Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (14) Surah: Al-An‘ām
قُلۡ أَغَيۡرَ ٱللَّهِ أَتَّخِذُ وَلِيّٗا فَاطِرِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَهُوَ يُطۡعِمُ وَلَا يُطۡعَمُۗ قُلۡ إِنِّيٓ أُمِرۡتُ أَنۡ أَكُونَ أَوَّلَ مَنۡ أَسۡلَمَۖ وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ
Sọ pé: “Ṣé kí n̄g mú olùrànlọ́wọ́ kan yàtọ̀ sí Allāhu, Ẹlẹ́dàá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Òun sì ni Ó ń bọ́ (ẹ̀dá), wọn kì í bọ́ Ọ.” Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n pa mí láṣẹ pé kí n̄g jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣe ’Islām (ní àsìkò tèmi).”¹ Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
Irú āyah yìí wà níwájú ní āyah 163. Ó tún wà nínú sūrah az-Zumọr; 39:12. Kíyè sí i, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bá ’Islām láyé ni, kì í ṣe òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe ’Islām nítorí pé, ’Islām ni ẹ̀sìn tí gbogbo àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - tó ṣíwájú rẹ̀ ṣe. Àmọ́ nínú ìjọ tirẹ̀, òun ni ẹni àkọ́kọ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Bákan náà, bí ìkọ̀ọ̀kan àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - ṣe máa ń sọ nìyẹn nínú ìjọ kóówá wọn ní ìgbà kóówá wọn gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7: 143. Nítorí náà, Ànábì kọ̀ọ̀kan ní ẹni àkọ́kọ́ onígbàgbọ́ òdodo nínú ìjọ rẹ̀. Kódà fún wí pé nínú ìjọ Fir‘aon, àwọn òpìdán rẹ̀ ni àwọn tó kọ́kọ́ gbàgbọ́ ní òdodo, l’ó mú àwọn náà pe ara wọn ní ẹni àkọ́kọ́ onígbàgbọ́ òdodo, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú sūrah aṣ-Ṣu‘arā’; 26:51.
Síwájú sí i, nígbà tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ń kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ aláìgbàgbọ́, ìyẹn nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:41, wọ́n sì kúkú di aláìgbàgbọ́ ní gbogbo ọ̀nà lẹ́yìn Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ǹjẹ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl sì ni àwọn ẹni àkọ́kọ́ aláìgbàgbọ́ bí? Rárá. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ìjọ ìjọ tó ṣíwájú wọn di aláìgbàgbọ́ ṣíwájú wọn bí ìjọ Ànábì Nūh - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Àmọ́ nígbà tàwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl, àwọn ni wọ́n tún wà nípò àwọn ẹni àkọ́kọ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìjọ tiwọn. Nítorí náà, kò sí “ìtakora tóríbẹ́ẹ̀” nínú àwọn āyah wọ̀nyẹn.
Síwájú sí i, ìtúmọ̀ ’Islām ni ìjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ pátápátá fún àṣẹ Allāhu, òfin Rẹ̀ àti ìlànà Rẹ̀. Èyí ni àwọn kan mọ̀ sí “ṣíṣe ìfẹ́-tỌlọ́hun”. Èwo nínú àwọn Ànábì Ọlọ́hun àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni kò juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ pátápátá fún àṣẹ Allāhu, òfin Rẹ̀ àti ìlànà Rẹ̀? Èwo nínú wọn sẹ́ ni kò ṣe ìfẹ́-tỌlọ́hun? Kò sí. Ìdí nìyí ti gbogbo wọn fi jẹ́ mùsùlùmí gẹ́gẹ́ bi Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ṣe fi rinlẹ̀ nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:128 – 141.
Kíyè sí i! Nasrọ̄niyyah kò túmọ̀ sí “ṣíṣe ìfẹ́ tỌlọ́hun”. Nasrọ̄niyyah kò sì túmọ̀ sí ìjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ pátápátá fún àṣẹ Ọlọ́hun, òfin Ọlọ́hun àti ìlànà Rẹ̀. Kódà àwọn nasọ̄rọ̄ wulẹ̀ ti kó ara wọn kúrò lábẹ́ òfin Ọlọ́hun, wọ́n ti wà lábẹ́ òfin “ìfẹ́-àwọn wòlíì” ní orúkọ “oore-ọ̀fẹ́ ‘Īsā ọmọ Mọryam”. Èyí ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah at-Taobah; 9:31 àti sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3:64.
Nítorí náà, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kì í ṣe ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ pátápátá fún àṣẹ Allāhu, òfin Rẹ̀ àti ìlànà Rẹ̀. Àmọ́ nínú ìjọ rẹ̀, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (14) Surah: Al-An‘ām
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close