Terjemahan makna Alquran Alkarim - Terjemahan Berbahasa Yoruba * - Daftar isi terjemahan

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Terjemahan makna Surah: Surah Fāṭir   Ayah:

Suuratu Faatir

ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ فَاطِرِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ جَاعِلِ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ رُسُلًا أُوْلِيٓ أَجۡنِحَةٖ مَّثۡنَىٰ وَثُلَٰثَ وَرُبَٰعَۚ يَزِيدُ فِي ٱلۡخَلۡقِ مَا يَشَآءُۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (Ẹni tí) Ó ṣe àwọn mọlāika alápá méjì àti mẹ́ta àti mẹ́rin ní Òjíṣẹ́. Ó ń ṣe àlékún ohun tí Ó bá fẹ́ lára ẹ̀dá. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.¹
1. Àgbọ́yé òǹkà tí ó jẹyọ nínú sūrah an-Nisā’; 4:3 ni àgbọ́yé òǹkà tó tún jẹyọ nínú āyah yìí. Èyí túmọ̀ sí pé, alápá méjì wà nínú àwọn mọlāika, alápá mẹ́ta wà nínú wọn, alápá mẹ́rin sì wà nínú wọn. Alápá púpọ̀, tí apá rẹ̀ lé ní mẹ́rin, tún wà nínú wọn.
Tafsir berbahasa Arab:
مَّا يَفۡتَحِ ٱللَّهُ لِلنَّاسِ مِن رَّحۡمَةٖ فَلَا مُمۡسِكَ لَهَاۖ وَمَا يُمۡسِكۡ فَلَا مُرۡسِلَ لَهُۥ مِنۢ بَعۡدِهِۦۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Ohunkóhun tí Allāhu bá ṣí ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìkẹ́ fún àwọn ènìyàn, kò sí ẹni tí ó lè dì í mọ́wọ́ (láti dá a dúró). Ohunkóhun tí Ó bá sì mú dání, kò sí ẹni tí ó lè mú un wá lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Tafsir berbahasa Arab:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡۚ هَلۡ مِنۡ خَٰلِقٍ غَيۡرُ ٱللَّهِ يَرۡزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۚ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَأَنَّىٰ تُؤۡفَكُونَ
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín. Ǹjẹ́ ẹ̀lẹ́dàá kan yàtọ̀ sí Allāhu tún wà tí ó ń pèsè fún yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?
Tafsir berbahasa Arab:
وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدۡ كُذِّبَتۡ رُسُلٞ مِّن قَبۡلِكَۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ
Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ kan ní òpùrọ́ ṣíwájú rẹ. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
Tafsir berbahasa Arab:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞۖ فَلَا تَغُرَّنَّكُمُ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا وَلَا يَغُرَّنَّكُم بِٱللَّهِ ٱلۡغَرُورُ
Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìṣẹ̀mí ayé tàn yín jẹ. Kí ẹ sì má ṣe jẹ́ kí (Èṣù) ẹlẹ́tàn tàn yín jẹ.
Tafsir berbahasa Arab:
إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ لَكُمۡ عَدُوّٞ فَٱتَّخِذُوهُ عَدُوًّاۚ إِنَّمَا يَدۡعُواْ حِزۡبَهُۥ لِيَكُونُواْ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلسَّعِيرِ
Dájúdájú Èṣù ni ọ̀tá fún yín. Nítorí náà, ẹ mú un ní ọ̀tá. Ó kàn ń pe àwọn ìjọ rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè jẹ́ èrò inú Iná tó ń jó.
Tafsir berbahasa Arab:
ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدٞۖ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَأَجۡرٞ كَبِيرٌ
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, ìyà líle ń bẹ fún wọn. Àwọn tó sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, àforíjìn àti ẹ̀san tó tóbi ń bẹ fún wọn.
