Fassarar Ma'anonin Alqura'ni - Fassara da Yarabanci * - Teburin Bayani kan wasu Fassarori

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Fassarar Ma'anoni Sura: Suratu Almu'aminoun   Aya:

Suuratul-Mu'minuun

قَدۡ أَفۡلَحَ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ
Dájúdájú àwọn onígbàgbọ́ òdodo ti jèrè.
Tafsiran larabci:
ٱلَّذِينَ هُمۡ فِي صَلَاتِهِمۡ خَٰشِعُونَ
Àwọn tó ń páyà (Allāhu) nínú ìrun wọn,
Tafsiran larabci:
وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَنِ ٱللَّغۡوِ مُعۡرِضُونَ
àti àwọn tó ń ṣẹ́rí kúrò níbi ìsọkúsọ,
Tafsiran larabci:
وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِلزَّكَوٰةِ فَٰعِلُونَ
àti àwọn tó ń ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀mí àti ara) wọn.¹
1. Ìtúmọ̀ mìíràn fún āyah yìí nìyí: “àti àwọn tó ń yọ zakāh”. Àmọ́ ìtúmọ̀ òkè yẹn ló bá a mu jùlọ nítorí àwọn ìwòye mẹ́ta kan.
Ìkíní: Sūrah Mọkkah àti āyah Mọkkah ni āyah yìí. Zakāh yíyọ kò sì bẹ̀rẹ̀ ní Mọkkah Alápọ̀n-ọ́nlé, bí kò ṣe ní Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀. Ìkejì: Nínú al-Ƙur’ān Alápọ̀n-ọ́nlé, gbogbo āyah tó ń sọ̀rọ̀ nípa zakāh yíyọ nínú dúkìá máa ń sopọ̀ mọ́ ìrun kíkí “ẹ kí ìrun, ẹ yọ zakāh”.
Ìkẹta: “Ītā’u zakāh” yíyọ zakāh ní èdè al-Ƙur’ān Alápọ̀n-ọ́nlé tí ó bá ń sọ̀rọ̀ nípa zakāh dúkìá, kì í lo “fi‘lu-zakāh” ṣíṣe zakāh.
Nípa ìwọ̀nyẹn, zakāh tẹ̀mí àti tara ni èròǹgbà Allāhu nínú āyah yìí, kì í ṣe zakāh ti dúkìá.
Zakāh tẹ̀mí: òhun ni fífi “taohīdullāh” mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àti “al-’iklās” ọkàn tó mọ́ kúrò níbi “riyā’” ṣekárími jọ́sìn fún Allāhu - Ọba mímọ́, kí á fi àwọn n̄ǹkan méjèèjì yẹn ṣe àfọ̀mọ́ ọkàn wa kúrò níbi “ṣirk” ẹbọ, “kufr” àìgbàgbọ́, “nifāƙ” ìṣojú-méjì àti “’amrọ̄dul-ƙulūb” àwọn àìsàn-ọkàn bíi “kibr” motómotó, “hasad” kèéta àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ti zakāh tara, òhun ni fífi ìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu àti àṣẹ Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a - yapa sí àṣẹ Èṣù. Ìyẹn ni pé, ṣíṣe ohun tí ẹ̀sìn pa wá ní àṣẹ rẹ̀ àti jíjìnnà sí ohun tí ẹ̀sìn kọ̀ fún wa. Wallāhu ’a‘lam.
Tafsiran larabci:
وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِفُرُوجِهِمۡ حَٰفِظُونَ
àti àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,
Tafsiran larabci:
إِلَّا عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِهِمۡ أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَإِنَّهُمۡ غَيۡرُ مَلُومِينَ
àfi ní ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó wọn àti ẹrúbìnrin wọn. Dájúdájú wọn kì í ṣe ẹni èébú (tí wọ́n bá súnmọ́ wọn),
Tafsiran larabci:
فَمَنِ ٱبۡتَغَىٰ وَرَآءَ ذَٰلِكَ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡعَادُونَ
nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wá òmíràn (súnmọ́) lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà,¹
1. Lára wíwá òmíràn súnmọ́ yàtọ̀ sí ìyàwó àti ẹrúbìnrin ni sísúnmọ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ’Islām ṣe ní èèwọ̀ fúnni láti fẹ́ (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ní sūrah an-Nisā’; 4: 22-24), sísúnmọ́ ẹranko, ìbásùn láààrin ọkùnrin méjì, ìbásùn láààrin obìnrin méjì, fífí ọwọ́ fa àtọ̀-ẹni jáde. Kíyè sí i, ọ̀tọ̀ ni ẹrú, ọ̀tọ̀ ni ọmọ-ọ̀dọ̀. Ẹrúbìnrin ni olówó-ẹrú lè fi tura, kì í ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀.
Tafsiran larabci:
وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِأَمَٰنَٰتِهِمۡ وَعَهۡدِهِمۡ رَٰعُونَ
àti àwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn,
Tafsiran larabci:
وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَوَٰتِهِمۡ يُحَافِظُونَ
àti àwọn tó ń ṣọ́ ìrun wọn;
Tafsiran larabci:
أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡوَٰرِثُونَ
àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùjogún,
Tafsiran larabci:
ٱلَّذِينَ يَرِثُونَ ٱلۡفِرۡدَوۡسَ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ
àwọn tó máa jogún ọgbà ìdẹ̀ra Firdaos. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Tafsiran larabci:
وَلَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ مِن سُلَٰلَةٖ مِّن طِينٖ
Dájúdájú A ti ṣe ẹ̀dá ènìyàn láti inú ohun tí A mọ jáde láti inú ẹrẹ̀.
Tafsiran larabci:
ثُمَّ جَعَلۡنَٰهُ نُطۡفَةٗ فِي قَرَارٖ مَّكِينٖ
Lẹ́yìn náà, A ṣe é ní àtọ̀ sínú àyè ìrọ̀rùn kan (ìyẹn, ilé-ọmọ).
Tafsiran larabci:
ثُمَّ خَلَقۡنَا ٱلنُّطۡفَةَ عَلَقَةٗ فَخَلَقۡنَا ٱلۡعَلَقَةَ مُضۡغَةٗ فَخَلَقۡنَا ٱلۡمُضۡغَةَ عِظَٰمٗا فَكَسَوۡنَا ٱلۡعِظَٰمَ لَحۡمٗا ثُمَّ أَنشَأۡنَٰهُ خَلۡقًا ءَاخَرَۚ فَتَبَارَكَ ٱللَّهُ أَحۡسَنُ ٱلۡخَٰلِقِينَ
Lẹ́yìn náà, A sọ àtọ̀ di ẹ̀jẹ̀ dídì. Lẹ́yìn náà, A sọ ẹ̀jẹ̀ dídì di bááṣí ẹran. Lẹ́yìn náà, A sọ bááṣí ẹran di eegun. Lẹ́yìn náà, A fi ẹran bo eegun. Lẹ́yìn náà, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn.¹ Nítorí náà, ìbùkún ni fún Allāhu, Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá (oníṣẹ́-ọnà).²
1. Ìyẹn ni pé, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn tí ó ní ẹ̀mí, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà sókè bẹ̀rẹ̀ láti òpóǹló títí di ọjọ́ ikú.
