Check out the new design

Traducción de los significados del Sagrado Corán - Traducción Yoruba - Abu Rahima Mikael * - Índice de traducciones

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traducción de significados Capítulo: Al-Israa   Versículo:
مَّن كَانَ يُرِيدُ ٱلۡعَاجِلَةَ عَجَّلۡنَا لَهُۥ فِيهَا مَا نَشَآءُ لِمَن نُّرِيدُ ثُمَّ جَعَلۡنَا لَهُۥ جَهَنَّمَ يَصۡلَىٰهَا مَذۡمُومٗا مَّدۡحُورٗا
Ẹni tí ó bá ń gbèrò (oore) ayé yìí (nìkan), A máa taari ohun tí A bá fẹ́ sí i nínú rẹ̀ ní kíákíá fún ẹni tí A bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, A máa ṣe iná Jahanamọ fún un; ó máa wọ inú rẹ̀ ní ẹni èébú, ẹni ẹ̀kọ̀.
Las Exégesis Árabes:
وَمَنۡ أَرَادَ ٱلۡأٓخِرَةَ وَسَعَىٰ لَهَا سَعۡيَهَا وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَأُوْلَٰٓئِكَ كَانَ سَعۡيُهُم مَّشۡكُورٗا
Ẹni tí ó bá sì gbèrò (oore) ọ̀run, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rẹ̀ fún ọ̀run náà, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, àwọn wọ̀nyẹn, wọ́n máa fi ẹ̀san rere àdìpèlé dúpẹ́ iṣẹ́ wọn fún wọn.
Las Exégesis Árabes:
كُلّٗا نُّمِدُّ هَٰٓؤُلَآءِ وَهَٰٓؤُلَآءِ مِنۡ عَطَآءِ رَبِّكَۚ وَمَا كَانَ عَطَآءُ رَبِّكَ مَحۡظُورًا
Àwọn wọ̀nyí (tó ń gbèrò oore ayé) àti àwọn wọ̀nyí (tó ń gbèrò oore ọ̀run), gbogbo wọn ni À ń ṣe oore ayé fún láti inú ọrẹ Olúwa rẹ. Wọn kò níí dí ọrẹ Olúwa rẹ lọ́wọ́ (fún ìkíní kejì nílé ayé).
Las Exégesis Árabes:
ٱنظُرۡ كَيۡفَ فَضَّلۡنَا بَعۡضَهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖۚ وَلَلۡأٓخِرَةُ أَكۡبَرُ دَرَجَٰتٖ وَأَكۡبَرُ تَفۡضِيلٗا
Wo bí A ṣe fún apá kan wọn lóore àjùlọ lórí apá kan (nílé ayé). Dájúdájú tọ̀run tún tóbi jùlọ ní ipò, ó sì tóbi jùlọ lóore àjùlọ.
Las Exégesis Árabes:
لَّا تَجۡعَلۡ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ فَتَقۡعُدَ مَذۡمُومٗا مَّخۡذُولٗا
Má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu nítorí kí o má baà jókòó (sínú Iná) ní ẹni àbùkù, ẹni ẹ̀kọ̀ (tí wọ́n máa dá ìṣòro rẹ̀ dá).
Las Exégesis Árabes:
۞ وَقَضَىٰ رَبُّكَ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّآ إِيَّاهُ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَٰنًاۚ إِمَّا يَبۡلُغَنَّ عِندَكَ ٱلۡكِبَرَ أَحَدُهُمَآ أَوۡ كِلَاهُمَا فَلَا تَقُل لَّهُمَآ أُفّٖ وَلَا تَنۡهَرۡهُمَا وَقُل لَّهُمَا قَوۡلٗا كَرِيمٗا
Olúwa rẹ pàṣẹ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àyàfi Òun. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì tàbí ìkíní kejì wọn bá dàgbà sí ọ lọ́dọ̀, má ṣe ṣíọ̀ sí wọn, má ṣe jágbe mọ́ wọn. Máa bá àwọn méjèèjì sọ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé.
Las Exégesis Árabes:
وَٱخۡفِضۡ لَهُمَا جَنَاحَ ٱلذُّلِّ مِنَ ٱلرَّحۡمَةِ وَقُل رَّبِّ ٱرۡحَمۡهُمَا كَمَا رَبَّيَانِي صَغِيرٗا
Rẹ apá rẹ nílẹ̀ dáadáa (bọ̀wọ̀) fún àwọn méjèèjì nípa ṣíṣe àánú wọn. Kí o sì sọ pé: “Olúwa Ẹlẹ́dàá mi, kẹ́ àwọn méjèèjì nítorí pé, àwọn méjèèjì náà tọ́ mi ní kékeré.”
Las Exégesis Árabes:
رَّبُّكُمۡ أَعۡلَمُ بِمَا فِي نُفُوسِكُمۡۚ إِن تَكُونُواْ صَٰلِحِينَ فَإِنَّهُۥ كَانَ لِلۡأَوَّٰبِينَ غَفُورٗا
Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí yín, tí ẹ bá jẹ́ ẹni rere. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláforíjìn fún àwọn olùronúpìwàdà.
Las Exégesis Árabes:
وَءَاتِ ذَا ٱلۡقُرۡبَىٰ حَقَّهُۥ وَٱلۡمِسۡكِينَ وَٱبۡنَ ٱلسَّبِيلِ وَلَا تُبَذِّرۡ تَبۡذِيرًا
Fún ẹbí ní ẹ̀tọ́ rẹ̀. (Fún) mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá ní n̄ǹkan). Kí o sì má ṣe ná dúkìá yín ní ìná-àpà.
Las Exégesis Árabes:
إِنَّ ٱلۡمُبَذِّرِينَ كَانُوٓاْ إِخۡوَٰنَ ٱلشَّيَٰطِينِۖ وَكَانَ ٱلشَّيۡطَٰنُ لِرَبِّهِۦ كَفُورٗا
Dájúdájú àwọn àpà, wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá àwọn ṣaetọ̄n. Aláìmoore sì ni aṣ-Ṣaetọ̄n jẹ́ sí Olúwa rẹ̀.
Las Exégesis Árabes:
 
Traducción de significados Capítulo: Al-Israa
Índice de Capítulos Número de página
 
Traducción de los significados del Sagrado Corán - Traducción Yoruba - Abu Rahima Mikael - Índice de traducciones

Traducida por Sheij Abu Rahima Michael Aikueyeni.

Cerrar