Tafsir berbahasa Arab:
أَفَمَن زُيِّنَ لَهُۥ سُوٓءُ عَمَلِهِۦ فَرَءَاهُ حَسَنٗاۖ فَإِنَّ ٱللَّهَ يُضِلُّ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُۖ فَلَا تَذۡهَبۡ نَفۡسُكَ عَلَيۡهِمۡ حَسَرَٰتٍۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِمَا يَصۡنَعُونَ
Ṣé ẹni tí wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú ọwọ́ rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún, tí ó sì ń rí i ní (iṣẹ́) dáadáa, (l’o fẹ́ máa banújẹ́ nítorí rẹ̀?) Dájúdájú Allāhu ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Nítorí náà, má ṣe fi ìbanújẹ́ pa ara rẹ̀ nítorí tiwọn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Tafsir berbahasa Arab:
وَٱللَّهُ ٱلَّذِيٓ أَرۡسَلَ ٱلرِّيَٰحَ فَتُثِيرُ سَحَابٗا فَسُقۡنَٰهُ إِلَىٰ بَلَدٖ مَّيِّتٖ فَأَحۡيَيۡنَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَاۚ كَذَٰلِكَ ٱلنُّشُورُ
Allāhu ni Ẹni tí Ó fi àwọn atẹ́gùn ránṣẹ́. (Atẹ́gùn náà) sì máa tú ẹ̀ṣújò sókè. A sì fi fún ìlú (tí ilẹ̀ rẹ̀) ti kú lómi mu. A sì fi ta ilẹ̀ náà jí lẹ́yìn tí ó ti kú. Báyẹn ni àjíǹde (ẹ̀dá yó ṣe rí).
Tafsir berbahasa Arab:
مَن كَانَ يُرِيدُ ٱلۡعِزَّةَ فَلِلَّهِ ٱلۡعِزَّةُ جَمِيعًاۚ إِلَيۡهِ يَصۡعَدُ ٱلۡكَلِمُ ٱلطَّيِّبُ وَٱلۡعَمَلُ ٱلصَّٰلِحُ يَرۡفَعُهُۥۚ وَٱلَّذِينَ يَمۡكُرُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدٞۖ وَمَكۡرُ أُوْلَٰٓئِكَ هُوَ يَبُورُ
Ẹní tí ó bá ń fẹ́ iyì dájúdájú ti Allāhu ni gbogbo iyì pátápátá. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ dáadáa ń gòkè lọ. Ó sì ń gbé iṣẹ́ rere gòkè (sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀). Àwọn tí wọ́n ń pète àwọn aburú, ìyà líle ń bẹ fún wọn. Ète àwọn wọ̀nyẹn sì máa parun.
Tafsir berbahasa Arab:
وَٱللَّهُ خَلَقَكُم مِّن تُرَابٖ ثُمَّ مِن نُّطۡفَةٖ ثُمَّ جَعَلَكُمۡ أَزۡوَٰجٗاۚ وَمَا تَحۡمِلُ مِنۡ أُنثَىٰ وَلَا تَضَعُ إِلَّا بِعِلۡمِهِۦۚ وَمَا يُعَمَّرُ مِن مُّعَمَّرٖ وَلَا يُنقَصُ مِنۡ عُمُرِهِۦٓ إِلَّا فِي كِتَٰبٍۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٞ
Allāhu da yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ó tún da yín) láti ara àtọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó ṣe yín ní akọ-abo. Obìnrin kan kò níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àti pé A kò níí fa ẹ̀mí ẹlẹ́mìí-gígùn gùn, A kò sì ní ṣe àdínkù nínú ọjọ́ orí (ẹlòmíìràn), àfi kí ó ti wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu.