2. Irú gbólóhùn yìí أَحْسَنَ ٱلْخَٰلِقِينَ “Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá.” tún wà nínú sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.
Irúfẹ́ gbólóhùn yìí nìwọ̀nyí: وَأَنتَ خَيْرُ ٱلرَّٰزِقِينَ Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùpèsè. (sūrah al-Mọ̄’idah; 5:114); وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَٰكِمِينَ Òun l’Ó sì dára jùlọ nínú àwọn olùdájọ́. (sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:87);
وَأَنتَ أَرْحَمُ ٱلرَّٰحِمِينَ Ìwọ sì ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú. (sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:151); àti وَهُوَ أَسْرَعُ ٱلْحَٰسِبِينَ Òun sì yára jùlọ nínú àwọn oníṣirò. (sūrah al-’Ani‘ām; 6:62).
Àwọn gbólóhùn wọ̀nyẹn ń fi rinlẹ̀ pé Allāhu - tó ga jùlọ - ń jẹ́ Ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́dàá, olùpèsè, olùdájọ́, aláàánú àti oníṣirò.
Kíyè sí i, nínú àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa ń ṣe fún àwọn ẹ̀dá Rẹ̀, àmọ́ tí a tún ń rí àwọn kan nínú àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ tí àwọn náà máa ń ṣe wọ́n ni dídá ẹ̀dá, ìpèsè, ẹjọ́ dídá, àánú ṣíṣe àti ìṣírò iṣẹ́. Ṣùgbọ́n ìkọ̀ọ̀kan àwọn iṣẹ́ náà bùkátà sí àlàyé.
Dídá ẹ̀dá: Ní òdodo ni pé, kò sí ẹ̀dá kan láyé àti lọ́run, ìbáà mọ bíi ọmọ iná igún, àfi kí Allāhu jẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Kódà “àdámọ́”, ẹ̀dá kan nínú ẹ̀dá Allahu ni. Bí ẹnikẹ́ni bá ń lo “ìṣẹ̀dá” fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ó rí bẹ́ẹ̀ láti ara “ẹ̀dá” tí Allāhu ṣẹ̀dá ni. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kò lè rí bẹ́ẹ̀. Allāhu nìkan ṣoṣo ló ń dá ẹ̀dá láti ibi àìsí wá síbi bíbẹ. Àmọ́ ohun tí a gbàlérò pẹ̀lú fífi dídá ẹ̀dá tì sọ́dọ̀ ẹ̀dá ni ṣíṣe iṣẹ́-ọnà bíi ère gbígbẹ́ àti yíya àwòrán n̄ǹkan ẹlẹ́mìí. Èdè abunikù fún agbẹ́gilére ni “ẹlẹ́dàá”. Tí agbẹ́gilére bá mọ súná burúkú tí Allāhu - tó ga jùlọ - fún un, tí ó sì mọ̀ pé dájúdájú òun kò lè fi ẹ̀mí sára ère rẹ̀ tó ń gbẹ́ kalẹ̀, bóyá ó máa mọ̀ ọ́n ní ọ̀ràn. Ìdí nìyí tí hadīth kan fi sọ pé, lára ìyà tí ń bẹ nílẹ̀ ní ọ̀run nínú Iná fún agbẹ́gilére ni pé, wọ́n máa sọ fún un pé kí ó fi ẹ̀mí sára ère rẹ̀. Kò sì níí lè ṣe bẹ́ẹ̀. Wàyí, wọ́n ń pé agbẹ́gilére ní “ẹlẹ́dàá” nítorí pé, wọ́n ń fi iṣẹ́-ọnà wọn jọ ẹ̀dá tí Allāhu dá. Tí a bá wá lo orúkọ “ẹlẹ́dàá” fún wọn, dípò oníṣẹ́-ọnà, tí Allāhu - tó ga jùlọ - sì ń jẹ́ Ẹlẹ́dàá, ta wá ni Ẹlẹ́dàá tó dára jùlọ tí ẹ̀dá tirẹ̀ jẹ́ ojúlówó? Allāhu - tó ga jùlọ - ni. Ìdí nìyí tí Allāhu fi sọ pé, “Òun ni Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá.” Pípe “oníṣẹ́-ọnà” ni “ẹlẹ́dàá” kò sì túmọ̀ sí pé ẹ̀dá kan wà tó ṣẹ̀dá ara rẹ̀ tàbí pé ẹ̀dá kan wà tó ń dá ẹ̀dá mìíràn bí kò ṣe ṣíṣe iṣẹ́-ọnà. Nítorí náà, ìtúmọ̀ àwọn ẹlẹ́dàá nínú āyah yìí ni “àwọn oníṣẹ́-ọnà tàbí àwọn agbẹ́gilére”.
Ìpèsè: Àwọn ẹ̀dá kan gbàgbọ́ pé àwọn òrìṣà kan ń pèsè ìjẹ-ìmu àti dúkìá fún àwọn. Bí àpẹ̀ẹrẹ, Yorùbá gbàgbọ́ pé òrìṣà Ajé ń ṣe ìjẹ-ìmu, owó àti okòwò tí wọ́n sọ di “ọrọ̀-Ajé. Àwọn tó ń bọ́ ẹlòmíìràn náà ń sọra wọn di olùpèsè. Yàtọ̀ sí pé Allāhu ti fi rinlẹ̀ pé Òun nìkan ni Olùpèsè fún gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀. Tí èyí kò bá tí ì dá àwọn kan lójú bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì fẹ́ gbé gbogbo ìpèsè olúkùlùkù lórí ìwọ̀n, ó máa hàn sí wọn kedere pé, ìpèsè ti Allāhu pọ̀ jùlọ, kò sì ṣe é kà. Àti pé nínú ìpèsè Rẹ̀ ni wọ́n ti ń fún àwọn òrìṣà.
Ẹjọ́ dídá; A kúkú ní àwọn adájọ́ láààrin àwọn ènìyàn, yálà nílé ẹjọ́ tàbí ní àyè mìíràn. Àmọ́ kò sí adájọ́ tí ó jẹ́ arínú-róde. Àti pé ó wà nínú àwọn adájọ́ tó ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti fi ẹjọ́ ṣègbè. Allāhu nìkan ṣoṣo ni kì í fí ẹjọ́ ṣègbè. Àti pé ìdájọ́ Rẹ̀ dúró sórí mímọ ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba olùrojọ́. Nítorí náà, ìdí nìyí tí Allāhu fi mọ ẹjọ́ da jùlọ nínú àwọn adájọ́. Ìdájọ́ Rẹ̀ sì ni òpin.
Àánú Ṣíṣe: Ojú àánú àti ọkàn àánú ń bẹ lára àwọn ẹ̀dá kan, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí wọ́n fi ń pè wọ́n ní ẹlẹ́yinjú-àánú. Àmọ́ Allāhu ní àánú ẹ̀dá Rẹ̀ púpọ̀ jùlọ. Àti pé, nínú àánú tí Allāhu fi sí àwọn ẹ̀dá kan lọ́kàn ni wọ́n fi di aláàánú. Nítorí náà, Allāhu ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú.
