Allāhu máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Ó sì máa mú wọn lékún sí i nínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.¹
1. Kì í ṣe gbogbo ìṣe tí Allāhu bá fi ròyìn Ara Rẹ̀ ni ó máa di orúkọ Rẹ̀ àfi èyí tí Allāhu bá fúnra Rẹ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí orúkọ Rẹ̀ nítorí àwọn ìdí wọ̀nyí:
Ìdí àkọ́kọ́: Nínú ìdí tí a kò gbọ́dọ̀ fi sọ gbogbo ìṣe tí Allāhu bá fi ròyìn Ara Rẹ̀ di orúkọ Rẹ̀ ni pé, Allāhu fi àwọn ìṣe kan ròyìn Ara Rẹ̀, tí àwọn ìṣe náà jẹ́ ìṣe tó dúró sórí fífi orúkọ ìṣe ẹ̀dá sọ orúkọ ẹ̀san ìṣe náà. Irú rẹ̀ ló ṣẹlẹ̀ nínú āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yìí. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kì í ṣe olùṣeyẹ̀yẹ́ (ẹni tí ó máa ń ṣe yẹ̀yẹ́) tàbí oníyẹ̀yẹ́ (ẹni tí ẹ̀dá lè fi ṣe yẹ̀yẹ́). Ẹnì kan kò sì níí máa ṣe yẹ̀yẹ́ àfi kí ó jẹ́ aláwàdà, oníranù. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kì í ṣe àwàdà, kì í sì ṣe ìranù. Ẹ̀dá l’ó lè jẹ́ aláwàdà, oníranù. Nítorí náà, kò sí orúkọ ẹ̀san tí a lè fún ẹni tí ó bá ń fi Allāhu tàbí āyah Rẹ̀ tàbí Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́ bí kò ṣe yẹ̀yẹ́. Ìyẹn ni pé, ẹ̀san yẹ̀yẹ́ ni ẹ̀san olùṣeyẹ̀yẹ́.
Síwájú sí i, irú èyí náà ló ṣẹlẹ̀ nínú sūrah an-Nisā’ 4:142. Àwọn munāfiki ni ẹlẹ́tàn, Allāhu kì í ṣe ẹlẹ́tàn. Ẹnì kan kò níí jẹ́ ẹlẹ́tàn àfi kí ó jẹ́ òpùrọ́, olùyapa-àdéhùn. Allāhu kì í ṣe òpùrọ́. Allāhu gan-an ni Òdodo. Bákan náà, Allāhu ni Olùmú-àdéhùn-ṣẹ. Àmọ́ nígbà tí ẹ̀dá bá lérò pé òun lè tan Allāhu, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti-gban̄gba, ohun tí ó máa jẹ́ ẹ̀san rẹ̀ lọ́dọ̀ Allāhu kò níí jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ẹ̀dẹ. Ìyẹn ni pé, Allāhu yóò máa jẹ́ kí ẹlẹ́tàn náà lérò pé, òjé òun ń jẹ Allāhu ni àṣírí òun kò fi tú síta. Kò sì sí òjé kan kan tí ó lè jẹ Allāhu. Ohun tí ẹlẹ́tàn ń ṣe ni ó rí ní ẹ̀san. Báyìí náà ni ọ̀rọ̀ ṣe rí lórí àwọn āyah tí Allāhu ti fi “mọkr” àti “kaed” (ète) ròyìn Ara Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú àwọn āyah wọ̀nyí: sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:99, sūrah Yūnus; 10:21, sūrah ar-Ra‘d; 13:42, sūrah at-Tọ̄riƙ; 86:16.
Irú èyí náà ló ṣẹlẹ̀ nínú sūrah as-Sajdah; 32:14. Ìyẹn ni pé, ìgbàgbé ni ẹ̀san ìgbàgbé, kì í ṣe pé Allāhu jẹ́ onígbàgbé (ẹni tó máa ń gbàgbé n̄ǹkan) tàbí ẹni tí ó yẹ kí ẹ̀dá gbàgbé. Ẹni tí wọ́n bá kọ́ ní ẹ̀kọ́, tí ó sì gbàgbé rẹ̀ tàbí ẹni tí inú rẹ̀ bá bu ni onígbàgbé. Allāhu mọ́, Ó sì ga tayọ ìwọ̀nyẹn. Nítorí náà, ẹni tí ó bá gbàgbé Allāhu nílé ayé ni ẹni tí ó pa Allāhu tì, tí kò sì jọ́sìn fún Un. Kí ni ó máa jẹ́ ẹ̀san rẹ̀ lọ́dọ̀ Allāhu bí kò ṣe pé kí Allāhu pa òun náà tì sínú ìyà Iná gbére. Ìyẹn ni pé, Allāhu kò níí fún un ní àǹfààní kan kan láti jáde kúrò nínú Iná. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Allāhu máa ń gbàgbé bí? Rárá o. Ṣebí ohun tí àgbẹ̀ bá gbìn sínú ilẹ̀ ló máa ká lérè oko. Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ni wọ́n ń pè ní “muṣākalah” fífi iṣẹ́ jọ ẹ̀san iṣẹ́.