Tafsir berbahasa Arab:
وَمَا يَسۡتَوِي ٱلۡبَحۡرَانِ هَٰذَا عَذۡبٞ فُرَاتٞ سَآئِغٞ شَرَابُهُۥ وَهَٰذَا مِلۡحٌ أُجَاجٞۖ وَمِن كُلّٖ تَأۡكُلُونَ لَحۡمٗا طَرِيّٗا وَتَسۡتَخۡرِجُونَ حِلۡيَةٗ تَلۡبَسُونَهَاۖ وَتَرَى ٱلۡفُلۡكَ فِيهِ مَوَاخِرَ لِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Àwọn odò méjì náà kò dọ́gba; èyí ni (omi) dídùn gan-an, tí mímu rẹ̀ ń lọ tìnrín ní ọ̀fun. Èyí sì ni (omi) iyọ̀ tó móró. Àti pé nínú gbogbo (omi odò wọ̀nyí) l’ẹ ti ń jẹ ẹran (odò àti ẹja) tútù. Ẹ sì ń wa kùsà àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ẹ̀ ń wọ̀ (sára). O sì ń rí àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń la ààrin omi kọjá nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Allāhu àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).
Tafsir berbahasa Arab:
يُولِجُ ٱلَّيۡلَ فِي ٱلنَّهَارِ وَيُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِي ٱلَّيۡلِ وَسَخَّرَ ٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ كُلّٞ يَجۡرِي لِأَجَلٖ مُّسَمّٗىۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ لَهُ ٱلۡمُلۡكُۚ وَٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ مَا يَمۡلِكُونَ مِن قِطۡمِيرٍ
(Allāhu) ń ti òru bọ inú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọ inú òru. Ó rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn máa rìn fún gbèdéke àkókò kan.¹ Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Àwọn tí ẹ sì ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò ní ìkápá kan lórí èpo kóró inú dàbínù.
1. Gbèdéke àkókò náà ni òpin ayé.
Tafsir berbahasa Arab:
إِن تَدۡعُوهُمۡ لَا يَسۡمَعُواْ دُعَآءَكُمۡ وَلَوۡ سَمِعُواْ مَا ٱسۡتَجَابُواْ لَكُمۡۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يَكۡفُرُونَ بِشِرۡكِكُمۡۚ وَلَا يُنَبِّئُكَ مِثۡلُ خَبِيرٖ
Tí ẹ bá pè wọ́n, wọn kò lè gbọ́ ìpè yín. Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n gbọ́, wọn kò lè da yín lóhùn. Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yóò tako bí ẹ ṣe fi wọ́n ṣe akẹgbẹ́ fún Allāhu. Kò sì sí ẹni tí ó lè fún ọ ní ìró kan (nípa ẹ̀dá ju) irú (ìró tí) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ (fún ọ nípa wọn).
Tafsir berbahasa Arab:
۞ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ أَنتُمُ ٱلۡفُقَرَآءُ إِلَى ٱللَّهِۖ وَٱللَّهُ هُوَ ٱلۡغَنِيُّ ٱلۡحَمِيدُ
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ni aláìní (tí ẹ ní bùkátà) sí Allāhu. Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.
Tafsir berbahasa Arab:
إِن يَشَأۡ يُذۡهِبۡكُمۡ وَيَأۡتِ بِخَلۡقٖ جَدِيدٖ
Tí Ó bá fẹ́, Ó máa mu yín kúrò lórí ilẹ̀. Ó sì máa mú ẹ̀dá titun wá.
Tafsir berbahasa Arab:
وَمَا ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ بِعَزِيزٖ
Ìyẹn kò sì lágbara kan lára Allāhu.¹
1. Kò kó wàhálà kan bá Allāhu Ẹlẹ́dàá.
Tafsir berbahasa Arab:
وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٞ وِزۡرَ أُخۡرَىٰۚ وَإِن تَدۡعُ مُثۡقَلَةٌ إِلَىٰ حِمۡلِهَا لَا يُحۡمَلۡ مِنۡهُ شَيۡءٞ وَلَوۡ كَانَ ذَا قُرۡبَىٰٓۗ إِنَّمَا تُنذِرُ ٱلَّذِينَ يَخۡشَوۡنَ رَبَّهُم بِٱلۡغَيۡبِ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَۚ وَمَن تَزَكَّىٰ فَإِنَّمَا يَتَزَكَّىٰ لِنَفۡسِهِۦۚ وَإِلَى ٱللَّهِ ٱلۡمَصِيرُ
Ẹlẹ́rù ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Kódà kí ẹnì kan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ lọ́rùn ké sí (ẹlòmíìràn) fún àbárù ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, wọn kò níí bá a ru kiní kan nínú rẹ̀, ìbáà jẹ́ ìbátan.¹ Àwọn tí ò ń ṣèkìlọ̀ fún ni àwọn tó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, tí wọ́n sì ń kírun. Ẹni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀), ó ṣàfọ̀mọ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nahl; 16:25.