Bí àlàyé ṣe máa lọ nìyẹn lórí irú àwọn gbólóhùn bẹ́ẹ̀ nínú al-Ƙur’ān, gẹ́gẹ́ bíi gbólóhùn “Olùyára jùlọ nínú àwọn olùṣírò-iṣẹ́”. Àmọ́ ní ti ète dídá gẹ́gẹ́ bí وَٱللَّهُ خَيْرُ ٱلْمَٰكِرِينَ Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn adéte. (āl-‘Imrọ̄n; 3:54). Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
Tafsiran larabci:
ثُمَّ إِنَّكُم بَعۡدَ ذَٰلِكَ لَمَيِّتُونَ
Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn ìyẹn, dájúdájú ẹ̀yin yóò di òkú.
Tafsiran larabci:
ثُمَّ إِنَّكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ تُبۡعَثُونَ
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní Ọjọ́ Àjíǹde wọ́n máa gbe yín dìde.
Tafsiran larabci:
وَلَقَدۡ خَلَقۡنَا فَوۡقَكُمۡ سَبۡعَ طَرَآئِقَ وَمَا كُنَّا عَنِ ٱلۡخَلۡقِ غَٰفِلِينَ
Dájúdájú A dá àwọn sánmọ̀ méje sí òkè yín. Àwa kò sì níí dágunlá sí àwọn ẹ̀dá.
Tafsiran larabci:
وَأَنزَلۡنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءَۢ بِقَدَرٖ فَأَسۡكَنَّٰهُ فِي ٱلۡأَرۡضِۖ وَإِنَّا عَلَىٰ ذَهَابِۭ بِهِۦ لَقَٰدِرُونَ
À ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ níwọ̀n níwọ̀n. Lẹ́yìn náà, À ń mú un dúró sínú ilẹ̀. Dájúdájú Àwa kúkú lágbára láti mú un lọ.
Tafsiran larabci:
فَأَنشَأۡنَا لَكُم بِهِۦ جَنَّٰتٖ مِّن نَّخِيلٖ وَأَعۡنَٰبٖ لَّكُمۡ فِيهَا فَوَٰكِهُ كَثِيرَةٞ وَمِنۡهَا تَأۡكُلُونَ
Lẹ́yìn náà, A fi dá àwọn ọgbà oko dàbínù àti àjàrà fún yín; ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso wà nínú rẹ̀ fún yín, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.
Tafsiran larabci:
وَشَجَرَةٗ تَخۡرُجُ مِن طُورِ سَيۡنَآءَ تَنۢبُتُ بِٱلدُّهۡنِ وَصِبۡغٖ لِّلۡأٓكِلِينَ
Àti igi kan tó ń hù jáde níbi àpáta Sīnā’; ó ń mú epo àti n̄ǹkan ìṣebẹ̀ jáde fún àwọn tó ń jẹ ẹ́.
Tafsiran larabci:
وَإِنَّ لَكُمۡ فِي ٱلۡأَنۡعَٰمِ لَعِبۡرَةٗۖ نُّسۡقِيكُم مِّمَّا فِي بُطُونِهَا وَلَكُمۡ فِيهَا مَنَٰفِعُ كَثِيرَةٞ وَمِنۡهَا تَأۡكُلُونَ
Àti pé dájúdájú àríwòye wà fún yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn; À ń fún yín mu nínú ohun tí ó wà nínú ikùn wọn. Àwọn àǹfààní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (mìíràn) tún wà fún yín lára wọn, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.
Tafsiran larabci:
وَعَلَيۡهَا وَعَلَى ٱلۡفُلۡكِ تُحۡمَلُونَ
Ẹ sì ń kó ẹrù sí orí àwọn ẹran ọ̀sìn àti ọkọ̀ ojú-omi.
Tafsiran larabci:
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوۡمِهِۦ فَقَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥٓۚ أَفَلَا تَتَّقُونَ
Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun mìíràn tí ẹ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
Tafsiran larabci:
فَقَالَ ٱلۡمَلَؤُاْ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن قَوۡمِهِۦ مَا هَٰذَآ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُكُمۡ يُرِيدُ أَن يَتَفَضَّلَ عَلَيۡكُمۡ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَأَنزَلَ مَلَٰٓئِكَةٗ مَّا سَمِعۡنَا بِهَٰذَا فِيٓ ءَابَآئِنَا ٱلۡأَوَّلِينَ
Àwọn olórí tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín, tí ó fẹ́ gbé àjùlọ fún ara rẹ̀ lórí yín. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (ránṣẹ́ sí wa ni), ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ ni. A kò sì gbọ́ èyí rí lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́.
Tafsiran larabci:
إِنۡ هُوَ إِلَّا رَجُلُۢ بِهِۦ جِنَّةٞ فَتَرَبَّصُواْ بِهِۦ حَتَّىٰ حِينٖ
Kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí àlùjànnú ń bẹ lára rẹ̀. Nítorí náà, ẹ máa retí (ìkángun) rẹ̀ títí di ìgbà kan ná.”
Tafsiran larabci:
قَالَ رَبِّ ٱنصُرۡنِي بِمَا كَذَّبُونِ
(Ànábì) Nūh sọ pé: “Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́.”
Tafsiran larabci:
فَأَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡهِ أَنِ ٱصۡنَعِ ٱلۡفُلۡكَ بِأَعۡيُنِنَا وَوَحۡيِنَا فَإِذَا جَآءَ أَمۡرُنَا وَفَارَ ٱلتَّنُّورُ فَٱسۡلُكۡ فِيهَا مِن كُلّٖ زَوۡجَيۡنِ ٱثۡنَيۡنِ وَأَهۡلَكَ إِلَّا مَن سَبَقَ عَلَيۡهِ ٱلۡقَوۡلُ مِنۡهُمۡۖ وَلَا تُخَٰطِبۡنِي فِي ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓاْ إِنَّهُم مُّغۡرَقُونَ
Nítorí náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: “Ṣe ọkọ̀ ojú-omi ní ojú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Nígbà tí àṣẹ Wa bá dé, tí omi bá ṣẹ́ yọ ní ojú àrò, nígbà náà ni kí o kó sínú ọkọ̀ ojú-omi gbogbo n̄ǹkan ní oríṣi méjì takọ-tabo àti ará ilé rẹ, àyàfi ẹni tí ọ̀rọ̀ náà kò lé lórí nínú wọn (fún ìparun). Má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ṣàbòsí; dájúdájú A óò tẹ̀ wọ́n rì sínú omi ni.
Tafsiran larabci:
فَإِذَا ٱسۡتَوَيۡتَ أَنتَ وَمَن مَّعَكَ عَلَى ٱلۡفُلۡكِ فَقُلِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي نَجَّىٰنَا مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّٰلِمِينَ
Nígbà tí o bá jókòó sínú ọkọ̀ ojú-omi náà, ìwọ àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ, sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó gbà wá là lọ́wọ́ ijọ alábòsí.”
