Traducción de los significados del Sagrado Corán - Traducción Yoruba * - Índice de traducciones

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traducción de significados Versículo: (72) Capítulo: Sura Al-Ahzaab
إِنَّا عَرَضۡنَا ٱلۡأَمَانَةَ عَلَى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَٱلۡجِبَالِ فَأَبَيۡنَ أَن يَحۡمِلۡنَهَا وَأَشۡفَقۡنَ مِنۡهَا وَحَمَلَهَا ٱلۡإِنسَٰنُۖ إِنَّهُۥ كَانَ ظَلُومٗا جَهُولٗا
Dájúdájú Àwa fi àgbàfipamọ́ (iṣẹ́ ẹ̀sìn àṣegbaláádá) lọ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àpáta. Wọ́n kọ̀ láti gbé e; wọ́n páyà rẹ̀. Ènìyàn sì gbé e. Dájúdájú (ènìyàn) jẹ́ alábòsí, aláìmọ̀kan.¹
1. Àgbàfipamọ́ ni ìtúmọ̀ “ ’amọ̄nah”. Èyí sì túmọ̀ sí ohun tí wọ́n gbé lé wa lọ́wọ́ fún ṣíṣọ́ àti àmójútó. Ohun tí Allāhu - tó ga jùlọ - gbélé wa lọ́wọ́ tí a óò máa ṣọ́, tí a óò máa ṣe àmójútó rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni ẹ̀sìn Rẹ̀, ’Islām. Allāhu sì gbé ẹ̀sìn náà kalẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀san. Ìyẹn ni pé, ẹni tí ó bá rí i ṣe gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe gbé e kalẹ̀, ó máa gba láádá lórí rẹ̀. Àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti àpáta gbà láti máa ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu, àmọ́ wọ́n ní àwọn kò bùkátà sí láádá. Ènìyàn tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn àṣegbaláádá tán, ó di wàhálà sí wọn lọ́rùn nítorí pé, wọn kò mọ̀ pé tí ṣíṣe n̄ǹkan bá la láádá lọ, àìṣe rẹ̀ máa la ìyà lọ. Ìbá kúkú ṣuwọ̀n fún ènìyàn àti àlùjànnú láti ṣe ẹ̀sìn láì retí láádá kan tayọ ìtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu nìkan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀dá yòókù ṣe gbà á.
Las Exégesis Árabes:
 
Traducción de significados Versículo: (72) Capítulo: Sura Al-Ahzaab
Índice de Capítulos Número de página
 
Traducción de los significados del Sagrado Corán - Traducción Yoruba - Índice de traducciones

Traducción de los significados del Sagrado Corán al idioma Yoruba por Abu Rahima Mikael Aikweiny. Año de impresión: 1432H.

Cerrar