Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (43) Surah: Al-A‘rāf
وَنَزَعۡنَا مَا فِي صُدُورِهِم مِّنۡ غِلّٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهِمُ ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ وَقَالُواْ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي هَدَىٰنَا لِهَٰذَا وَمَا كُنَّا لِنَهۡتَدِيَ لَوۡلَآ أَنۡ هَدَىٰنَا ٱللَّهُۖ لَقَدۡ جَآءَتۡ رُسُلُ رَبِّنَا بِٱلۡحَقِّۖ وَنُودُوٓاْ أَن تِلۡكُمُ ٱلۡجَنَّةُ أُورِثۡتُمُوهَا بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
A ó sì mú inúnibíni kúrò nínú ọkàn wọn. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ wọn. Wọn yóò sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu,¹ Ẹni tí Ó fi wá mọ̀nà yìí. Àwa ìbá tí mọ̀nà, tí kì í bá ṣe pé Allāhu tọ́ wa sí ọ̀nà. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá.” Wọ́n sì máa pè wọ́n pé: “Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A jogún rẹ̀ fún yín nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”²
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Fātihah;1:2.
عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ قَالَ قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ لَنْ يُنَجِّيَ أَحَدًا مِنْكُمْ عَمَلُهُ قَالُوا وَلَا أَنْتَ يَا رَسُولَ اللَّهِ قَالَ وَلَا أَنَا إِلَّا أَنْ يَتَغَمَّدَنِي اللَّهُ بِرَحْمَةٍ.
Láti ọ̀dọ̀ bàbá Huraerah - kí Allāhu yọ́nú sí i -, ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé, “Iṣẹ́ ẹnì kan kan nínú yín kò lè là á (kò lè mú un rí ìgbàlà níbi Iná).” Wọ́n sọ pé, “Àti ìwọ náà, Òjíṣẹ́ Allāhu?” Ó sọ pé, “Àti èmi náà àfi kí Allāhu fi àánú bò mí ní àṣírí. (Bukọ̄riy)
Kíyè sí i, àwọn kan lérò pé, hadīth yìí tako āyah yìí àti irú rẹ̀. Kódà àwọn kan sọ pé, hadīth yìí kò ní àlàáfíà. Àwọn kan wulẹ̀ sọ pé, “Nítorí irú hadīth yìí ni àwọn kò fi gba àwọn hadīth wọlé.”
Ní àkọ́kọ́ ná, kò sí ìtakora kan kan láààrin āyah àti hadīth yìí. Àlàyé tí ó wà lórí rẹ̀ ni pé, kódà kí ẹ̀dá sin Allāhu - tó ga jùlọ - =
= fún gbogbo ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ mọ̀ dájú pé, kò lè mú Allāhu pẹ̀lú ipá láti gba iṣẹ́ náà. Gbígbà tí Allāhu bá gba iṣẹ́ ẹ̀dá nígbà náà kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àánú Rẹ̀. Ẹni tí Allāhu bá ṣíjú àánú Rẹ̀ wo lórí iṣẹ́ rẹ̀ ni iṣẹ́ rẹ̀ máa là á níbi ìyà Iná. Ẹni tí Allāhu bá kọ iṣẹ́ rẹ̀ lé lọ́wọ́, iṣẹ́ náà ti di iṣẹ́ òfò. Ìdí nìyí tí àwọn Ànábì fi máa ń tọrọ pé “Allāhu, gbà á lọ́wọ́ wa”.
Síwájú sí i, dípò kí àwọn ènìyàn ṣọra wọn, kí wọ́n sì jìnnà tefétefé sí iṣẹ́ tí kò bá òfin ẹ̀sìn mu, àìmọ̀kan ara wọn tún ń tì wọ́n lọ síbi pípe hadīth tó ní àlàáfíà parí ní hadīth tí kò ní àlàáfíà. Níwọ̀n ìgbà tí hadīth bá ti wà nínú Sọhīhul-Bukọ̄riy tàbí Sọhīhu Muslim, ó gbọ́dọ̀ ní àlàáfíà. Àgbọ́yé rẹ̀ nìkan ló kù wá kù.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (43) Surah: Al-A‘rāf
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close