Tafsiran larabci:
وَقُل رَّبِّ أَنزِلۡنِي مُنزَلٗا مُّبَارَكٗا وَأَنتَ خَيۡرُ ٱلۡمُنزِلِينَ
Sọ pé: “Olúwa mi, sọ̀ mí kalẹ̀ sí ibùsọ̀ ìbùkún. Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn amúnigúnlẹ̀.”¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah as-Sọffāt; 37:125.
Tafsiran larabci:
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ وَإِن كُنَّا لَمُبۡتَلِينَ
Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Àwa sì ni À ń dán ẹ̀dá wò.
Tafsiran larabci:
ثُمَّ أَنشَأۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِمۡ قَرۡنًا ءَاخَرِينَ
Lẹ́yìn náà, A mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn.
Tafsiran larabci:
فَأَرۡسَلۡنَا فِيهِمۡ رَسُولٗا مِّنۡهُمۡ أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥٓۚ أَفَلَا تَتَّقُونَ
A tún rán Òjíṣẹ́ kan sí wọn láààrin ara wọn (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun mìíràn tí ẹ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
Tafsiran larabci:
وَقَالَ ٱلۡمَلَأُ مِن قَوۡمِهِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بِلِقَآءِ ٱلۡأٓخِرَةِ وَأَتۡرَفۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا مَا هَٰذَآ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُكُمۡ يَأۡكُلُ مِمَّا تَأۡكُلُونَ مِنۡهُ وَيَشۡرَبُ مِمَّا تَشۡرَبُونَ
Àwọn olórí tó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀, àwọn tó pe ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn nírọ́, àwọn tí A ṣe gbẹdẹmukẹ fún nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí, wọ́n wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín; ó ń jẹ nínú ohun tí ẹ̀ ń jẹ, ó sì ń mu nínú ohun tí ẹ̀ ń mu.
Tafsiran larabci:
وَلَئِنۡ أَطَعۡتُم بَشَرٗا مِّثۡلَكُمۡ إِنَّكُمۡ إِذٗا لَّخَٰسِرُونَ
Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé abara kan bí irú yín, dájúdájú ẹ mà ti di ẹni òfò nìyẹn.
Tafsiran larabci:
أَيَعِدُكُمۡ أَنَّكُمۡ إِذَا مِتُّمۡ وَكُنتُمۡ تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَنَّكُم مُّخۡرَجُونَ
Ṣé ó ń ṣe àdéhùn fún yín pé nígbà tí ẹ bá kú, tí ẹ sì di erùpẹ̀ àti egungun tán, dájúdájú wọn yóò mu yín jáde (ní alààyè)?
Tafsiran larabci:
۞ هَيۡهَاتَ هَيۡهَاتَ لِمَا تُوعَدُونَ
Ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín (yìí) jìnnà tefétefé (sí òdodo).
Tafsiran larabci:
إِنۡ هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا ٱلدُّنۡيَا نَمُوتُ وَنَحۡيَا وَمَا نَحۡنُ بِمَبۡعُوثِينَ
Kò sí ìṣẹ̀mí ayé kan mọ́ àyàfi èyí tí à ń lò yìí; àwa kan ń kú, àwa kan ń wáyé. Àti pé wọn kò níí gbé wa dìde mọ́.
Tafsiran larabci:
إِنۡ هُوَ إِلَّا رَجُلٌ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗا وَمَا نَحۡنُ لَهُۥ بِمُؤۡمِنِينَ
(Òjíṣẹ́ náà) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Àwa kò sì níí gbà á gbọ́.”
Tafsiran larabci:
قَالَ رَبِّ ٱنصُرۡنِي بِمَا كَذَّبُونِ
(Òjíṣẹ́ náà) sọ pé: “Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́.”
Tafsiran larabci:
قَالَ عَمَّا قَلِيلٖ لَّيُصۡبِحُنَّ نَٰدِمِينَ
(Allāhu) sọ pé: “Láìpẹ́ ńṣe ni wọn yóò di alábàámọ̀.”
Tafsiran larabci:
فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّيۡحَةُ بِٱلۡحَقِّ فَجَعَلۡنَٰهُمۡ غُثَآءٗۚ فَبُعۡدٗا لِّلۡقَوۡمِ ٱلظَّٰلِمِينَ
Nítorí náà, ohùn igbe mú wọn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. A sì sọ wọ́n di pàǹtí. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ alábòsí.
Tafsiran larabci:
ثُمَّ أَنشَأۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِمۡ قُرُونًا ءَاخَرِينَ
Lẹ́yìn náà, A tún mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn.
Tafsiran larabci:
مَا تَسۡبِقُ مِنۡ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسۡتَـٔۡخِرُونَ
Ìjọ kan kò níí lọ ṣíwájú àkókò (ìparun) rẹ̀, wọn kò sì níí sún (ìparun wọn) síwájú.
Tafsiran larabci:
ثُمَّ أَرۡسَلۡنَا رُسُلَنَا تَتۡرَاۖ كُلَّ مَا جَآءَ أُمَّةٗ رَّسُولُهَا كَذَّبُوهُۖ فَأَتۡبَعۡنَا بَعۡضَهُم بَعۡضٗا وَجَعَلۡنَٰهُمۡ أَحَادِيثَۚ فَبُعۡدٗا لِّقَوۡمٖ لَّا يُؤۡمِنُونَ
Lẹ́yìn náà, A rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa níṣẹ́ ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ ìjọ kan bá dé, wọ́n á pè é ní òpùrọ́. A sì mú apá kan wọn tẹ̀lé apá kan nínú ìparun. A tún sọ wọ́n di ìtàn. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ tí kò gbàgbọ́ ní òdodo.
Tafsiran larabci:
ثُمَّ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ وَأَخَاهُ هَٰرُونَ بِـَٔايَٰتِنَا وَسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٍ
Lẹ́yìn náà, A rán (Ànábì) Mūsā àti ọmọ-ìyá rẹ̀ (Ànábì) Hārūn níṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé.
Tafsiran larabci:
إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦ فَٱسۡتَكۡبَرُواْ وَكَانُواْ قَوۡمًا عَالِينَ
(A rán wọn níṣẹ́) sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣègbéraga, wọ́n sì jẹ́ ìjọ olùjẹgàba.
Tafsiran larabci:
فَقَالُوٓاْ أَنُؤۡمِنُ لِبَشَرَيۡنِ مِثۡلِنَا وَقَوۡمُهُمَا لَنَا عَٰبِدُونَ
Wọ́n wí pé: “Ṣé kí á gba abara méjì bí irú wa gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹrú wa ni àwọn ènìyàn wọn?”
Tafsiran larabci:
فَكَذَّبُوهُمَا فَكَانُواْ مِنَ ٱلۡمُهۡلَكِينَ
Nítorí náà, wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. Wọ́n sì wà nínú àwọn olùparun.
Tafsiran larabci:
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ لَعَلَّهُمۡ يَهۡتَدُونَ
Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà.
