Check out the new design

Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail * - Indice Traduzioni

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduzione dei significati Sura: Al-Fâtihah   Versetto:

Al-Fatiha

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.[1]
[1] Sūratun Mọkkiyyah túmọ̀ sí sūrah tí ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú Hijrah. Bákan náà, sūratun Mọdaniyyah túmọ̀ sí sūrah tí ó sọ̀kalẹ̀ lẹ́yìn Hijrah.
Esegesi in lingua araba:
ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Gbogbo ẹyìn[1] ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa[2] gbogbo ẹ̀dá (àgbáńlá ayé àti ọ̀run),
[1] Nínú èdè Lárúbáwá, “hamd” yàtọ̀ sí “ṣukr” àmọ́ ìtúmọ̀ ìkíní kejì fẹ́ súnmọ́ ara wọn. Ìtúmọ̀ “hamd” ni “ẹyìn” èyí tí a sọ jáde ní ẹnu pẹ̀lú ìfẹ́ àti gbígbé-títóbi fún ẹni tí ẹyìn tọ́ sí nítorí pé ẹni náà jẹ́ ẹni tí ó pé tán pátápátá tí kò kù sí ibì kan kan níbi pàápàá rẹ̀, àwọn ìròyìn rẹ̀ àti àwọn ìṣe rẹ̀. Kò sì sí ẹni tí ó pé tán pátápátá bí kò ṣe Allāhu - Ọba tó ga jùlọ -. Nítorí náà, Allāhu nìkan ṣoṣo ni a gbọ́dọ̀ máa yìn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ pé, Òun nìkan náà ni a gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. [2] Ọ̀rọ̀ yìí “rọbb” (Olúwa), ó kó ọ̀rọ̀ mẹ́ta sínú. Dídá ẹ̀dá, ṣíṣe ìjọba lórí ẹ̀dá tàbí níni ẹ̀dá àti dídarí ọ̀rọ̀ ẹ̀dá. Nígbà tí a bá pe Allāhu ní “rọbb” (Olúwa), gbogbo ìwọ̀nyẹn ló kó sínú nítorí pé, Allāhu ni Ẹlẹ́dàá wa, tiRẹ̀ ni ìjọba lórí gbogbo ẹ̀dá, Òun sì ni Ó ń darí kádàrá ẹ̀dá. Nítorí náà, Allāhu ni Olúwa wa.
Esegesi in lingua araba:
ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run,
Esegesi in lingua araba:
مَٰلِكِ يَوۡمِ ٱلدِّينِ
Ọba Olùkápá-ọjọ́-ẹ̀san.
Esegesi in lingua araba:
إِيَّاكَ نَعۡبُدُ وَإِيَّاكَ نَسۡتَعِينُ
Ìwọ nìkan ni à ń jọ́sìn fún. Ọ̀dọ̀ Rẹ nìkan sì ni à ń wá ìrànlọ́wọ́ sí.[1]
[1] Èyí ni àdéhùn ojoojúmọ́ tí à ń ṣe fún Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa àdéhùn náà, ó ti di ẹlẹ́bọ pọ́nńbélé títí ó fi máa ronú pìwàdà.
Esegesi in lingua araba:
ٱهۡدِنَا ٱلصِّرَٰطَ ٱلۡمُسۡتَقِيمَ
Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ l’ójú ọ̀nà tààrà (ẹ̀sìn ’Islām),[1]
[1] Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ l’ójú ọ̀nà tààrà (’Islām),
Esegesi in lingua araba:
صِرَٰطَ ٱلَّذِينَ أَنۡعَمۡتَ عَلَيۡهِمۡ غَيۡرِ ٱلۡمَغۡضُوبِ عَلَيۡهِمۡ وَلَا ٱلضَّآلِّينَ
ọ̀nà àwọn tí O ṣe ìdẹ̀ra fún, yàtọ̀ sí (ọ̀nà) àwọn ẹni-ìbínú (ìyẹn, àwọn yẹhudi) àti (ọ̀nà) àwọn olùṣìnà (ìyẹn, àwọn nasọ̄rọ̄).
Esegesi in lingua araba:
 
Traduzione dei significati Sura: Al-Fâtihah
Indice delle Sure Numero di pagina
 
Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail - Indice Traduzioni

Tradotta dallo Sheikh Abu Rahima Mikail Aikoyini.

Chiudi