Ìdí kejì: Nínú ìdí tí a kò gbọ́dọ̀ fi sọ gbogbo ìṣe tí Allāhu bá fi ròyìn Ara Rẹ̀ di orúkọ Rẹ̀ ni pé, Allāhu fi àwọn iṣẹ́ kan ròyìn Ara Rẹ̀, tí àwọn iṣẹ́ náà jẹ́ iṣẹ́ tó dúró sórí fífi gbólóhùn “kunfayakūn” Rẹ̀ kún iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀dá nítorí kí iṣẹ́ náà lè di òhun. Mùsùlùmí kò sì gbọ́dọ̀ sọ irúfẹ́ iṣẹ́ náà di orúkọ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -. Irú rẹ̀ ló ṣẹlẹ̀ nínú sūrah al-’Anfāl; 8:17.
Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kò fi Ọwọ́ ara Rẹ̀ jùkò. Òkò tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì jù lu àwọn ọ̀tá lójú ogun kì í ṣe òkò tí ó lè gba ẹ̀mí lára ènìyàn. Àmọ́ òkò náà gba ẹ̀mí wọn pẹ̀lú “kunfayakūn” Allāhu. Ṣé a wá lè pe Allāhu ní òǹjùkò bí nítorí pé Ó fi iṣẹ́ òkò jíjù ròyìn Ara Rẹ̀. Rárá.
1. Kì í ṣe gbogbo ìṣe tí Allāhu bá fi ròyìn Ara Rẹ̀ ni ó máa di orúkọ Rẹ̀ àfi èyí tí Allāhu bá fúnra Rẹ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí orúkọ Rẹ̀ nítorí àwọn ìdí wọ̀nyí:
Ìdí àkọ́kọ́: Nínú ìdí tí a kò gbọ́dọ̀ fi sọ gbogbo ìṣe tí Allāhu bá fi ròyìn Ara Rẹ̀ di orúkọ Rẹ̀ ni pé, Allāhu fi àwọn ìṣe kan ròyìn Ara Rẹ̀, tí àwọn ìṣe náà jẹ́ ìṣe tó dúró sórí fífi orúkọ ìṣe ẹ̀dá sọ orúkọ ẹ̀san ìṣe náà. Irú rẹ̀ ló ṣẹlẹ̀ nínú āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yìí. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kì í ṣe olùṣeyẹ̀yẹ́ (ẹni tí ó máa ń ṣe yẹ̀yẹ́) tàbí oníyẹ̀yẹ́ (ẹni tí ẹ̀dá lè fi ṣe yẹ̀yẹ́). Ẹnì kan kò sì níí máa ṣe yẹ̀yẹ́ àfi kí ó jẹ́ aláwàdà, oníranù. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kì í ṣe àwàdà, kì í sì ṣe ìranù. Ẹ̀dá l’ó lè jẹ́ aláwàdà, oníranù. Nítorí náà, kò sí orúkọ ẹ̀san tí a lè fún ẹni tí ó bá ń fi Allāhu tàbí āyah Rẹ̀ tàbí Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́ bí kò ṣe yẹ̀yẹ́. Ìyẹn ni pé, ẹ̀san yẹ̀yẹ́ ni ẹ̀san olùṣeyẹ̀yẹ́.
