Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Ayah: (60) Surah: At-Tawbah
۞ إِنَّمَا ٱلصَّدَقَٰتُ لِلۡفُقَرَآءِ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱلۡعَٰمِلِينَ عَلَيۡهَا وَٱلۡمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمۡ وَفِي ٱلرِّقَابِ وَٱلۡغَٰرِمِينَ وَفِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِۖ فَرِيضَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ
Àwọn tí ọrẹ (Zakāh) wà fún ni àwọn aláìní, àwọn mẹ̀kúnnù,¹ àwọn òṣìṣẹ́ Zakāh, àwọn tí ọkàn wọn fẹ́ gba ’Islām (ìyẹn àwọn tí wọ́n fẹ́ fi fa ọkàn wọn mọ́ra sínú ẹ̀sìn), àwọn ẹrú (fún gbígba òmìnira), àwọn onígbèsè, àwọn tó wà lójú ogun (ẹ̀sìn) Allāhu àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
1. “Faƙīr” ni aláìní, tálíkà, olòṣì. Ìyẹn ni ẹni tí ó fẹ́ ṣiṣẹ́, àmọ́ tí kò rí iṣẹ́ kan kan ṣe, yálà lábẹ́ ènìyàn tàbí iṣẹ́ àdáni. Kò sì ní ọ̀nà kan kan tí ó lè gbà rí owó. Kí wọ́n fún un nínú zakah kí ó fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tara tirẹ̀. “Miskīn” ni mẹ̀kúnnù. Ìyẹn ni ẹni tí ó ń rí iṣẹ́ kan ṣe, àmọ́ tí owó tó ń rí lórí iṣẹ́ náà kò ká àpapọ̀ bùkátà ìjẹ-ìmu rẹ̀, owó ilé gbígbé rẹ̀ àti gbígbọ́ bùkátà lórí ará ilé rẹ̀. Kí wọ́n fún un nínú zakah kí ó fi yanjú bùkátà ọrùn rẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Ayah: (60) Surah: At-Tawbah
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close