاهَا فَكَأَنَّمَآ أَحۡيَا ٱلنَّاسَ جَمِيعٗاۚ وَلَقَدۡ جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُنَا بِٱلۡبَيِّنَٰتِ ثُمَّ إِنَّ كَثِيرٗا مِّنۡهُم بَعۡدَ ذَٰلِكَ فِي ٱلۡأَرۡضِ لَمُسۡرِفُونَ
Nítorí ìyẹn, A sì ṣe é ní òfin fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pé, dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹ̀mí (ènìyàn) kan láìjẹ́ nítorí pípa ẹ̀mí (ènìyàn) kan tàbí ṣíṣe ìbàjẹ́ kan lórí ilẹ̀¹, ó dà bí ẹni tí ó pa gbogbo ènìyàn pátápátá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú ẹ̀mí (ènìyàn) ṣẹ̀mí, ó dà bí ẹni tí ó mú gbogbo ènìyàn ṣẹ̀mí pátápátá. Àwọn Òjíṣẹ́ Wa sì ti wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. Lẹ́yìn náà, dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn lẹ́yìn ìyẹn ni alákọyọ lórí ilẹ̀.
1. Ìbàjẹ́ ṣíṣe lórí ilẹ̀ pé oríṣiríṣi. Nítorí náà, àwọn ìbàjẹ́ kan wà tí ó jẹ́ pé pípa ọ̀daràn ni ìjìyà rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni pé, àwọn ìbàjẹ́ kan wà tí ìjìyà wọn kò wọ ipò pípa ọ̀daràn. Nínú ìbàjẹ́ tí ìjìyà rẹ̀ wọ pípa ọ̀daràn ni ó jẹyọ nínú hadīth yìí:
عَنْ عَبْدِ اللَّهِ قَالَ قَالَ رَسُولُ اللَّهِ -صلى الله عليه وسلم- « لاَ يَحِلُّ دَمُ امْرِئٍ مُسْلِمٍ يَشْهَدُ أَنْ لاَ إِلَهَ إِلاَّ اللَّهُ وَأَنِّى رَسُولُ اللَّهِ إِلاَّ بِإِحْدَى ثَلاَثٍ الثَّيِّبُ الزَّانِ وَالنَّفْسُ بِالنَّفْسِ وَالتَّارِكُ لِدِينِهِ الْمُفَارِقُ لِلْجَمَاعَةِ ». Láti ọ̀dọ̀ ‘Abdullāh - kí Allāhu yọ́nú sí i -, ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé, “Ẹ̀jẹ̀ ènìyàn tí ó jẹ́ mùsùlùmí kò lẹ́tọ̀ọ́ (kò lẹ́tọ̀ọ́ láti pa mùsùlùmí kan) tí ó ń jẹ́rìí pé “kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu, àti pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu ni mí” àfi nítorí ọ̀kan nínú àwọn n̄ǹkan mẹ́ta (wọ̀nyí): ẹni tí ó ti ṣe ìgbéyàwó rí tí ó lọ ṣe sìná (wọ́n máa lẹ̀ ẹ́ lókò pa), ẹ̀mí (olùpànìyàn) fún ẹ̀mí (ènìyàn tí ó pa) àti ẹni tí ó gbé ẹ̀sìn ’Islām rẹ̀ jù sílẹ̀, tí ó fi ìjọ mùsùlùmí sílẹ̀.” (Muslim àti Bukọ̄riy ló gbà á wá.)
Kíyè sí i, ẹni tí ó gbé ẹ̀sìn ’Islām rẹ̀ jù sílẹ̀ fẹ́ gbógun ti gbogbo ìjọ mùsùlùmí, ó sì fẹ́ sọ ara di alákòóbá fún ìran rẹ̀ ni. Nítorí náà, ọ̀ràn rẹ̀ ti wọ ipò ẹni tí ó di ọ̀tẹ̀ mọ́ ìjọba ’Islām lórí ilẹ̀ ’Islām. Pípa ni ìjìyà rẹ̀ láyé. Iná gbére sì ni ìyà rẹ̀ ní ọ̀run.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (32) Surah: Al-Mā’idah
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close