Tafsiran larabci:
وَجَعَلۡنَا ٱبۡنَ مَرۡيَمَ وَأُمَّهُۥٓ ءَايَةٗ وَءَاوَيۡنَٰهُمَآ إِلَىٰ رَبۡوَةٖ ذَاتِ قَرَارٖ وَمَعِينٖ
A ṣe ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ ní àmì kan. A sì ṣe ibùgbé fún àwọn méjèèjì sí ibi gíga kan, tó ní ibùgbé, tó sì ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Anbiyā’ 21;91
Tafsiran larabci:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلرُّسُلُ كُلُواْ مِنَ ٱلطَّيِّبَٰتِ وَٱعۡمَلُواْ صَٰلِحًاۖ إِنِّي بِمَا تَعۡمَلُونَ عَلِيمٞ
Ẹ̀yin Òjíṣẹ́, ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa, kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú Èmi ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Tafsiran larabci:
وَإِنَّ هَٰذِهِۦٓ أُمَّتُكُمۡ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ وَأَنَا۠ رَبُّكُمۡ فَٱتَّقُونِ
Àti pé dájúdájú (’Islām) yìí ni ẹ̀sìn yín. (Ó jẹ́) ẹ̀sìn kan ṣoṣo. Èmi sì ni Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.
Tafsiran larabci:
فَتَقَطَّعُوٓاْ أَمۡرَهُم بَيۡنَهُمۡ زُبُرٗاۖ كُلُّ حِزۡبِۭ بِمَا لَدَيۡهِمۡ فَرِحُونَ
Ṣùgbọ́n wọ́n gé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn wọn láààrin ara wọn sí kélekèle. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun tó ń bẹ ní ọ̀dọ̀ wọn.
Tafsiran larabci:
فَذَرۡهُمۡ فِي غَمۡرَتِهِمۡ حَتَّىٰ حِينٍ
Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ sínú ìṣìnà wọn títí di ìgbà kan ná.
Tafsiran larabci:
أَيَحۡسَبُونَ أَنَّمَا نُمِدُّهُم بِهِۦ مِن مَّالٖ وَبَنِينَ
Ṣé wọ́n ń lérò pé (bí) A ṣe ń fi dúkìá àti ọmọ nìkan ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn,
Tafsiran larabci:
نُسَارِعُ لَهُمۡ فِي ٱلۡخَيۡرَٰتِۚ بَل لَّا يَشۡعُرُونَ
ni A óò ṣe máa yára ti àwọn oore sí ọ̀dọ̀ wọn lọ (títí láéláé). Rárá, wọn kò fura ni!¹
1. Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ èsì fún ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn aláìgbàgbọ́ tí wọ́n lérò pé ẹni ayé bá yẹ ni ọ̀run yóò yẹ. Àmọ́ kò yé wọn pé, oore ilé ayé yìí wà ní abẹ́ oore Àjọkẹ́-ayé (ar-rahmāniyyah) fún gbogbo ẹ̀dá láì fi tẹ̀sìn ṣe.
Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, oore ọ̀run wà ní abẹ́ oore Àṣàkẹ́ ọ̀run (ar-rahīmiyyah) fún ọ̀wọ́ àwa onígbàgbọ́ òdodo. Nítorí náà, oore ẹ̀dẹ tí kò lè dé ọ̀run ni oore ọwọ́ aláìgbàgbọ́ àti ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí.
Tafsiran larabci:
إِنَّ ٱلَّذِينَ هُم مِّنۡ خَشۡيَةِ رَبِّهِم مُّشۡفِقُونَ
Dájúdájú àwọn tó ń páyà (ìṣírò-iṣẹ́) nípa ìpáyà wọn nínú Olúwa wọn;
Tafsiran larabci:
وَٱلَّذِينَ هُم بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ يُؤۡمِنُونَ
àti àwọn tó ń gba àwọn āyah Olúwa wọn gbọ́;
Tafsiran larabci:
وَٱلَّذِينَ هُم بِرَبِّهِمۡ لَا يُشۡرِكُونَ
àti àwọn tí kì í ṣẹbọ sí Olúwa wọn,
Tafsiran larabci:
وَٱلَّذِينَ يُؤۡتُونَ مَآ ءَاتَواْ وَّقُلُوبُهُمۡ وَجِلَةٌ أَنَّهُمۡ إِلَىٰ رَبِّهِمۡ رَٰجِعُونَ
àti àwọn tí wọ́n ń ṣe ohun wọ́n ń ṣe (nínú àwọn iṣẹ́ rere) pẹ̀lú ìbẹ̀rù nínú ọkàn wọn pé dájúdájú àwọn yóò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn;
Tafsiran larabci:
أُوْلَٰٓئِكَ يُسَٰرِعُونَ فِي ٱلۡخَيۡرَٰتِ وَهُمۡ لَهَا سَٰبِقُونَ
àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n ń yára ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn sì ni aṣíwájú nínú (àwọn ẹ̀san) iṣẹ́ náà.
Tafsiran larabci:
وَلَا نُكَلِّفُ نَفۡسًا إِلَّا وُسۡعَهَاۚ وَلَدَيۡنَا كِتَٰبٞ يَنطِقُ بِٱلۡحَقِّ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ
Àti pé A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Tírà kan tó ń sọ òdodo (nípa iṣẹ́ ẹ̀dá) ń bẹ lọ́dọ̀ Wa. A kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Tafsiran larabci:
بَلۡ قُلُوبُهُمۡ فِي غَمۡرَةٖ مِّنۡ هَٰذَا وَلَهُمۡ أَعۡمَٰلٞ مِّن دُونِ ذَٰلِكَ هُمۡ لَهَا عَٰمِلُونَ
Àmọ́ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ wà nínú ìfọ́núfọ́ra nípa (al-Ƙur’ān) yìí. Àti pé wọ́n ní àwọn iṣẹ́ kan lọ́wọ́, tí ó yàtọ̀ sí iṣẹ́ rere yẹn.¹ Wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ náà
1. “Iṣẹ́ rere yẹn” ni àwọn iṣẹ́ tí Allāhu - tó ga jùlọ- fi ròyìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo ṣíwájú nínú āyah 57 sí āyah 61.
Tafsiran larabci:
حَتَّىٰٓ إِذَآ أَخَذۡنَا مُتۡرَفِيهِم بِٱلۡعَذَابِ إِذَا هُمۡ يَجۡـَٔرُونَ
títí di ìgbà tí A máa gbá àwọn onígbẹdẹmukẹ nínú wọn mú pẹ̀lú ìyà. Nígbà náà ni wọ́n máa kígbe (fún ìrànlọ́wọ́).
Tafsiran larabci:
لَا تَجۡـَٔرُواْ ٱلۡيَوۡمَۖ إِنَّكُم مِّنَّا لَا تُنصَرُونَ
Ẹ má ṣe kígbe (fún ìrànlọ́wọ́) ní òní. Dájúdájú kò sí ẹni tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lọ́dọ̀ Wa.