Tafsir berbahasa Arab:
وَمَا يَسۡتَوِي ٱلۡأَعۡمَىٰ وَٱلۡبَصِيرُ
Afọ́jú àti olùríran kò dọ́gba.
Tafsir berbahasa Arab:
وَلَا ٱلظُّلُمَٰتُ وَلَا ٱلنُّورُ
Àwọn òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ (kò dọ́gba).
Tafsir berbahasa Arab:
وَلَا ٱلظِّلُّ وَلَا ٱلۡحَرُورُ
Àwọn ibòji àti ìgbóná òòrùn (kò dọ́gba).
Tafsir berbahasa Arab:
وَمَا يَسۡتَوِي ٱلۡأَحۡيَآءُ وَلَا ٱلۡأَمۡوَٰتُۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُسۡمِعُ مَن يَشَآءُۖ وَمَآ أَنتَ بِمُسۡمِعٖ مَّن فِي ٱلۡقُبُورِ
Àwọn alààyè àti òkú kò dọ́gba. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀rọ̀ gbọ́. Ìwọ kò sì lè fún ẹni tí ó wà nínú sàréè ní ọ̀rọ̀ gbọ́.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Naml; 27:81.
Tafsir berbahasa Arab:
إِنۡ أَنتَ إِلَّا نَذِيرٌ
Ìwọ kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀.
Tafsir berbahasa Arab:
إِنَّآ أَرۡسَلۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ بَشِيرٗا وَنَذِيرٗاۚ وَإِن مِّنۡ أُمَّةٍ إِلَّا خَلَا فِيهَا نَذِيرٞ
Dájúdájú Àwa fi òdodo rán ọ níṣẹ́. (O sì jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Kò sí ìjọ kan (ṣíwájú rẹ) àfi kí olùkìlọ̀ ti rè kọjá láààrin wọn.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus 10; 47.
Tafsir berbahasa Arab:
وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدۡ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَبِٱلزُّبُرِ وَبِٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُنِيرِ
Tí wọ́n bá sì ń pè ọ́ ní òpùrọ́, àwọn tó ṣíwájú wọn náà kúkú pe (ọ̀rọ̀ Allāhu) ní irọ́ (nígbà tí) àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, àwọn ìpín-ìpín Tírà àti Tírà tó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.
Tafsir berbahasa Arab:
ثُمَّ أَخَذۡتُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۖ فَكَيۡفَ كَانَ نَكِيرِ
Lẹ́yìn náà, Mo gbá àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ mú. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!
Tafsir berbahasa Arab:
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَخۡرَجۡنَا بِهِۦ ثَمَرَٰتٖ مُّخۡتَلِفًا أَلۡوَٰنُهَاۚ وَمِنَ ٱلۡجِبَالِ جُدَدُۢ بِيضٞ وَحُمۡرٞ مُّخۡتَلِفٌ أَلۡوَٰنُهَا وَغَرَابِيبُ سُودٞ
Ṣé o kò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀? A sì fi mú àwọn èso tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn jáde. Àti pé àwọn ojú ọ̀nà funfun àti pupa tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn àti aláwọ̀ dúdú kirikiri wà nínú àwọn àpáta.
