Check out the new design

Terjemahan makna Alquran Alkarim - Terjemahan Berbahasa Yoruba - Abu Rahimah Mikael * - Daftar isi terjemahan

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Terjemahan makna Surah: Al-Māidah   Ayah:
وَمَا لَنَا لَا نُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَمَا جَآءَنَا مِنَ ٱلۡحَقِّ وَنَطۡمَعُ أَن يُدۡخِلَنَا رَبُّنَا مَعَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلصَّٰلِحِينَ
Kí ni ó máa dí wa lọ́wọ́ tí a ò fi níí gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí ó dé bá wa nínú òdodo (ìyẹn, al-Ƙur’ān), tí a sì ń jẹ̀rankàn pé kí Olúwa wa fi wá sínú àwọn ẹni-ire.”
Tafsir berbahasa Arab:
فَأَثَٰبَهُمُ ٱللَّهُ بِمَا قَالُواْ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ وَذَٰلِكَ جَزَآءُ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Nítorí náà, nítorí ohun tí wọ́n sọ, Allāhu san wọ́n ní ẹ̀san pẹ̀lú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san fún àwọn olùṣe-rere.
Tafsir berbahasa Arab:
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَآ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَحِيمِ
Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm.[1]
1. Al-Ƙur’ān pín ìjọ nasọ̄rọ̄ sí méjì; ìkíní ni igun tí àwọn ìròyìn tó wà nínú āyah 82 sí 84 nínú sūrah yìí wà lára rẹ̀. Igun yìí ló máa ń padà gba ’Islām ṣíwájú ọjọ́ ikú wọn. Igun yìí nìkan ló sì máa bá àwa mùsùlùmí wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú āyah 85 nínú sūrah yìí. Igun kejì ni àwọn nasọ̄rọ̄ tí kò ní àwọn ìròyìn wọ̀nyẹn lára. Igun yìí ló máa ń takú sínú ẹ̀sìn nasọ̄rọ̄ lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān ti dé etí ìgbọ́ wọn. Igun yìí ló sì máa wà pẹ̀lú àwọn yẹhudi àti ọ̀ṣẹbọ nínú Iná gbére.
Tafsir berbahasa Arab:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تُحَرِّمُواْ طَيِّبَٰتِ مَآ أَحَلَّ ٱللَّهُ لَكُمۡ وَلَا تَعۡتَدُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُعۡتَدِينَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe sọ àwọn n̄ǹkan dáadáa tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún yín di èèwọ̀. Ẹ sì má ṣe tayọ ẹnu-ààlà. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà.
Tafsir berbahasa Arab:
وَكُلُواْ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ حَلَٰلٗا طَيِّبٗاۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِيٓ أَنتُم بِهِۦ مُؤۡمِنُونَ
Ẹ jẹ n̄ǹkan ẹ̀tọ́ tó dára nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún yín. Àti pé ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́ nínú Rẹ̀.
Tafsir berbahasa Arab:
لَا يُؤَاخِذُكُمُ ٱللَّهُ بِٱللَّغۡوِ فِيٓ أَيۡمَٰنِكُمۡ وَلَٰكِن يُؤَاخِذُكُم بِمَا عَقَّدتُّمُ ٱلۡأَيۡمَٰنَۖ فَكَفَّٰرَتُهُۥٓ إِطۡعَامُ عَشَرَةِ مَسَٰكِينَ مِنۡ أَوۡسَطِ مَا تُطۡعِمُونَ أَهۡلِيكُمۡ أَوۡ كِسۡوَتُهُمۡ أَوۡ تَحۡرِيرُ رَقَبَةٖۖ فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ ثَلَٰثَةِ أَيَّامٖۚ ذَٰلِكَ كَفَّٰرَةُ أَيۡمَٰنِكُمۡ إِذَا حَلَفۡتُمۡۚ وَٱحۡفَظُوٓاْ أَيۡمَٰنَكُمۡۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Allāhu kò níí fí ìbúra tí ó bọ́ lẹ́nu yín bi yín, ṣùgbọ́n Ó máa fi àwọn ìbúra tí ẹ fínnúfíndọ̀ mú wá bi yín. Nítorí náà, ìtánràn rẹ̀ ni bíbọ́ tálíkà mẹ́wàá pẹ̀lú oúnjẹ tí ó wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì tí ẹ̀ ń fi bọ́ ará ilé yín, tàbí kí ẹ raṣọ fún wọn, tàbí kí ẹ tú ẹrú kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹni tí kò bá rí (èyí ṣe), ó máa gba ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta. Ìyẹn ni ìtánràn ìbúra yín nígbà tí ẹ bá búra. Ẹ ṣọ́ ìbúra yín. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.
Tafsir berbahasa Arab:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِنَّمَا ٱلۡخَمۡرُ وَٱلۡمَيۡسِرُ وَٱلۡأَنصَابُ وَٱلۡأَزۡلَٰمُ رِجۡسٞ مِّنۡ عَمَلِ ٱلشَّيۡطَٰنِ فَٱجۡتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ọtí,[1] tẹ́tẹ́, àwọn òrìṣà àti iṣẹ́ yíyẹ̀wò², ẹ̀gbin nínú iṣẹ́ aṣ-Ṣaetọ̄n ni. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí i nítorí kí ẹ lè jèrè.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:219. 2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah 3.
Tafsir berbahasa Arab:
 
Terjemahan makna Surah: Al-Māidah
Daftar surah Nomor Halaman
 
Terjemahan makna Alquran Alkarim - Terjemahan Berbahasa Yoruba - Abu Rahimah Mikael - Daftar isi terjemahan

Terjemahan oleh Syekh Abu Rahimah Mikael Aykoyini.

Tutup