Tafsiran larabci:
قَدۡ كَانَتۡ ءَايَٰتِي تُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ فَكُنتُمۡ عَلَىٰٓ أَعۡقَٰبِكُمۡ تَنكِصُونَ
Wọ́n kúkú ń ka àwọn āyah Mi fún yín. Àmọ́ ńṣe ni ẹ̀ ń fà sẹ́yìn (níbi òdodo).
Tafsiran larabci:
مُسۡتَكۡبِرِينَ بِهِۦ سَٰمِرٗا تَهۡجُرُونَ
Ẹ̀ sì ń fi (Kaaba) ṣègbéraga, ẹ tún sọ ìsọkúsọ (nípa al-Ƙur’ān) ní alẹ́!
Tafsiran larabci:
أَفَلَمۡ يَدَّبَّرُواْ ٱلۡقَوۡلَ أَمۡ جَآءَهُم مَّا لَمۡ يَأۡتِ ءَابَآءَهُمُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Ṣé wọn kò ronú sí ọ̀rọ̀ náà ni? Tàbí ohun tó dé bá wọn jẹ́ ohun tí kò dé bá àwọn bàbá wọn àkọ́kọ́ rí ni?
Tafsiran larabci:
أَمۡ لَمۡ يَعۡرِفُواْ رَسُولَهُمۡ فَهُمۡ لَهُۥ مُنكِرُونَ
Tàbí wọn kò mọ Òjíṣẹ́ wọn mọ́ ni wọ́n fi di alátakò rẹ̀?
Tafsiran larabci:
أَمۡ يَقُولُونَ بِهِۦ جِنَّةُۢۚ بَلۡ جَآءَهُم بِٱلۡحَقِّ وَأَكۡثَرُهُمۡ لِلۡحَقِّ كَٰرِهُونَ
Tàbí wọn ń wí pé àlùjànnú kan ń bẹ lára rẹ̀ ni? Rárá o. Ó mú òdodo wá bá wọn ni. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì jẹ́ olùkórira òdodo.
Tafsiran larabci:
وَلَوِ ٱتَّبَعَ ٱلۡحَقُّ أَهۡوَآءَهُمۡ لَفَسَدَتِ ٱلسَّمَٰوَٰتُ وَٱلۡأَرۡضُ وَمَن فِيهِنَّۚ بَلۡ أَتَيۡنَٰهُم بِذِكۡرِهِمۡ فَهُمۡ عَن ذِكۡرِهِم مُّعۡرِضُونَ
Tí ó bá jẹ́ pé (Allāhu), Ọba Òdodo tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni, àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àwọn tó wà nínú wọn ìbá kúkú ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n A mú ìṣítí nípa ọ̀rọ̀ ara wọn wá fún wọn ni, wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbi ìṣítí (tí A mú wá fún) wọn.
Tafsiran larabci:
أَمۡ تَسۡـَٔلُهُمۡ خَرۡجٗا فَخَرَاجُ رَبِّكَ خَيۡرٞۖ وَهُوَ خَيۡرُ ٱلرَّٰزِقِينَ
Tàbí ò ń béèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn ni? Owó-ọ̀yà Olúwa rẹ̀ lóore jùlọ. Àti pé Òun l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.
Tafsiran larabci:
وَإِنَّكَ لَتَدۡعُوهُمۡ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
Àti pé dájúdájú ò ń pè wọ́n sójú ọ̀nà tààrà ni.
Tafsiran larabci:
وَإِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ عَنِ ٱلصِّرَٰطِ لَنَٰكِبُونَ
Àwọn tí kò sì gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni wọ́n ń ṣẹ́rí kúrò lójú ọ̀nà náà.
Tafsiran larabci:
۞ وَلَوۡ رَحِمۡنَٰهُمۡ وَكَشَفۡنَا مَا بِهِم مِّن ضُرّٖ لَّلَجُّواْ فِي طُغۡيَٰنِهِمۡ يَعۡمَهُونَ
Tí ó bá jẹ́ pé A kẹ́ wọn (nílé ayé), tí A sì gbé gbogbo ìṣòro ara wọn kúrò fún wọn, wọn ìbá tún won̄koko mọ́ ìtayọ ẹnu-ààlà wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà (nínú ìṣìnà).
Tafsiran larabci:
وَلَقَدۡ أَخَذۡنَٰهُم بِٱلۡعَذَابِ فَمَا ٱسۡتَكَانُواْ لِرَبِّهِمۡ وَمَا يَتَضَرَّعُونَ
Dájúdájú A fi ìyà jẹ wọ́n. Àmọ́ wọn kò tẹríba fún Olúwa wọn, wọn kò sì rawọ́ rasẹ̀ sí I
Tafsiran larabci:
حَتَّىٰٓ إِذَا فَتَحۡنَا عَلَيۡهِم بَابٗا ذَا عَذَابٖ شَدِيدٍ إِذَا هُمۡ فِيهِ مُبۡلِسُونَ
títí di ìgbà tí A fi ṣílẹ̀kùn ìyà líle fún wọn; nígbà náà ni wọ́n sọ̀rètí nù.
Tafsiran larabci:
وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَنشَأَ لَكُمُ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡأَبۡصَٰرَ وَٱلۡأَفۡـِٔدَةَۚ قَلِيلٗا مَّا تَشۡكُرُونَ
(Allāhu), Òun ni Ẹni tí Ó ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fún yín. Ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá sì kéré púpọ̀.
Tafsiran larabci:
وَهُوَ ٱلَّذِي ذَرَأَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَإِلَيۡهِ تُحۡشَرُونَ
Òun ni Ẹni tí Ó da yín sórí ilẹ̀, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n yóò ko yín jọ sí.
Tafsiran larabci:
وَهُوَ ٱلَّذِي يُحۡيِۦ وَيُمِيتُ وَلَهُ ٱخۡتِلَٰفُ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ
Òun ni Ẹni tó ń sọ ẹ̀dá di alààyè, Ó ń sọ ẹ̀dá di òkú, tiRẹ̀ sì ni ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán, ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?
Tafsiran larabci:
بَلۡ قَالُواْ مِثۡلَ مَا قَالَ ٱلۡأَوَّلُونَ
Rárá (wọn kò níí ṣe làákàyè, ṣebí) irú ohun tí àwọn ẹni àkọ́kọ́ wí ni àwọn náà wí.
Tafsiran larabci:
قَالُوٓاْ أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ
Wọ́n wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti kú, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé wọn yóò gbé wa dìde ni?
Tafsiran larabci:
لَقَدۡ وُعِدۡنَا نَحۡنُ وَءَابَآؤُنَا هَٰذَا مِن قَبۡلُ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّآ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Wọ́n kúkú ti ṣàdéhùn èyí fún àwa àti àwọn bàbá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
Tafsiran larabci:
قُل لِّمَنِ ٱلۡأَرۡضُ وَمَن فِيهَآ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ
Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí Ó ni ilẹ̀ àti ẹni tí ó wà ní orí rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”
Tafsiran larabci:
سَيَقُولُونَ لِلَّهِۚ قُلۡ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?”