Tafsir berbahasa Arab:
وَمِنَ ٱلنَّاسِ وَٱلدَّوَآبِّ وَٱلۡأَنۡعَٰمِ مُخۡتَلِفٌ أَلۡوَٰنُهُۥ كَذَٰلِكَۗ إِنَّمَا يَخۡشَى ٱللَّهَ مِنۡ عِبَادِهِ ٱلۡعُلَمَٰٓؤُاْۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ غَفُورٌ
Àti pé ó wà nínú àwọn ènìyàn, àwọn n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti àwọn ẹran-ọ̀sìn tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra wọn, gẹ́gẹ́ bí (àwọ̀ èso àti àpáta) wọ̀nyẹn (ṣe yàtọ̀ síra wọn). Àwọn tó ń páyà Allāhu nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ni àwọn onímọ̀ (tí wọ́n mọ̀ pé), dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Aláforíjìn.¹
1. Àìmọ̀kan kò ṣeé lò láti fi páyà Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - . Aláìmọ̀kan yóò máa ṣe àwọn kiní kàn tí ó máa lérò pé òun ń fi páyà Allāhu ni, àmọ́ tó jẹ́ pé ńṣe l’ó ń da ara rẹ̀ láàmú. Ìmọ̀ nípa Allāhu ni ènìyàn lè fi páyà Allāhu ní ọ̀nà òtítọ́ àti ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ìmọ̀ náà ní àsìkò yìí ni ìmọ̀ al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - . Méjèèjì l’ó máa jogún ìpáyà Allāhu fún olówó rẹ̀.
Kíyè sí i! Tí a bá rí onímímọ̀ ẹ̀sìn tí kì í páyà Allāhu, ó wù ú bẹ́ẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni. Kì í ṣe pé ìmọ̀ nípa Allāhu l’ó sọ ọ́ di bẹ́ẹ̀. Àpẹ̀ẹrẹ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn onibidiah. Nítorí náà, tí ẹ̀dá bá kéú tán, tó sọ bidiah di iṣẹ́, tó kúndùn bidiah ju sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - , Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ti yọ barka “ìbùkún” kúrò nínú ìmọ̀ rẹ̀ nìyẹn. Ẹ ka sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:175 àti 176 kí ẹ rí àpẹ̀ẹrẹ irú wọn.
Tafsir berbahasa Arab:
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَتۡلُونَ كِتَٰبَ ٱللَّهِ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَنفَقُواْ مِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ سِرّٗا وَعَلَانِيَةٗ يَرۡجُونَ تِجَٰرَةٗ لَّن تَبُورَ
Dájúdájú àwọn tó ń ké tírà Allāhu, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń ná nínú n̄ǹkan tí A ṣe ní arísìkí fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba, wọ́n ń nírètí sí òwò kan tí kò níí parun.
Tafsir berbahasa Arab:
لِيُوَفِّيَهُمۡ أُجُورَهُمۡ وَيَزِيدَهُم مِّن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ غَفُورٞ شَكُورٞ
(Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́.¹
1. Nínú orúkọ àti ìròyìn Allāhu ni “Ṣākir” àti “Ṣakūr”. Ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ méjèèjì ni “ṣukr” (ọpẹ́ / mímọ rírì oore àti sísọ ọ́). Pípe Allāhu ní “Ṣākir” àti “Ṣakūr” sì ń túmọ̀ sí Ẹni tí Ó mọ rírì iṣẹ́ rere tí ẹ̀dá ṣe, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ó fi ń sọ ẹ̀san iṣẹ́ rere náà di àdìpèlé fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Nítorí náà, tí a bá sọ pé, “Allāhu á dúpẹ́ fún ọ.”, ó ń túmọ̀ sí pé, “Allāhu kò níí fi láádá iṣẹ́ rere rẹ dùn ọ́, Allāhu á sì san ọ́ ní ẹ̀san rere àdìpèlé lórí rẹ̀.”
