Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (121) Surah: Al-An‘ām
وَلَا تَأۡكُلُواْ مِمَّا لَمۡ يُذۡكَرِ ٱسۡمُ ٱللَّهِ عَلَيۡهِ وَإِنَّهُۥ لَفِسۡقٞۗ وَإِنَّ ٱلشَّيَٰطِينَ لَيُوحُونَ إِلَىٰٓ أَوۡلِيَآئِهِمۡ لِيُجَٰدِلُوكُمۡۖ وَإِنۡ أَطَعۡتُمُوهُمۡ إِنَّكُمۡ لَمُشۡرِكُونَ
Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ jẹ nínú ohun tí wọn kò fi orúkọ Allāhu pa.¹ Dájúdájú ìbàjẹ́ ni. Àti pé dájúdájú àwọn èṣù, wọn yóò máa fi ọ̀rọ̀ irọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ẹni wọn, nítorí kí wọ́n lè takò yín. Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé wọn, dájúdájú ẹ ti di ọ̀ṣẹbọ.
1. Méjì ni ẹran tí wọn kò fi orúkọ Allāhu pa. Ìkíní: ẹran tí wọ́n fi orúkọ mìíràn yàtọ̀ sí orúkọ Allāhu pa, èèwọ̀ ni. Ìkejì: ẹran tí mùsùlùmí pa, àmọ́ tí ó gbàgbé láti fi orúkọ Allāhu pa á, wọ́n ṣàmójú kúrò fún un, ẹ̀tọ́ sì ni ẹran náà. Àmọ́ ìyapa-ẹnu wà lórí jíjẹ ẹran náà bí ó bá jẹ́ pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣàì fi orúkọ Allāhu pa á ni.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (121) Surah: Al-An‘ām
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close