Traducción de los significados del Sagrado Corán - Traducción Yoruba * - Índice de traducciones

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traducción de significados Versículo: (213) Capítulo: Sura Al-Baqara
كَانَ ٱلنَّاسُ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ فَبَعَثَ ٱللَّهُ ٱلنَّبِيِّـۧنَ مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ وَأَنزَلَ مَعَهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ لِيَحۡكُمَ بَيۡنَ ٱلنَّاسِ فِيمَا ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِۚ وَمَا ٱخۡتَلَفَ فِيهِ إِلَّا ٱلَّذِينَ أُوتُوهُ مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡبَيِّنَٰتُ بَغۡيَۢا بَيۡنَهُمۡۖ فَهَدَى ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لِمَا ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِ مِنَ ٱلۡحَقِّ بِإِذۡنِهِۦۗ وَٱللَّهُ يَهۡدِي مَن يَشَآءُ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٍ
Àwọn ènìyàn jẹ́ ìjọ kan ṣoṣo (ẹlẹ́sìn ’Islām bẹ̀rẹ̀ lórí Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a -). Lẹ́yìn náà, Allāhu gbé àwọn Ànábì dìde, tí wọ́n ń jẹ́ oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún wọn pẹ̀lú òdodo nítorí kí Ó lè fi ṣe ìdájọ́ láààrin àwọn ènìyàn nípa ohun tí wọ́n yapa-ẹnu lórí rẹ̀. Kò sì sí ẹni tó yapa-ẹnu (lórí ’Islām) àfi àwọn tí A fún ní Tírà, lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú dé bá wọn ní ti ìlara láààrin ara wọn (sí àwọn Ànábì - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -). Nítorí náà, Allāhu tọ́ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo sọ́nà pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀ nípa ohun tí (àwọn onílara)¹ yapa-ẹnu lórí rẹ̀ nípa òdodo (’Islām). Allāhu yó máa tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà.²
1. Ìyẹn àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄.
2. Ẹ wo sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:19, 67, 80 àti 85.
Las Exégesis Árabes:
 
Traducción de significados Versículo: (213) Capítulo: Sura Al-Baqara
Índice de Capítulos Número de página
 
Traducción de los significados del Sagrado Corán - Traducción Yoruba - Índice de traducciones

Traducción de los significados del Sagrado Corán al idioma Yoruba por Abu Rahima Mikael Aikweiny. Año de impresión: 1432H.

Cerrar