Síwájú sí i, irú èyí náà ló ṣẹlẹ̀ nínú sūrah an-Nisā’ 4:142. Àwọn munāfiki ni ẹlẹ́tàn, Allāhu kì í ṣe ẹlẹ́tàn. Ẹnì kan kò níí jẹ́ ẹlẹ́tàn àfi kí ó jẹ́ òpùrọ́, olùyapa-àdéhùn. Allāhu kì í ṣe òpùrọ́. Allāhu gan-an ni Òdodo. Bákan náà, Allāhu ni Olùmú-àdéhùn-ṣẹ. Àmọ́ nígbà tí ẹ̀dá bá lérò pé òun lè tan Allāhu, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti-gban̄gba, ohun tí ó máa jẹ́ ẹ̀san rẹ̀ lọ́dọ̀ Allāhu kò níí jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ẹ̀dẹ. Ìyẹn ni pé, Allāhu yóò máa jẹ́ kí ẹlẹ́tàn náà lérò pé, òjé òun ń jẹ Allāhu ni àṣírí òun kò fi tú síta. Kò sì sí òjé kan kan tí ó lè jẹ Allāhu. Ohun tí ẹlẹ́tàn ń ṣe ni ó rí ní ẹ̀san. Báyìí náà ni ọ̀rọ̀ ṣe rí lórí àwọn āyah tí Allāhu ti fi “mọkr” àti “kaed” (ète) ròyìn Ara Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú àwọn āyah wọ̀nyí: sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:99, sūrah Yūnus; 10:21, sūrah ar-Ra‘d; 13:42, sūrah at-Tọ̄riƙ; 86:16.
Irú èyí náà ló ṣẹlẹ̀ nínú sūrah as-Sajdah; 32:14. Ìyẹn ni pé, ìgbàgbé ni ẹ̀san ìgbàgbé, kì í ṣe pé Allāhu jẹ́ onígbàgbé (ẹni tó máa ń gbàgbé n̄ǹkan) tàbí ẹni tí ó yẹ kí ẹ̀dá gbàgbé. Ẹni tí wọ́n bá kọ́ ní ẹ̀kọ́, tí ó sì gbàgbé rẹ̀ tàbí ẹni tí inú rẹ̀ bá bu ni onígbàgbé. Allāhu mọ́, Ó sì ga tayọ ìwọ̀nyẹn. Nítorí náà, ẹni tí ó bá gbàgbé Allāhu nílé ayé ni ẹni tí ó pa Allāhu tì, tí kò sì jọ́sìn fún Un. Kí ni ó máa jẹ́ ẹ̀san rẹ̀ lọ́dọ̀ Allāhu bí kò ṣe pé kí Allāhu pa òun náà tì sínú ìyà Iná gbére. Ìyẹn ni pé, Allāhu kò níí fún un ní àǹfààní kan kan láti jáde kúrò nínú Iná. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Allāhu máa ń gbàgbé bí? Rárá o. Ṣebí ohun tí àgbẹ̀ bá gbìn sínú ilẹ̀ ló máa ká lérè oko. Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ni wọ́n ń pè ní “muṣākalah” fífi iṣẹ́ jọ ẹ̀san iṣẹ́.
Ìdí kejì: Nínú ìdí tí a kò gbọ́dọ̀ fi sọ gbogbo ìṣe tí Allāhu bá fi ròyìn Ara Rẹ̀ di orúkọ Rẹ̀ ni pé, Allāhu fi àwọn iṣẹ́ kan ròyìn Ara Rẹ̀, tí àwọn iṣẹ́ náà jẹ́ iṣẹ́ tó dúró sórí fífi gbólóhùn “kunfayakūn” Rẹ̀ kún iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀dá nítorí kí iṣẹ́ náà lè di òhun. Mùsùlùmí kò sì gbọ́dọ̀ sọ irúfẹ́ iṣẹ́ náà di orúkọ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -. Irú rẹ̀ ló ṣẹlẹ̀ nínú sūrah al-’Anfāl; 8:17.
Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kò fi Ọwọ́ ara Rẹ̀ jùkò. Òkò tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì jù lu àwọn ọ̀tá lójú ogun kì í ṣe òkò tí ó lè gba ẹ̀mí lára ènìyàn. Àmọ́ òkò náà gba ẹ̀mí wọn pẹ̀lú “kunfayakūn” Allāhu. Ṣé a wá lè pe Allāhu ní òǹjùkò bí nítorí pé Ó fi iṣẹ́ òkò jíjù ròyìn Ara Rẹ̀. Rárá.
Fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé, dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan ń bẹ fún wọn, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìgbàkígbà tí A bá p’èsè jíjẹ-mímu kan fún wọn nínú èso rẹ̀, wọn yóò sọ pé: “Èyí ni wọ́n ti pèsè fún wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” - Wọ́n mú un wá fún wọn ní ìrísí kan náà ni (àmọ́ pẹ̀lú adùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀). - Àwọn ìyàwó mímọ́ sì ń bẹ fún wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.
Báwo ni ẹ ṣe ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu ná! Bẹ́ẹ̀ sì ni òkú ni yín (tẹ́lẹ̀), Ó sì sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.¹
Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Mo sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi ní owó pọ́ọ́kú.¹ Èmi nìkan ṣoṣo ni kí ẹ sì bẹ̀rù.
Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí rọrọ̀ kiní kan fún ẹ̀mí kan. Wọn kò níí gba ìṣìpẹ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀. Wọn kò níí gba ààrọ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀.¹ Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.²
1. Ìyẹn ni pé, l’ọ́jọ́ Àjíǹde dúkìá kan kan kò níí wúlò fún ìràpadà ẹ̀mí níbi Iná àfi iṣẹ́ rere tí í ṣe ìjọ́sìn fún Allāhu àti ìwà rere tó tọ sunnah.
2. Àwọn kan sọ pé, “Àwọn āyah kan sọ pé kò sí ìṣìpẹ̀ l’ọ́jọ́ Àjíǹde, àwọn āyah mìíràn sọ pé ìṣìpẹ̀ wà.” Wọ́n ní, “Ìtakora nìyẹn.”
Èsì: Èyí jẹ́ “ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀”, kì í ṣe “ìtakora tóríbẹ́ẹ̀”. Àlàyé rẹ̀ nìyí. Àwọn āyah tó ń sọ pé kò sí ìṣìpẹ̀ l’ọ́jọ́ Àjíǹde ń jẹ́ ọ̀rọ̀ ajáni-ní-tànmọ́ọ̀n fún àwọn yẹhudi àti àwọn nasọ̄rọ̄ tí wọ́n ń fọkàn sí ìṣìpẹ̀ láì ṣe iṣẹ́ tí ó máa mú wọn lẹ́tọ̀ọ́ sí ìṣìpẹ̀ àti àwọn ọ̀ṣẹbọ tí ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà tiwọn wulẹ̀ dúró sórí bíbọ ẹ̀dá kan nítorí kí ó lè ṣìpẹ̀ wọn l’ọ́jọ́ Àjíǹde. Irúfẹ́ àwọn āyah náà ni sūrah al-Baƙọrah; 2:48, 123 àti 254 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:51. Àmọ́ àwọn āyah tó ń sọ pé ìṣìpẹ̀ máa wà l’ọ́jọ́ Àjíǹde ń sọ nípa àwọn májẹ̀mú tí ó wà fún ìṣìpẹ̀, olùṣìpẹ̀ àti olùṣìpẹ̀-fún. Irúfẹ́ àwọn āyah náà ni sūrah al-Baƙọrah; 2:255, sūrah Tọ̄hā; 20:109, sūrah Saba’; 34:23, sūrah az-Zukruf; 43:86 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:70. Kíyè sí i, gbígbà tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - máa gba ìṣìpẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kan fún àwọn kan kò kéré ipò fún agbára Allāhu, àmọ́ ipò tí ìbániṣàdúà wà ni ìṣìpẹ̀ wà. Nítorí náà, bí ó ṣe lẹ́tọ̀ọ́ láti bá ẹlòmíìràn ṣàdúà, bẹ́ẹ̀ náà ló máa ní ẹ̀tọ́ láti bá ẹlòmíìràn ṣìpẹ̀ l’ọ́jọ́ Àjíǹde. Olùṣìpẹ̀ àkọ́kọ́ fún gbogbo ẹ̀dá sì ni Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Àmọ́ má ṣe fọkàn sí pé mùsùlùmí kan máa ṣìpẹ̀ rẹ tàbí pé o máa ṣìpẹ̀ mùsùlùmí kan nítorí pé, nínú ohun tó pamọ́ fún ẹ̀dá ni ìmọ̀ nípa ta gan-an ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - máa fi ìṣìpẹ̀ pọ́nlé nínú àwa ẹrúsìn Rẹ̀. Àdúà wa ni pé, kí Allāhu fi ìṣìpẹ̀ ṣe àpọ́nlé fún èmi àti ẹ̀yin.
A tún fi ẹ̀ṣújò ṣe ibòji fún yín. A sì tún sọ (ohun mímu) mọnnu¹ àti (ohun jíjẹ) salwā² kalẹ̀ fún yín. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fún yín. Wọn kò sì ṣàbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
1. Adùn rẹ̀ dà bí adùn oyin.
2. Orúkọ ẹyẹ kan tí ó ládùn gan-an.
Nítorí náà, A sọ pé: “Ẹ fi burè kan (lára màálù) lu (òkú náà).”¹ Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ òkú di alààyè. Ó sì ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín, nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
1. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Òkú náà sì ta jí. Ó tú àṣírí ẹni tí ó pa á. Ó sì kú padà. Báyìí ni Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - ṣe jí òkú dìde pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -.
