ترجمهٔ معانی قرآن کریم - ترجمه ى یوروبایی * - لیست ترجمه ها

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

ترجمهٔ معانی آیه: (38) سوره: سوره بقره
قُلۡنَا ٱهۡبِطُواْ مِنۡهَا جَمِيعٗاۖ فَإِمَّا يَأۡتِيَنَّكُم مِّنِّي هُدٗى فَمَن تَبِعَ هُدَايَ فَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ
A sọ pé¹: “Gbogbo yín, ẹ sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Nígbà tí ìmọ̀nà bá dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, ìpáyà kò níí sí fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
1. Kíyè sí i, nígbàkígbà tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - bá lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ “ọ̀pọ̀” dípò “ẹyọ” fún ara Rẹ̀, kò túmọ̀ sí pé “Ọlọ́hun Òdodo” pọ̀ ní òǹkà. Ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ ọ̀pọ̀ lè dúró fún ọ̀pọ̀ ní òǹkà tàbí àpọ́nlé. Ibikíbi tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - bá ti lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ “ọ̀pọ̀” nínú al-Ƙur’ān tàbí ọ̀rọ̀-orúkọ “ọ̀pọ̀” tàbí ọ̀rọ̀-ìṣe “ọ̀pọ̀”, kò túmọ̀ sí “Ọlọ́hun” púpọ̀ rárá. Àmọ́ Ó ń ṣe àpọ́nlé fún iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀ ni. Kí èyí lè dájú pé ìwọ̀nyí kò túmọ̀ sí “Ọlọ́hun” púpọ̀, ṣebí ìtúmọ̀ ọlọ́hun ni ẹni tí wọ́n ń jọ́sìn fún tàbí ẹni tí wọ́n ń bọ, ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé ibikíbi tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - bá ti sọ̀rọ̀ kan jíjọ́sìn fún Un kì í lo ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ kan àfi “ẹyọ”. Èyí ló fi rinlẹ̀ pé ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́hun Òdodo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, àmọ́ Ó lè lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ ọ̀pọ̀ “Àwa” fún ara Rẹ̀ ní ti ìtúmọ̀ àpọ́nlé.
تفسیرهای عربی:
 
ترجمهٔ معانی آیه: (38) سوره: سوره بقره
فهرست سوره ها شماره صفحه
 
ترجمهٔ معانی قرآن کریم - ترجمه ى یوروبایی - لیست ترجمه ها

ترجمه ى معانی قرآن کریم به زبان یوروبایی. مترجم: شیخ ابو رحیمه میکائیل ایکوینی. سال چاپ: 1432هجرى قمرى.

بستن