Tafsiran larabci:
قُلۡ مَن رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ ٱلسَّبۡعِ وَرَبُّ ٱلۡعَرۡشِ ٱلۡعَظِيمِ
Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ méjèèje àti Olúwa Ìtẹ́ ńlá?”
Tafsiran larabci:
سَيَقُولُونَ لِلَّهِۚ قُلۡ أَفَلَا تَتَّقُونَ
Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
Tafsiran larabci:
قُلۡ مَنۢ بِيَدِهِۦ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيۡءٖ وَهُوَ يُجِيرُ وَلَا يُجَارُ عَلَيۡهِ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ
Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀, (Ẹni tí) Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”
Tafsiran larabci:
سَيَقُولُونَ لِلَّهِۚ قُلۡ فَأَنَّىٰ تُسۡحَرُونَ
Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń dan yín?”
Tafsiran larabci:
بَلۡ أَتَيۡنَٰهُم بِٱلۡحَقِّ وَإِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ
Àmọ́ sá, òdodo ni A mú wá ba wọn. Dájúdájú àwọn sì ni òpùrọ́.
Tafsiran larabci:
مَا ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ مِن وَلَدٖ وَمَا كَانَ مَعَهُۥ مِنۡ إِلَٰهٍۚ إِذٗا لَّذَهَبَ كُلُّ إِلَٰهِۭ بِمَا خَلَقَ وَلَعَلَا بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖۚ سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ
Allāhu kò fi ẹnì kan kan ṣe ọmọ, kò sì sí ọlọ́hun kan pẹ̀lú Rẹ̀. (Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà, ọlọ́hun kọ̀ọ̀kan ìbá ti kó ẹ̀dá tó dá lọ, apá kan wọn ìbá sì borí apá kan. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀ nípa ọmọ bíbí).
Tafsiran larabci:
عَٰلِمِ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ فَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ
(Allāhu) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Nítorí náà, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n fi ń ṣẹbọ sí I.
Tafsiran larabci:
قُل رَّبِّ إِمَّا تُرِيَنِّي مَا يُوعَدُونَ
Sọ pé: “Olúwa mi, Ó ṣeé ṣe kí Ó fi ohun tí wọ́n ń ṣèlérí rẹ̀ fún wọn hàn mí,
Tafsiran larabci:
رَبِّ فَلَا تَجۡعَلۡنِي فِي ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّٰلِمِينَ
Olúwa mi, má ṣe fi mí sínú ìjọ alábòsí.”
Tafsiran larabci:
وَإِنَّا عَلَىٰٓ أَن نُّرِيَكَ مَا نَعِدُهُمۡ لَقَٰدِرُونَ
Dájúdájú Àwa lágbára láti fi ohun tí A ṣèlérí rẹ̀ fún wọn hàn ọ́.
Tafsiran larabci:
ٱدۡفَعۡ بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ ٱلسَّيِّئَةَۚ نَحۡنُ أَعۡلَمُ بِمَا يَصِفُونَ
Fi èyí tó dára tí àìdára dànù. Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n fi ń ròyìn (Wa).
Tafsiran larabci:
وَقُل رَّبِّ أَعُوذُ بِكَ مِنۡ هَمَزَٰتِ ٱلشَّيَٰطِينِ
Sọ pé: “Olúwa mi, mò ń sádi Ọ́ níbi ròyíròyí t’àwọn èṣù.
Tafsiran larabci:
وَأَعُوذُ بِكَ رَبِّ أَن يَحۡضُرُونِ
Mò ń sádi Ọ́, Olúwa mi, níbi kí wọ́n wá bá mi.”
Tafsiran larabci:
حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَ أَحَدَهُمُ ٱلۡمَوۡتُ قَالَ رَبِّ ٱرۡجِعُونِ
(Wọ́n ń ṣẹ̀mí lọ) títí di ìgbà tí ikú fi máa dé bá ọ̀kan nínú wọn. Ó sì máa wí pé: “Olúwa mi, Ẹ dá mi padà (sílé ayé)
Tafsiran larabci:
لَعَلِّيٓ أَعۡمَلُ صَٰلِحٗا فِيمَا تَرَكۡتُۚ كَلَّآۚ إِنَّهَا كَلِمَةٌ هُوَ قَآئِلُهَاۖ وَمِن وَرَآئِهِم بَرۡزَخٌ إِلَىٰ يَوۡمِ يُبۡعَثُونَ
nítorí kí èmi lè ṣe iṣẹ́ rere nínú èyí tí mo gbé jù sílẹ̀. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, dájúdájú ó jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí ó kàn ń wí ni, (àmọ́) gàgá ti wà ní ẹ̀yìn wọn títí di ọjọ́ tí A óò gbé wọn dìde.¹
1. Kíyè sí i, àwọn āyah yìí (99 àti 100) ti fi rinlẹ̀ pé kò sí ìpadàsáyé fún àwọn òkú. Irú āyah yìí tún wà nínú sūrah az-Zumọr; 39:58 àti 59.
Síwájú sí i, àkúdàáyà kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ète àlùpàyídà láti ọ̀dọ̀ àwọn èṣù àlùjànnú. Irú ètekéte yìí náà ni àwọn olówò àlùjànnú máa ń lò láti fi ṣe àwọn òògùn ẹbọ bíi àfẹ́ẹ̀rí, ayẹta, òkígbẹ́, ìṣíjú, ọ̀wọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí náà, kì í ṣe òkú gan-an gan-an ní wọ́n tún lè rí mọ́ níbikíbi nílé ayé, àmọ́ àwọn èṣù àlùjànnú kan lè gbé àwọ̀ àti àwòrán òkú kan wọ̀ láti tan àwọn aláìgbàgbọ́ jẹ. Èyí sì tún jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òye tó wà nínú mọ̀mí-n̄g-mọ̀ọ́ tó gbọ́dọ̀ wáyé láààrin àwọn ẹbí tó fẹ́ di tọkọ taya nítorí kí ẹnì kan má baà fi èṣù àlùjànnú ṣe ẹnì kejì rẹ̀.
Tafsiran larabci:
فَإِذَا نُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَلَآ أَنسَابَ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَئِذٖ وَلَا يَتَسَآءَلُونَ
Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, kò níí sí ìbátan láààrin wọn ní ọjọ́ yẹn, wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè.¹
1. Àwọn nasọ̄rọ̄ sọ pé, “Āyah yìí tako sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:27 nípa ọ̀rọ̀ ìbéèrè.” Èsì: Kò sí ìtakora nínú rẹ̀. Ẹ wò ó, gbólóhùn yìí “wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè” ìyẹn ní kété tí olúkùlùkù bá kọ́kọ́ jí dìde láti inú sàréè rẹ̀. Iyè yóò pamọ́ àwọn ẹ̀dá nínú lásìkò náà ni, gẹ́gẹ́ bí ó tún ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Ƙọsọsọ; 28:66 àti sūrah az-Zumọr 39:68. Àmọ́ nígbà tí àwọn mọlāika bá da àwọn ẹ̀dá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu Ọba Olùdájọ́ àwọn ẹ̀dá máa bẹ̀rẹ̀ sí i bira wọn léèrè ìbéèrè ní ti àbámọ̀ àti ìtakora, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:27. Nítorí náà, kò sí ìtakora láààrin àwọn āyah náà.
