Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (18) Surah: Al-An‘ām
وَهُوَ ٱلۡقَاهِرُ فَوۡقَ عِبَادِهِۦۚ وَهُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡخَبِيرُ
Òun sì ni Olùborí tó wà lókè àwọn ẹrú Rẹ̀. Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán.¹
Āyah yìí àti āyah 61 nínú sūrah yìí ti fi rinlẹ̀ pé, òkè lókè àwọn sánmọ̀ ni pàápàá bíbẹ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - wà pẹ̀lú títóbi Rẹ̀. Àmọ́ sūrah az-Zukruf; 43:84, sūrah al-Hadīd; 57:4 àti = = sūrah al-Mujādilah; 58:7 èyí tí àwọn kan fi lérò pé kò sí ibi tí pàápàá bíbẹ Allāhu kò sí, lókè àti nílẹ̀ ní kọ̀rọ̀ àti ní gban̄gba, ó jẹ́ ìtúmọ̀ òdì tí kò wà ní ìbámu sí èròǹgbà Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - lórí àwọn āyah náà. Ìdí ni pé, àwọn āyah 18 àti 61 nínú sūrah al-’Ani‘ām àti sūrah an-Nahl; 16:50 ń sọ nípa ibi tí pàápàá bíbẹ Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - wà, ìyẹn sì ni òkè sánmọ̀ keje. Àmọ́ àwọn sūrah az-Zukruf; 43: 84, sūrah al-Hadīd; 57:4 àti sūrah al-Mujādilah; 58:7 sì ń sọ nípa ìmọ̀ Allāhu àti nípa bí ìmọ̀ Rẹ̀ ṣe gbòòrò, tó sì fi ìmọ̀ Rẹ̀ yípo gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀ pátápátá, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò fi sí ẹ̀dá kan kan tí Allāhu kò nímọ̀ nípa ibi tí ó wà.
Ìdí nìyí tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ṣe fi sūrah al-’Ani‘ām; 6:80, sūrah Tọ̄hā; 20:98 àti sūrah at-Tọlāƙ; 65:12 yanjú ìrújú tí àwọn aláṣìtú wọ̀nyẹn ní.
Kíyè sí i, tòhun ti bí Fir‘aon ṣe ṣàì gbàgbọ́ tó nínú pàápàá bíbẹ Allāhu, kò kúkú wá Allāhu lọ sí àyè kan kan lórí ilẹ̀ ayé bí kò ṣe òkè ayé, ìyẹn sánmọ̀, bí ó tilẹ̀ já sí pé kò lè rí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā -. Èyí wà nínú sūrah Gọ̄fir; 40:36 - 37.
Ọ̀kan pàtàkì tó sì burú nínú àwọn àdìsọ́kàn àwọn aláìgbàgbọ́ ni pé, “ibi gbogbo ni Ọlọ́hun wà”. Má ṣe bá wọn sọ bẹ́ẹ̀ nítorí kí o má baà dà bí tiwọn. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mujādilah; 58:7.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (18) Surah: Al-An‘ām
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close