Ṣé ẹ̀ ń rankàn pé wọn yóò gbà yín gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé igun kan nínú wọn kúkú ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, wọ́n á yí i padà sódì lẹ́yìn tí wọ́n ti gbọ́ ọ yé; wọ́n sì mọ̀.
Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì ku apá kan wọn ku apá kan, wọ́n á wí pé: “Ṣé kì í ṣe pé ẹ̀ ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Allāhu ti ṣípayá rẹ̀ fún yín, kí wọ́n lè fi jà yín níyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín? Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni!”
Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ń fi ọwọ́ ara wọn kọ tírà, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Nítorí kí wọ́n lè tà á ní owó pọ́ọ́kú. Ègbé ni fún wọn sẹ́ nípa ohun tí ọwọ́ wọn kọ. Ègbé sì ni fún wọn pẹ̀lú nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Rárá (Iná kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí); ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ ibi kan, tí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tún yí i ká, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀run ra ìṣẹ̀mí ayé.¹ Nítorí náà, A ò níí ṣe ìyà ní fífúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
1. Ìyẹn ni pé, wọ́n mú ìṣẹ̀mí ayé, wọ́n sì fi ìṣẹ̀mí ọ̀run sílẹ̀. Ƙọtādah sọ pé, “Wọ́n fẹ́ràn kékeré tayé ju púpọ̀ tọ̀run” [Tọbariy] Ibn Kẹthīr sọ pé, “Wọ́n fẹ́ràn ayé ju ọ̀run, wọ́n sì ṣa ayé lẹ́ṣà ju ọ̀run.”
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa.” Wọ́n sì ń ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tó wà lẹ́yìn rẹ̀, òhun sì ni òdodo, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú wọn. Sọ pé: “Nítorí kí ni ẹ fi ń pa àwọn Ànábì Allāhu tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo?
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yín, A sì gbé àpáta s’ókè orí yín, (A sọ pé:) “Ẹ gbá ohun tí A fún yín mú dáradára. Kí ẹ sì tẹ́tí gbọ́rọ̀.” Wọ́n wí pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì yapa (rẹ̀).” Wọ́n ti kó ìfẹ́ bíbọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù sínú ọkàn wọn nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ wọn. Sọ pé: “Aburú ni ohun tí ìgbàgbọ́ (ìbọ̀rìṣà) yín ń pa yín láṣẹ rẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”
Wọ́n sì tẹ̀lé ohun tí àwọn èṣù àlùjànnú ń kà (fún wọn nínú idán lásìkò) ìjọba (Ànábì) Sulaemọ̄n. (Ànábì) Sulaemọ̄n kò sì di kèfèrí, ṣùgbọ́n àwọn èṣù àlùjànnú ni wọ́n di kèfèrí, wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn ní idán àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwọn mọlāika méjèèjì, Hārūt àti Mọ̄rūt ní ìlú Bābil.¹ Àwọn mọlāika méjèèjì náà kò sì níí kọ́ ẹnikẹ́ni àyàfi kí wọ́n sọ pé: “Àdánwò ni wá. Nítorí náà, má di kèfèrí.” Wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí wọn yóò fi ṣòpínyà láààrin ọmọnìyàn àti ẹnì kejì rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. - Wọn kò sì lè kó ìnira bá ẹnikẹ́ni àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. - Wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ó máa kó ìnira bá wọn, tí kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọ́n kúkú ti mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ra idán, kò níí sí ìpín rere kan fún un ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Aburú sì ni ohun tí wọ́n rà fún ẹ̀mí ara wọn tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.
1. Kíyè sí i, àwọn onímọ̀ Tafsīr tí wọ́n gbà pé mọlāika ni Hārūt àti Mọ̄rūt, wọ́n túmọ̀ āyah yìí pé, “ṣùgbọ́n àwọn èṣù àlùjànnú ni wọ́n di kèfèrí, wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn ní idán àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwọn mọlāika méjèèjì náà Hārūt àti Mọ̄rūt,…”. Ṣùgbọ́n àwọn onímọ̀ Tafsīr tí wọ́n gbà pé orúkọ àwọn àlùjànnú méjì kan ni Hārūt àti Mọ̄rūt, wọ́n túmọ̀ āyah yìí pé, “(Ànábì) Sulaemọ̄n kò sì di kèfèrí, … àti pé wọn kò sọ idán kalẹ̀ fún àwọn mọlāika méjì náà “(ìyẹn, Jibrīl àti Mīkā’īl). Hārūt àti Mọ̄rūt sì ni àlùjànnú tí ń kọ́ àwọn ènìyàn ní idán ní Bābil.” Àmọ́ sá, igun méjèèjì ló ní àlàyé ìdáláre lórí rẹ̀ nínú èdè Lárúbáwá, kì í ṣe nínú hadīth.
