Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (13) Surah: An-Najm
وَلَقَدۡ رَءَاهُ نَزۡلَةً أُخۡرَىٰ
Àti pé dájúdájú ó tún rí i nígbà kejì¹
1. Gbólóhùn “rọ’āhu” jẹyọ nínú āyah yìí. Ó tún jẹyọ bẹ́ẹ̀ nínú sūrah at-Takwīr; 81:23. Ìtúmọ̀ rẹ̀ sì ni pé, “Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - rí i.” Ta ni ó rí? Ṣé Allāhu ni tàbí mọlāika Jibrīl? Àní sẹ́, ta ni ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ ẹnì kẹta yìí “hu” tó jẹyọ nínú gbólóhùn yìí ń tọ́ka sí? Kí á má gbàgbé pé āyah yẹn ń sọ̀rọ̀ nípa ìrìn-àjò òru àti ìgun sánmọ̀ tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ṣe ni.
Èsì: Àwọn igun kan nínú àwọn àáfà sọ pé, mọlāika Jibrīl ni Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - rí. Igun kejì sì sọ pé, Allāhu - tó ga jùlọ - ni ó rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igun yìí fi kún un pé ọkàn l’ó fi rí Allāhu, kì í ṣe ojú. Ṣebí bí ẹ̀dá ṣe ní ojú ìta, ni ó ní ojú inú. Àmọ́ èyí tí ó gbéwọ̀n jùlọ lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām ni pé, orúkọ mọlāika Jibrīl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni “hu” yẹn ń rọ́pò.
Ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ ni hadīth tí ìyá wa ‘Ā’iṣah - kí Allāhu yọ́nú sí i - gbàwá lórí ọ̀rọ̀ náà pé, “Èmi ni àkọ́kọ́ nínú ìjọ yìí tí ó béèrè nípa ìyẹn lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ó sì sọ pé. “Jibrīl ni mo rí.” (Muslim).
Bákan náà, nínú ẹ̀gbàwá Abū Tharr - kí Allāhu yọ́nú sí i -, ó sọ pé, mo bi Òjíṣẹ́ Allāhu ní ìbéèrè pé, “Ṣé o fojú rí Olúwa rẹ bí?” Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì sọ pé: “Ìmọ́lẹ̀ kan (dí mi lọ́wọ́), báwo ni mo ṣe máa rí I nígbà náà!” (Muslim)
Irú èyí náà l’ó ṣẹlẹ̀ sí Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:143.
Tọ́ọ̀, ó ṣeé ṣe kí á rí ọ̀rọ̀ mìíràn kan láti ọ̀dọ̀ àwọn Sọhābah - kí Allāhu yọ́nú sí wọn -, bíi ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀dọ̀ Ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí i - wá pé, “Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fi ọkàn rẹ̀ rí Allāhu ni.” Ìyẹn ni pé, ó fojú inú rí I, kì í ṣe ojú ìta.
Kíyè sí i, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó lágbára tó èyí tí ó tọ̀dọ̀ Ànábì fúnra rẹ̀ wá tààrà lórí ọ̀rọ̀ náà. Ẹ̀gbàwá ‘Ā’iṣah àti ẹ̀gbàwá Abū Tharr sì ni ẹ̀gbàwá tó ti ọ̀dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - wá lórí ọ̀rọ̀ náà. Má ṣe fọkàn sí ibò míìràn. Àti pé, sūrah al-’Ani‘ām; 6:103 àti sūrah aṣ-Ṣūrā; 42:51 ti fi rinlẹ̀ pé, ojú kan kò lè fojú rinjú pẹ̀lú Allāhu, yálà fún gbígba iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Allāhu tàbí fún n̄ǹkan mìíràn.
Àmọ́ sá, rírí Allāhu sójú máa wáyé fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nìkan lọ́jọ́ Àjíǹde. Èyí sì wà ní ìbámu sí sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:22 - 23.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (13) Surah: An-Najm
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close