Tafsir berbahasa Arab:
وَٱلَّذِيٓ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ هُوَ ٱلۡحَقُّ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِۗ إِنَّ ٱللَّهَ بِعِبَادِهِۦ لَخَبِيرُۢ بَصِيرٞ
Ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà, òhun ni òdodo tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
Tafsir berbahasa Arab:
ثُمَّ أَوۡرَثۡنَا ٱلۡكِتَٰبَ ٱلَّذِينَ ٱصۡطَفَيۡنَا مِنۡ عِبَادِنَاۖ فَمِنۡهُمۡ ظَالِمٞ لِّنَفۡسِهِۦ وَمِنۡهُم مُّقۡتَصِدٞ وَمِنۡهُمۡ سَابِقُۢ بِٱلۡخَيۡرَٰتِ بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَضۡلُ ٱلۡكَبِيرُ
Lẹ́yìn náà, A jogún tírà (al-Ƙur’ān) fún àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Nítorí náà, alábòsí tó ń bo ẹ̀mí ara rẹ̀ sí wà nínú wọn. Olùṣe-déédé wà nínú wọn. Olùgbawájú níbi àwọn iṣẹ́ rere tún wà nínú wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ìyẹn sì ni oore àjùlọ tó tóbi.¹
1. Nínú āyah yìí, alábòsí tó ń bo ẹ̀mí ara rẹ̀ sí ni ẹni tí ó géwọ́ kúrú níbi àwọn n̄ǹkan ọ̀ran-anyàn nínú ẹ̀sìn. Olùṣe-déédé ni ẹni tó ń ṣe ọ̀wọ́ àwọn n̄ǹkan ọ̀ran-anyàn nínú ẹ̀sìn. Olùgbawájú níbi àwọn iṣẹ́ rere ni ẹni tó ń ṣe àwọn n̄ǹkan ọ̀ran-anyàn àti àwọn n̄ǹkan àṣegbọrẹ papọ̀ nínú ẹ̀sìn.
Tafsir berbahasa Arab:
جَنَّٰتُ عَدۡنٖ يَدۡخُلُونَهَا يُحَلَّوۡنَ فِيهَا مِنۡ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٖ وَلُؤۡلُؤٗاۖ وَلِبَاسُهُمۡ فِيهَا حَرِيرٞ
Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọn yóò wọ inú rẹ̀. Àwọn kerewú wúrà àti òkúta olówó iyebíye ni A óò máa fi ṣe ọ̀ṣọ́ fún wọn nínú rẹ̀. Àti pé aṣọ àláárì ni aṣọ wọn nínú rẹ̀.
Tafsir berbahasa Arab:
وَقَالُواْ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِيٓ أَذۡهَبَ عَنَّا ٱلۡحَزَنَۖ إِنَّ رَبَّنَا لَغَفُورٞ شَكُورٌ
Wọ́n yóò sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó mú ìbànújẹ́ kúrò fún wa. Dájúdájú Olúwa wa ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́,¹
1. Nínú orúkọ àti ìròyìn Allāhu ni “Ṣākir” àti “Ṣakūr”. Ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ méjèèjì ni “ṣukr” (ọpẹ́ / mímọ rírì oore àti sísọ ọ́). Pípe Allāhu ní “Ṣākir” àti “Ṣakūr” sì ń túmọ̀ sí Ẹni tí Ó mọ rírì iṣẹ́ rere tí ẹ̀dá ṣe, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ó fi ń sọ ẹ̀san iṣẹ́ rere náà di àdìpèlé fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Nítorí náà, tí a bá sọ pé, “Allāhu á dúpẹ́ fún ọ.”, ó ń túmọ̀ sí pé, “Allāhu kò níí fi láádá iṣẹ́ rere rẹ dùn ọ́, Allāhu á sì san ọ́ ní ẹ̀san rere àdìpèlé lórí rẹ̀.”
Tafsir berbahasa Arab:
ٱلَّذِيٓ أَحَلَّنَا دَارَ ٱلۡمُقَامَةِ مِن فَضۡلِهِۦ لَا يَمَسُّنَا فِيهَا نَصَبٞ وَلَا يَمَسُّنَا فِيهَا لُغُوبٞ
Ẹni tí Ó sọ̀ wá kalẹ̀ sínú ibùgbé gbére nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Wàhálà kan kò níí kàn wá nínú rẹ̀. Ìkáàárẹ̀ kan kò sì níí bá wa nínú rẹ̀.