Síwájú sí i, àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ yìí “ ‘alā muliki Sulaemọ̄n” kò túmọ̀ sí lórí àga ìjọba Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Rárá o. Kò sí ìgbà kan kan tí èṣù àlùjànnú rọ́nà jẹ gàba rí lórí àga Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ni pé, bí Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a - ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìgbàgbọ́ òdodo tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fi rán an níṣẹ́ sí wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn èṣù àlùjànnú kan ń lọ bá àwọn ènìyàn láti máa kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ idán láti máa fi tako ìgbàgbọ́ òdodo tí wọ́n ń gbọ́ lọ́dọ̀ Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Níkété tí ìró aburú yìí détí ìgbọ́ Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a - ló pàṣẹ láti gba gbogbo àkọsílẹ̀ idán náà lọ́wọ́ wọn. Ó sì bo gbogbo rẹ̀ mọ́ inú ilẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn agbọ́mágbà ènìyàn kan pẹ̀lú àwọn èṣù àlùjànnú olóríkunkun padà wá a kàn ní ibi tí Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a - bò ó mọ́. Wọ́n sì padà síbi lílo idán náà, wọ́n sì tún ń ba Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a - lórúkọ jẹ́ kiri ìlú pé, ohun tí ó fi ṣe ìjọba lórí àwọn ẹ̀dá nìyẹn. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀. Ìgbàgbọ́ òdodo àti àwọn iṣẹ́ ìyanu ni Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a - fi ṣe ìjọba rẹ̀, kì í ṣe idán. Ẹ tún ka ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Sọ̄d; 38:34. W-Allāhu ’a‘lam.
Ti Allāhu ni ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn. Nítorí náà, ibikíbi tí wọ́n bá dojú yín kọ ibẹ̀ yẹn náà ni ojú rere Allāhu (ìyẹn ni pé, ẹ ti dojúkọ Allāhu ní ibi tí wọ́n bá pa yín láṣẹ pé kí ẹ dojúkọ kírun.) Dájúdájú Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.¹
1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ti fi sūrah al-Baƙọrah; 2:144, 149, àti 150 pa ìdájọ́ āyah yìí rẹ́, ìdájọ́ tí ń bẹ nínú āyah náà ṣe é lò fún ẹni tí ó wà ní àyè kan tí kò sì mọ agbègbè tí Kaabah wà sí ìlú náà láààrin orígun ayé mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nínú ìlú náà. Ibikíbi tí ó bá kọjú sí kírun rẹ̀ láààrin orígun méjì nínú orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìlú rẹ̀ tí gbé e títí ó máa fi mọ àmọ̀dájú nípa agbègbè tí Kaabah wà sí ìlú rẹ̀.
Àwọn tí kò nímọ̀ wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń bá wa sọ̀rọ̀ ni tàbí kí àmì kan wá bá wa (àwa ìbá gbàgbọ́)?” Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe sọ irú ọ̀rọ̀ wọn (yìí). Ọkàn wọn jọra wọn. A kúkú ti ṣe àlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú.
Dájúdájú Àwa fi òdodo rán ọ níṣẹ́. (O sì jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ (fún gbogbo ayé). Wọn kò sì níí bi ọ́ léèrè nípa àwọn èrò inú Iná.
Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí rọrọ̀ kiní kan fún ẹ̀mí kan. A ò sì níí gba ààrọ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀. Ìṣìpẹ̀ kan kò níí wúlò fún un. A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.¹
Olúwa wa, ṣe wá ní mùsùlùmí fún Ọ. Kí O sì ṣe nínú àrọ́mọdọ́mọ wa ní ìjọ mùsùlùmí fún Ọ. Fi ìlànà ẹ̀sìn wa hàn wá. Kí O sì gba ìronúpìwàdà wa. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ìjọ kan nìyẹn tí ó ti lọ. Tiwọn ni ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Tiyín ni ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí bi yín léèrè nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Ẹ sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb. (A gbàgbọ́ nínú) ohun tí wọ́n fún (àwọn Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā, àti ohun tí wọ́n fún àwọn Ànábì (yòókù) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”
Nítorí náà, tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú irú ohun tí ẹ gbàgbọ́, wọ́n ti mọ̀nà. Tí wọ́n bá sì gbúnrí, wọ́n ti wà nínú ìyapa (òdodo). Allāhu sì máa tó ọ (níbi aburú) wọn. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Tàbí ẹ̀ ń wí pé: “Dájúdájú (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb, wọ́n jẹ́ yẹhudi tàbí nasọ̄rọ̄.”¹ Sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin lẹ nímọ̀ jùlọ (nípa wọn ni) tàbí Allāhu?” Ta ló ṣàbòsí ju ẹni tó daṣọ bo ẹ̀rí ọ̀dọ̀ rẹ̀ (tí ó sọ̀kalẹ̀) láti ọ̀dọ̀ Allāhu? Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
1. Kókó tí āyah yìí ń fi rinlẹ̀ ni pé, kò sí Ànábì kan tàbí Òjíṣẹ́ Allāhu kan tó ṣe ẹ̀sìn yẹ̀húdí tàbí nasọ̄rọ̄ tàbí ìbọ̀rìṣà. ’Islām ni ẹ̀sìn tí gbogbo wọn ṣe - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá wọn -.
Ìjọ kan nìyẹn tí ó ti lọ. Tiwọn ni ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Tiyín ni ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí bi yín léèrè nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn ọmọ wọn. Dájúdájú àwọn ìjọ kan wà nínú wọn tí wọ́n kúkú ń fi òdodo pamọ́, wọ́n sì mọ̀.
Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí àdánwò kan bá kàn wọ́n, wọ́n á sọ pé: “Dájúdájú Allāhu l’Ó ni àwa; dájúdájú ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àwa yóò padà sí.”
Àyàfi àwọn tó ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣe àtúnṣe, tí wọ́n sì ṣàfi hàn òdodo, nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn ni Mo máa gba ìronúpìwàdà wọn. Èmi sì ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ tẹ̀lé ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Rárá, A óò máa tẹ̀lé ohun tí a bá l’ọ́wọ́ àwọn bàbá wa ni.” Ṣé pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn bàbá wọn kò ṣe làákàyè kan kan (nípa ẹ̀sìn), tí wọn kò sì mọ̀nà?
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó fi ìmọ̀nà ra ìṣìnà, (wọ́n tún fi) àforíjìn ra ìyà.¹ Ṣé wọn sì lè ṣèfaradà fún Iná! (Àbí kí ló kì wọ́n láyà láti ṣe iṣẹ́ Iná!)
1. Ìyẹn ni pé, wọ́n mú ìṣìnà, wọ́n fi ìmọ̀nà sílẹ̀, wọ́n mú ìyà, wọ́n sì fi àforíjìn sílẹ̀.
Ẹ pa wọ́n níbikíbi tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n. Kí ẹ sì lé wọn jáde kúrò níbi tí wọ́n ti le yín jáde. Ìfòòró le ju pípa lọ. Ẹ má ṣe jà wọ́n lógun ní Mọ́sálásí Haram títí wọ́n fi máa jà yín lógun nínú rẹ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá jà yín lógun, ẹ jà wọ́n lógun. Báyẹn ni ẹ̀san àwọn aláìgbàgbọ́.
Ẹ náwó sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe fi ọwọ́ ara yín fa ìparun (nípa sísá fún ogun ẹ̀sìn). Ẹ ṣe rere. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe-rere.
Bi àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl léèrè pé: “Mélòó ni A ti fún wọn nínú āyah tó yanjú (àmọ́ tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀)?” Ẹnikẹ́ni tí ó bá (fi àìgbàgbọ́) jìrọ̀ ìdẹ̀ra Allāhu lẹ́yìn tí ó dé bá a, dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.
A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn le yín lórí, ohun ìkórira sì ni fún yín. Ó sì lè jẹ́ pé ẹ kórira kiní kan, kí ohun náà sì jẹ́ oore fún yín. Ó sì tún lè jẹ́ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí kiní kan, kí ohun náà sì jẹ́ aburú fún yín. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
Wọ́n sì ń bi ọ́ léèrè nípa n̄ǹkan oṣù (obìnrin). Sọ pé: “Ìnira¹ ni (sísúnmọ́ wọn lásìkò náà). Nítorí náà, ẹ yẹra fún àwọn obìnrin l’ásìkò n̄ǹkan oṣù. Ẹ má ṣe súnmọ́ wọn (fún oorun ìfẹ́) títí wọn yó fi ṣe ìmọ́ra. Tí wọ́n bá sì ti ṣe ìmọ́ra, ẹ súnmọ́ wọn ní àyè tí Allāhu pa láṣẹ fún yín. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùronú-pìwàdà. Ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn olùmọ́ra.”²