Tafsiran larabci:
فَمَن ثَقُلَتۡ مَوَٰزِينُهُۥ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ
Ẹnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀wọ̀n, àwọn wọ̀nyẹn ni olùjèrè.
Tafsiran larabci:
وَمَنۡ خَفَّتۡ مَوَٰزِينُهُۥ فَأُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ فِي جَهَنَّمَ خَٰلِدُونَ
Ẹnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá fúyẹ́, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn lófò. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú iná Jahanamọ.
Tafsiran larabci:
تَلۡفَحُ وُجُوهَهُمُ ٱلنَّارُ وَهُمۡ فِيهَا كَٰلِحُونَ
Iná yóò máa jó wọn lójú. Wọn yó sì wà nínú rẹ̀, tí Iná yóò ti bà wọ́n lójú jẹ́.
Tafsiran larabci:
أَلَمۡ تَكُنۡ ءَايَٰتِي تُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ فَكُنتُم بِهَا تُكَذِّبُونَ
Ṣé wọ́n kì í ka àwọn āyah Mi fún yín ni, àmọ́ tí ẹ̀ ń pè é ní irọ́?
Tafsiran larabci:
قَالُواْ رَبَّنَا غَلَبَتۡ عَلَيۡنَا شِقۡوَتُنَا وَكُنَّا قَوۡمٗا ضَآلِّينَ
Wọ́n wí pé: “Olúwa wa, orí burúkú ló kọlù wá; àwa sì jẹ́ ìjọ olùṣìnà.
Tafsiran larabci:
رَبَّنَآ أَخۡرِجۡنَا مِنۡهَا فَإِنۡ عُدۡنَا فَإِنَّا ظَٰلِمُونَ
Olúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú Iná. Tí a bá fi lè padà (síbi iṣẹ́ ibi nílé ayé), dájúdájú nígbà náà alábòsí ni àwa.”
Tafsiran larabci:
قَالَ ٱخۡسَـُٔواْ فِيهَا وَلَا تُكَلِّمُونِ
(Allāhu) sọ pé: “Ẹ tẹ̀rì sínú rẹ̀. Ẹ má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀.”
Tafsiran larabci:
إِنَّهُۥ كَانَ فَرِيقٞ مِّنۡ عِبَادِي يَقُولُونَ رَبَّنَآ ءَامَنَّا فَٱغۡفِرۡ لَنَا وَٱرۡحَمۡنَا وَأَنتَ خَيۡرُ ٱلرَّٰحِمِينَ
Dájúdájú igun kan wà nínú àwọn ẹrúsìn Mi, tí wọ́n ń sọ pé: “Olúwa wa, a gbàgbọ́ ní òdodo. Nítorí náà, foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa. Ìwọ sì l’óore jùlọ nínú àwọn aláàánú.”¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.
Tafsiran larabci:
فَٱتَّخَذۡتُمُوهُمۡ سِخۡرِيًّا حَتَّىٰٓ أَنسَوۡكُمۡ ذِكۡرِي وَكُنتُم مِّنۡهُمۡ تَضۡحَكُونَ
Ṣùgbọ́n ẹ sọ wọ́n di oníyẹ̀yẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí àwọn yẹ̀yẹ́ (yín) fi mu yín gbàgbé ìrántí Mi. Ẹ̀yin sì ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín.
Tafsiran larabci:
إِنِّي جَزَيۡتُهُمُ ٱلۡيَوۡمَ بِمَا صَبَرُوٓاْ أَنَّهُمۡ هُمُ ٱلۡفَآئِزُونَ
Dájúdájú Mo san wọ́n ní ẹ̀san ní òní nítorí sùúrù wọn; dájúdájú àwọn, àwọn ni olùjèrè.
Tafsiran larabci:
قَٰلَ كَمۡ لَبِثۡتُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ عَدَدَ سِنِينَ
(Allāhu) sọ pé: “Ọdún mélòó ni ẹ̀yin (aláìgbàgbọ́) lò lórí ilẹ̀ ayé?”
Tafsiran larabci:
قَالُواْ لَبِثۡنَا يَوۡمًا أَوۡ بَعۡضَ يَوۡمٖ فَسۡـَٔلِ ٱلۡعَآدِّينَ
Wọ́n wí pé: “A lo ọjọ́ kan tàbí abala ọjọ́ kan, bi àwọn olùṣírò-ọjọ́ léèrè wò.”
Tafsiran larabci:
قَٰلَ إِن لَّبِثۡتُمۡ إِلَّا قَلِيلٗاۖ لَّوۡ أَنَّكُمۡ كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ
(Allāhu) sọ pé: “Ẹ kò gbé ilé ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀.”
Tafsiran larabci:
أَفَحَسِبۡتُمۡ أَنَّمَا خَلَقۡنَٰكُمۡ عَبَثٗا وَأَنَّكُمۡ إِلَيۡنَا لَا تُرۡجَعُونَ
Ṣé ẹ lérò pé A kàn ṣẹ̀dá yín fún ìranù ni, àti pé dájúdájú wọn ò níí da yín padà sọ́dọ̀ Wa?”
Tafsiran larabci:
فَتَعَٰلَى ٱللَّهُ ٱلۡمَلِكُ ٱلۡحَقُّۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ رَبُّ ٱلۡعَرۡشِ ٱلۡكَرِيمِ
Nítorí náà, Allāhu Ọba Òdodo ga. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Olúwa Ìtẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé.
Tafsiran larabci:
وَمَن يَدۡعُ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ لَا بُرۡهَٰنَ لَهُۥ بِهِۦ فَإِنَّمَا حِسَابُهُۥ عِندَ رَبِّهِۦٓۚ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلۡكَٰفِرُونَ
Ẹni tí ó bá pe ọlọ́hun mìíràn pẹ̀lú Allāhu, kò ní ẹ̀rí lọ́wọ́ lórí rẹ̀. Dájúdájú ìṣírò-iṣẹ́ rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́ kò níí jèrè.
Tafsiran larabci:
وَقُل رَّبِّ ٱغۡفِرۡ وَٱرۡحَمۡ وَأَنتَ خَيۡرُ ٱلرَّٰحِمِينَ
Sọ pé: “Olúwa mi, ṣàforíjìn, kí O sì kẹ́ (mi). Ìwọ sì l’óore jùlọ nínú àwọn aláàánú.”¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah 14.
Tafsiran larabci:
 
Fassarar Ma'anoni Sura: Suratu Almu'aminoun
Teburin Jerin Sunayen Surori Lambar shafi
 
Fassarar Ma'anonin Alqura'ni - Fassara da Yarabanci - Teburin Bayani kan wasu Fassarori

Fassarar Maanar Al-Qurani Mai girma da Yarabanci Wanda Shiekh Abu Rahima Mikail Alkweiny ya Fassara Wanda aka buga a Shekarar 1432 Hijira

Rufewa