Lẹ́yìn náà, A sọ àtọ̀ di ẹ̀jẹ̀ dídì. Lẹ́yìn náà, A sọ ẹ̀jẹ̀ dídì di bááṣí ẹran. Lẹ́yìn náà, A sọ bááṣí ẹran di eegun. Lẹ́yìn náà, A fi ẹran bo eegun. Lẹ́yìn náà, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn.[1] Nítorí náà, ìbùkún ni fún Allāhu, Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá (oníṣẹ́-ọnà).
1. Ìyẹn ni pé, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn tí ó ní ẹ̀mí, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà sókè bẹ̀rẹ̀ láti òpóǹló títí di ọjọ́ ikú.
Lẹ́yìn náà, A rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa níṣẹ́ ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ ìjọ kan bá dé, wọ́n á pè é ní òpùrọ́. A sì mú apá kan wọn tẹ̀lé apá kan nínú ìparun. A tún sọ wọ́n di ìtàn. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ tí kò gbàgbọ́ ní òdodo.
A ṣe ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ ní àmì kan. A sì ṣe ibùgbé fún àwọn méjèèjì sí ibi gíga kan, tó ní ibùgbé, tó sì ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú.[1]
àti àwọn tí wọ́n ń ṣe ohun wọ́n ń ṣe (nínú àwọn iṣẹ́ rere) pẹ̀lú ìbẹ̀rù nínú ọkàn wọn pé dájúdájú àwọn yóò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn;
Tí ó bá jẹ́ pé (Allāhu), Ọba Òdodo tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni, àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àwọn tó wà nínú wọn ìbá kúkú ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n A mú ìṣítí nípa ọ̀rọ̀ ara wọn wá fún wọn ni, wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbi ìṣítí (tí A mú wá fún) wọn.
Tí ó bá jẹ́ pé A kẹ́ wọn (nílé ayé), tí A sì gbé gbogbo ìṣòro ara wọn kúrò fún wọn, wọn ìbá tún won̄koko mọ́ ìtayọ ẹnu-ààlà wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà (nínú ìṣìnà).
Allāhu kò fi ẹnì kan kan ṣe ọmọ, kò sì sí ọlọ́hun kan pẹ̀lú Rẹ̀. (Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà, ọlọ́hun kọ̀ọ̀kan ìbá ti kó ẹ̀dá tó dá lọ, apá kan wọn ìbá sì borí apá kan. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀ nípa ọmọ bíbí).
nítorí kí èmi lè ṣe iṣẹ́ rere nínú èyí tí mo gbé jù sílẹ̀. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, dájúdájú ó jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí ó kàn ń wí ni, (àmọ́) gàgá ti wà ní ẹ̀yìn wọn títí di ọjọ́ tí A óò gbé wọn dìde.[1]
1. Kíyè sí i, àwọn āyah yìí (99 àti 100) ti fi rinlẹ̀ pé kò sí ìpadàsáyé fún àwọn òkú.
Contents of the translations can be downloaded and re-published, with the following terms and conditions:
1. No modification, addition, or deletion of the content.
2. Clearly referring to the publisher and the source (QuranEnc.com).
3. Mentioning the version number when re-publishing the translation.
4. Keeping the transcript information inside the document.
5. Notifying the source (QuranEnc.com) of any note on the translation.
6. Updating the translation according to the latest version issued from the source (QuranEnc.com).
7. Inappropriate advertisements must not be included when displaying translations of the meanings of the Noble Quran.
Igisubizo cy'ibyashatswe:
API specs
Endpoints:
Sura translation
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/sura/{translation_key}/{sura_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified sura (by its number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114)
Returns:
json object containing array of objects, each object contains the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/aya/{translation_key}/{sura_number}/{aya_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified aya (by its number sura_number and aya_number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114) aya_number: [1-...] (Aya number in the sura)
Returns:
json object containing the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".