Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (52) Surah: Al-An‘ām
وَلَا تَطۡرُدِ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ رَبَّهُم بِٱلۡغَدَوٰةِ وَٱلۡعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجۡهَهُۥۖ مَا عَلَيۡكَ مِنۡ حِسَابِهِم مِّن شَيۡءٖ وَمَا مِنۡ حِسَابِكَ عَلَيۡهِم مِّن شَيۡءٖ فَتَطۡرُدَهُمۡ فَتَكُونَ مِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ
Má ṣe lé àwọn tó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́ dànù; wọ́n ń fẹ́ Ojú rere Rẹ̀ ni. Ìṣirò-iṣẹ́ wọn kò sí ní ọrùn rẹ ní ọ̀nà kan kan. Kò sì sí ìṣirò-iṣẹ́ tìrẹ náà ní ọrùn wọn ní ọ̀nà kan kan. Tí o bá lé wọn dànù, o sì máa wà nínú àwọn alábòsí.¹
1. Āyah yìí ń sọ nípa àwọn Sọhābah tí wọ́n jẹ́ tálíkà pọ́nńbélé, gẹ́gẹ́ bí āyah 53 tí ó tẹ̀lé āyah yìí ṣe fi hàn. Àwọn Sọhābah wọ̀nyí - kí Allāhu yọ́nú sí wọn - kò sì ní ibi iṣẹ́ kan kan tí wọ́n lè máa rí lọ. Gbàgede mọ́sálásí Òjíṣẹ́ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni ibùgbé àti ibùsùn wọn. Gbàgede mọ́sálásí yìí ni à ń pè ní (صُفَّةٌ) suffah. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe àwọn Sọhābah wọ̀nyí ní ahlu-ssuffah “ará gbàgede / ọ̀ọ̀dẹ̀ òde mọ́sálásí”. Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu nínú oúnjẹ ọrẹ tí àwọn tó ríbi lọ bá gbé wá fún Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Wọn a sì máa gbé sàárà fún wọn pẹ̀lú. Fún wí pé wọn kì í lọ sí ibì kan kan ló fi jẹ́ pé ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́ ṣíṣe tilāwa al-Ƙur’ān àti ṣíṣe gbólóhùn athikr èyí tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kọ́ wọn ni àwọn Sọhābah wọ̀nyí dúnnímọ́ jùlọ. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sì pa Ànábì Rẹ̀ ní àṣẹ láti máa wà pẹ̀lú wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń wà pẹ̀lú àwọn mìíràn tí wọ́n ń ríbi lọ fún ọ̀nà ìjẹ-ìmu wọn. Nítorí náà, àwọn Sọhābah wọ̀nyí kì í ṣe sūfī tàbí onitọrīkọ kan kan. Àní sẹ́, wọn kì í ṣe ṣeeu, wọn kì í ṣe murīdī. Irúfẹ́ āyah yìí tún wà nínú sūrah al-Kahf; 18:28.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (52) Surah: Al-An‘ām
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close