Tafsir berbahasa Arab:
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَهُمۡ نَارُ جَهَنَّمَ لَا يُقۡضَىٰ عَلَيۡهِمۡ فَيَمُوتُواْ وَلَا يُخَفَّفُ عَنۡهُم مِّنۡ عَذَابِهَاۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي كُلَّ كَفُورٖ
Àti pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. A ò níí pa wọ́n (sínú rẹ̀), áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò kú. A ò níí ṣe ìyà inú rẹ̀ ní fífúyẹ́ fún wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ ní ẹ̀san.
Tafsir berbahasa Arab:
وَهُمۡ يَصۡطَرِخُونَ فِيهَا رَبَّنَآ أَخۡرِجۡنَا نَعۡمَلۡ صَٰلِحًا غَيۡرَ ٱلَّذِي كُنَّا نَعۡمَلُۚ أَوَلَمۡ نُعَمِّرۡكُم مَّا يَتَذَكَّرُ فِيهِ مَن تَذَكَّرَ وَجَآءَكُمُ ٱلنَّذِيرُۖ فَذُوقُواْ فَمَا لِلظَّٰلِمِينَ مِن نَّصِيرٍ
Wọn yóò máa lọgun ìrànlọ́wọ́ nínú rẹ̀ pé: “Olúwa wa, mú wa jáde nítorí kí á lè lọ́ ṣe iṣẹ́ rere, yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe.” Ṣé A ò fún yín ní ẹ̀mí gígùn lò tó fún ẹni tí ọ́ bá fẹ́ lo ìṣítí láti rí i lò nínú àsìkò náà ni? Olùkìlọ̀ sì wá ba yín. Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí.
Tafsir berbahasa Arab:
إِنَّ ٱللَّهَ عَٰلِمُ غَيۡبِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ
Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
Tafsir berbahasa Arab:
هُوَ ٱلَّذِي جَعَلَكُمۡ خَلَٰٓئِفَ فِي ٱلۡأَرۡضِۚ فَمَن كَفَرَ فَعَلَيۡهِ كُفۡرُهُۥۖ وَلَا يَزِيدُ ٱلۡكَٰفِرِينَ كُفۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ إِلَّا مَقۡتٗاۖ وَلَا يَزِيدُ ٱلۡكَٰفِرِينَ كُفۡرُهُمۡ إِلَّا خَسَارٗا
Òun ní Ẹni tó ń fi yín ṣe àrólé lórí ilẹ̀. Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, (ìyà) àìgbàgbọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Àìgbàgbọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì níí fún wọn ní àlékún kan lọ́dọ̀ Olúwa wọn bí kò ṣe ìbínú. Àìgbàgbọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì níí fún wọn ní àlékún kan bí kò ṣe òfò.
Tafsir berbahasa Arab:
قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ شُرَكَآءَكُمُ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُواْ مِنَ ٱلۡأَرۡضِ أَمۡ لَهُمۡ شِرۡكٞ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ أَمۡ ءَاتَيۡنَٰهُمۡ كِتَٰبٗا فَهُمۡ عَلَىٰ بَيِّنَتٖ مِّنۡهُۚ بَلۡ إِن يَعِدُ ٱلظَّٰلِمُونَ بَعۡضُهُم بَعۡضًا إِلَّا غُرُورًا
Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa àwọn òrìṣà yín tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹ fi ohun tí wọ́n dá hàn mí lórí ilẹ̀? Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) níbi (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Tàbí A fún wọn ní tírà kan, tí wọ́n ní ẹ̀rí tó yanjú lọ́wọ́ nínú rẹ̀? Rárá o! Kò sí àdéhùn kan tí àwọn alábòsí, apá kan wọn ń ṣe fún apá kan bí kò ṣe ẹ̀tàn.”