1. Suddiy àti Ƙọtādah túmọ̀ “’athā” sí “ìdọ̀tí”, Mujāhid túmọ̀ rẹ̀ sí “ẹ̀jẹ̀”. (Tọbariy).
2. عَنْ أَنَسٍ أَنَّ الْيَهُودَ كَانُوا إِذَا حَاضَتِ الْمَرْأَةُ فِيهِمْ لَمْ يُؤَاكِلُوهَا وَلَمْ يُجَامِعُوهُنَّ فِى الْبُيُوتِ فَسَأَلَ أَصْحَابُ النَّبِىِّ -صلى الله عليه وسلم- النَّبِىَّ -صلى الله عليه وسلم- فَأَنْزَلَ اللَّهُ تَعَالَى ( وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الْمَحِيضِ قُلْ هُوَ أَذًى فَاعْتَزِلُوا النِّسَاءَ فِى الْمَحِيضِ) إِلَى آخِرِ الآيَةِ فَقَالَ رَسُولُ اللَّهِ -صلى الله عليه وسلم- « اصْنَعُوا كُلَّ شَىْءٍ إِلاَّ النِّكَاحَ ».
Láti ọ̀dọ̀ ’Anas - kí Allāhu yọ́nú sí i -, “Dájúdájú àwọn yẹ̀húdí, nígbàkígbà tí obìnrin kan nínú wọn bá ń ṣe héélà lọ́wọ́, wọn kò níí bá jẹun papọ̀, wọn kò níí súnmọ́ ọn nínú ilé. Àwọn Sọhābah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì bi Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - léèrè. Allāhu - tó ga jùlọ - sì sọ āyah yìí kalẹ̀. Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé, “Ẹ ṣe gbogbo n̄ǹkan àfi ìtìbọ̀.”
Muslim ló gbà á wá. Ìyẹn ni pé, “Ẹ bá oníhéélà jẹun, ẹ bá a ṣeré, ẹ dìmọ́ ọn, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́dọ̀ ti kálámù bọ inú ìgò tàdáà àfi lẹ́yìn ìmọ́ra àti ìwẹ̀ ìmọ́ra.”
Allāhu kò níí fi ìbúra yín tí kò ti inú yín wá bi yín, ṣùgbọ́n Ó máa fi ohun tí ó bá ti inú ọkàn yín wá bi yín. Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà.
Nígbà tí wọ́n jáde sí Jālūt àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sọ pé: “Olúwa wa, fún wa ní omi sùúrù mu, fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ ṣinṣin, kí O sì ràn wá lọ́wọ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.”
Wọ́n sì ṣẹ́gun wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Dāwūd pa Jālūt. Allāhu sì fún un ní ìjọba àti ọgbọ́n. Ó tún fi ìmọ̀ mọ̀ ọ́n nínú ohun tí Ó fẹ́. Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, orí ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n Allāhu ni Olóore àjùlọ lórí gbogbo ẹ̀dá.
Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí wọ́n máa da yín padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ (nípa) ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Àti pé tí ẹ bá wà lórí ìrìn-àjò, tí ẹ̀yin kò sì rí akọ̀wé, ẹ gba ohun ìdógò. (Ṣùgbọ́n) tí apá kan yín bá fi ọkàn tán apá kan, kí ẹni tí wọ́n fi ọkàn tán dá ohun tí wọ́n fi ọkàn tán an lé lórí padà, kí ó sì bẹ̀rù Allāhu, Olúwa rẹ̀. Ẹ má ṣe fi ẹ̀rí pamọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi pamọ́, dájúdájú ọkàn rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe.
Contents of the translations can be downloaded and re-published, with the following terms and conditions:
1. No modification, addition, or deletion of the content.
2. Clearly referring to the publisher and the source (QuranEnc.com).
3. Mentioning the version number when re-publishing the translation.
4. Keeping the transcript information inside the document.
5. Notifying the source (QuranEnc.com) of any note on the translation.
6. Updating the translation according to the latest version issued from the source (QuranEnc.com).
7. Inappropriate advertisements must not be included when displaying translations of the meanings of the Noble Quran.
Hasil pencarian:
API specs
Endpoints:
Sura translation
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/sura/{translation_key}/{sura_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified sura (by its number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114)
Returns:
json object containing array of objects, each object contains the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/aya/{translation_key}/{sura_number}/{aya_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified aya (by its number sura_number and aya_number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114) aya_number: [1-...] (Aya number in the sura)
Returns:
json object containing the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".