Check out the new design

Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail * - Indice Traduzioni

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduzione dei significati Sura: Hûd   Versetto:
فَلَا تَكُ فِي مِرۡيَةٖ مِّمَّا يَعۡبُدُ هَٰٓؤُلَآءِۚ مَا يَعۡبُدُونَ إِلَّا كَمَا يَعۡبُدُ ءَابَآؤُهُم مِّن قَبۡلُۚ وَإِنَّا لَمُوَفُّوهُمۡ نَصِيبَهُمۡ غَيۡرَ مَنقُوصٖ
Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa ohun tí àwọn wọ̀nyí ń jọ́sìn fún. Wọn kò jọ́sìn fún kiní kan bí kò ṣe bí àwọn bàbá wọn náà ṣe ń jọ́sìn (fún àwọn òrìṣà) ní ìṣáájú. Dájúdájú Àwa yóò san wọ́n ní ẹ̀san ìpín (ìyà) wọn láì níí dín in kù.
Esegesi in lingua araba:
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ فَٱخۡتُلِفَ فِيهِۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيۡنَهُمۡۚ وَإِنَّهُمۡ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُ مُرِيبٖ
A kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa-ẹnu nípa rẹ̀. Àti pé tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan ti ṣíwájú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, Àwa ìbá ti ṣèdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa al-Ƙur’ān.
Esegesi in lingua araba:
وَإِنَّ كُلّٗا لَّمَّا لَيُوَفِّيَنَّهُمۡ رَبُّكَ أَعۡمَٰلَهُمۡۚ إِنَّهُۥ بِمَا يَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ
Dájúdájú ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni Olúwa rẹ yóò san ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn. Dájúdájú Òun ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Esegesi in lingua araba:
فَٱسۡتَقِمۡ كَمَآ أُمِرۡتَ وَمَن تَابَ مَعَكَ وَلَا تَطۡغَوۡاْۚ إِنَّهُۥ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ
Dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí A ṣe pa ìwọ àti ẹnikẹ́ni tí ó bá rónú pìwàdà pẹ̀lú rẹ láṣẹ. Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà. Dájúdájú Òun ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Esegesi in lingua araba:
وَلَا تَرۡكَنُوٓاْ إِلَى ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ فَتَمَسَّكُمُ ٱلنَّارُ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِنۡ أَوۡلِيَآءَ ثُمَّ لَا تُنصَرُونَ
Ẹ má ṣe tẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn tó ṣàbòsí nítorí kí Iná má baà fọwọ́ bà yín. Kò sì níí sí àwọn aláàbò fún yín lẹ́yìn Allāhu. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn yín lọ́wọ́.
Esegesi in lingua araba:
وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ طَرَفَيِ ٱلنَّهَارِ وَزُلَفٗا مِّنَ ٱلَّيۡلِۚ إِنَّ ٱلۡحَسَنَٰتِ يُذۡهِبۡنَ ٱلسَّيِّـَٔاتِۚ ذَٰلِكَ ذِكۡرَىٰ لِلذَّٰكِرِينَ
Kírun ní etí ọ̀sán méjèèjì[1] àti ní abala kan nínú òru[2]. Dájúdájú àwọn iṣẹ́ rere ń pa àwọn iṣẹ́ aburú rẹ́. Ìyẹn ni ìrántí fún àwọn olùrántí (Allāhu).
[1] Ìyẹn ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sán àti ìparí ọ̀sán. Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sán dúró fún lílà al-fajr fún ìrun Subh. Ìparí ọ̀sán dúró fún ìrun Ṭḥuhr àti ‘Asr. [2] Ìyẹn ni abala ìbẹ̀rẹ̀ òru. Èyí dúró fún ìrun Mọgrib àti ‘Iṣā’.
Esegesi in lingua araba:
وَٱصۡبِرۡ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Ṣe sùúrù. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.
Esegesi in lingua araba:
فَلَوۡلَا كَانَ مِنَ ٱلۡقُرُونِ مِن قَبۡلِكُمۡ أُوْلُواْ بَقِيَّةٖ يَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡفَسَادِ فِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا قَلِيلٗا مِّمَّنۡ أَنجَيۡنَا مِنۡهُمۡۗ وَٱتَّبَعَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مَآ أُتۡرِفُواْ فِيهِ وَكَانُواْ مُجۡرِمِينَ
Kí ó sì jẹ́ pé àwọn onílàákàyè kan wà nínú àwọn ìran tó ṣíwájú yín (nínú àwọn tí A parẹ́) kí wọ́n máa kọ ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ - àfi ènìyàn díẹ̀ lára àwọn tí A gbàlà nínú wọn. - Àwọn tó ṣàbòsí sì tẹ̀lé n̄ǹkan tí A fi ṣe gbẹdẹmukẹ fún wọn. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Esegesi in lingua araba:
وَمَا كَانَ رَبُّكَ لِيُهۡلِكَ ٱلۡقُرَىٰ بِظُلۡمٖ وَأَهۡلُهَا مُصۡلِحُونَ
Olúwa rẹ kì í pa àwọn ìlú run lọ́nà àbòsí, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ bá jẹ́ olùṣàtùn-únṣe.[1]
[1] Àwọn kan sọ pé, a tún lè túmọ̀ āyah yìí kan náà báyìí pé, “Allāhu kì í pa àwọn ìlú run fún wí pé wọ́n ń ṣẹbọ sí I, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ará ìlú náà bá ń ṣe déédé láààrin ara wọn.” (Tọbariy)
Esegesi in lingua araba:
 
Traduzione dei significati Sura: Hûd
Indice delle Sure Numero di pagina
 
Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail - Indice Traduzioni

Tradotta dallo Sheikh Abu Rahima Mikail Aikoyini.

Chiudi