Tafsir berbahasa Arab:
۞ إِنَّ ٱللَّهَ يُمۡسِكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ أَن تَزُولَاۚ وَلَئِن زَالَتَآ إِنۡ أَمۡسَكَهُمَا مِنۡ أَحَدٖ مِّنۢ بَعۡدِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ كَانَ حَلِيمًا غَفُورٗا
Dájúdájú Allāhu l’Ó ń mú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró ṣinṣin tí wọn kò fi yẹ̀ lulẹ̀. Dájúdájú tí wọ́n bá sì yẹ̀ lulẹ̀, kò sí ẹnì kan kan tí ó máa mú un dúró lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláfaradà, Aláforíjìn.
Tafsir berbahasa Arab:
وَأَقۡسَمُواْ بِٱللَّهِ جَهۡدَ أَيۡمَٰنِهِمۡ لَئِن جَآءَهُمۡ نَذِيرٞ لَّيَكُونُنَّ أَهۡدَىٰ مِنۡ إِحۡدَى ٱلۡأُمَمِۖ فَلَمَّا جَآءَهُمۡ نَذِيرٞ مَّا زَادَهُمۡ إِلَّا نُفُورًا
Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé: “Dájúdájú tí olùkìlọ̀ kan bá fi lè wá bá àwọn, dájúdájú àwọn yóò mọ̀nà tààrà ju èyíkéyìí nínú ìjọ (tó ti ṣíwájú).” Nígbà tí olùkìlọ̀ kan sì wá bá wọn, (èyí) kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe sísá (fún òdodo)
Tafsir berbahasa Arab:
ٱسۡتِكۡبَارٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَكۡرَ ٱلسَّيِّيِٕۚ وَلَا يَحِيقُ ٱلۡمَكۡرُ ٱلسَّيِّئُ إِلَّا بِأَهۡلِهِۦۚ فَهَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّا سُنَّتَ ٱلۡأَوَّلِينَۚ فَلَن تَجِدَ لِسُنَّتِ ٱللَّهِ تَبۡدِيلٗاۖ وَلَن تَجِدَ لِسُنَّتِ ٱللَّهِ تَحۡوِيلًا
ní ti ṣíṣe ìgbéraga lórí ilẹ̀ àti ní ti ète aburú. Ète aburú kò sì níí yí ẹnì kan po àfi oníṣẹ́ aburú. Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe ìṣe(Allāhu lórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́?¹ Nítorí náà, o ò níí rí ìpààrọ̀ fún ìṣe Allāhu. Àní sẹ́, o ò níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Hijr; 15:13.
Tafsir berbahasa Arab:
أَوَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ وَكَانُوٓاْ أَشَدَّ مِنۡهُمۡ قُوَّةٗۚ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُعۡجِزَهُۥ مِن شَيۡءٖ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّهُۥ كَانَ عَلِيمٗا قَدِيرٗا
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n sì ní agbára ju àwọn (wọ̀nyí) lọ! Àti pé kò sí kiní kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tí ó lè mórí bọ́ lọ́wọ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Alágbára.
Tafsir berbahasa Arab:
وَلَوۡ يُؤَاخِذُ ٱللَّهُ ٱلنَّاسَ بِمَا كَسَبُواْ مَا تَرَكَ عَلَىٰ ظَهۡرِهَا مِن دَآبَّةٖ وَلَٰكِن يُؤَخِّرُهُمۡ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗىۖ فَإِذَا جَآءَ أَجَلُهُمۡ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِعِبَادِهِۦ بَصِيرَۢا
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu yó (tètè) máa mú ènìyàn pẹ̀lú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ni, ìbá tí ṣẹ́ ku n̄ǹkan ẹlẹ́mìí kan kan mọ́ lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń lọ́ wọn lára di gbèdéke àkókò kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
Tafsir berbahasa Arab:
 
Terjemahan makna Surah: Surah Fāṭir
Daftar surah Nomor Halaman
 
Terjemahan makna Alquran Alkarim - Terjemahan Berbahasa Yoruba - Daftar isi terjemahan

Terjemahan makna Al-Qur`ān Al-Karīm ke bahasa Yoruba oleh Syekh Abu Rahimah Mikael Aykoyini. Cetakan tahun 1432 H.

Tutup