Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Al-Hashr   Ayah:

Al-Hash'r

سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Arabic explanations of the Qur’an:
هُوَ ٱلَّذِيٓ أَخۡرَجَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ مِن دِيَٰرِهِمۡ لِأَوَّلِ ٱلۡحَشۡرِۚ مَا ظَنَنتُمۡ أَن يَخۡرُجُواْۖ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُم مَّانِعَتُهُمۡ حُصُونُهُم مِّنَ ٱللَّهِ فَأَتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِنۡ حَيۡثُ لَمۡ يَحۡتَسِبُواْۖ وَقَذَفَ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلرُّعۡبَۚ يُخۡرِبُونَ بُيُوتَهُم بِأَيۡدِيهِمۡ وَأَيۡدِي ٱلۡمُؤۡمِنِينَ فَٱعۡتَبِرُواْ يَٰٓأُوْلِي ٱلۡأَبۡصَٰرِ
Òun ni Ẹni tí Ó mú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn onítírà[1] jáde kúrò nínú ilé wọn fún àkọ́kọ́ àkójọ (wọ́n sínú ìlú Ṣām). Ẹ̀yin kò lérò pé wọn yóò jáde. Àwọn náà sì lérò pé dájúdájú àwọn odi ilé wọn yóò dáàbò bo àwọn lọ́dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n Allāhu wá bá wọn ní ibi tí wọn kò ti lérò; Allāhu sì ju ìbẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Wọ́n ń fi ọwọ́ ara wọn àti ọwọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo wó àwọn ilé wọn. Nítorí náà, ẹ wòye, ẹ̀yin tí ẹ ní ojú ìríran.
[1] Ìyẹn àwọn Yẹhudi ọmọ Nadīr.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَوۡلَآ أَن كَتَبَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمُ ٱلۡجَلَآءَ لَعَذَّبَهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابُ ٱلنَّارِ
Àti pé tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ti kọ ìjáde kúrò nínú ìlú Mọdīnah lé àwọn onítírà lórí ni, dájúdájú (Allāhu) ìbá jẹ wọ́n níyà nílé ayé. Ìyà Iná sì tún wà fún wọn ní ọ̀run.[1]
[1] Ìyẹn ni pé, tí àwọn onítírà kò bá fi ìlú Mọdīnah sílẹ̀ fún àwọn mùsùlùmí ni, ẹ̀mí wọn ìbá lọ sí i nítorí pé, wọ́n ti da àwọn mùsùlùmí.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Al-Hashr
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close