Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó mú ẹrúsìn Rẹ̀ ṣe ìrìn-àjò ní alẹ́ láti Mọ́sálásí Haram sí Mọ́sálásí Aƙsọ̄ tí A fi ìbùkún yí ká, nítorí kí Á lè fi nínú àwọn àmì Wa hàn án. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.[1]
1. Ìrìn-àjò òru tí Allāhu - subhānahu wa ta ‘ālā - mú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - rìn yìí, kì í ṣe nípasẹ̀ àlá lílá, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí àti ara.
A sì fi mọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nínú Tírà pé: “Dájúdájú ẹ máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ nígbà mejì.[1] Dájúdájú ẹ tún máa ṣègbéraga tó tóbi.”
1. Ìbàjẹ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní ìsọ ti ìkìlọ̀, òhun ni pípa tí wọ́n máa fi ọwọ́ ara wọn pa Ànábì Zakariyyā - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti pípa tí wọ́n tún máa fi ọwọ́ ara wọn pa Ànábì Yahyā - kí ọlà Allāhu máa bá a -.
Lẹ́yìn náà, A dá ìṣẹ́gun lórí wọn padà fún yín. A sì fi àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ ṣèrànwọ́ fún yín. A sì ṣe yín ní ìjọ tó pọ̀ jùlọ.
Tí ẹ bá ṣe rere, ẹ ṣe rere fún ẹ̀mí ara yín. Tí ẹ bá sì ṣe aburú, fún ẹ̀mí ara yín ni. Nígbà tí àdéhùn ìkẹ́yìn bá dé, (A óò gbé ọmọ ogun mìíràn dìde) nítorí kí wọ́n lè kó ìbànújẹ́ bá yín àti nítorí kí wọ́n lè wọ inú Mọ́sálásí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wọ̀ ọ́ nígbà àkọ́kọ́ àti nítorí kí wọ́n lè pa ohun tí (àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl) jọba lórí rẹ̀ run pátápátá.
A ṣe alẹ́ àti ọ̀sán ní àmì méjì; A pa àmì alẹ́ rẹ́, A sì ṣe àmì ọ̀sán ní ìríran[1] nítorí kí ẹ lè wá oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò (àwọn ọjọ́). Gbogbo n̄ǹkan ni A ti ṣàlàyé rẹ̀ ní ìfọ́síwẹ́wẹ́.²
1. Àmì alẹ́ ni òṣùpá, àmì ọ̀sán ni òòrùn. 2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:114.
Ènìyàn kọ̀ọ̀kan, A ti so iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mọ́ ọn lọ́rùn. A sì máa mú ìwé kan jáde fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó máa pàdé rẹ̀ ní ṣíṣí sílẹ̀.
Nígbà tí A bá sì gbèrò láti pa ìlú kan run, A máa pa àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà láṣẹ (rere). Àmọ́ wọ́n máa ṣèbàjẹ́ sínú ìlú. Ọ̀rọ̀ náà yó sì kò lé wọn lórí. A ó sì pa wọ́n rẹ́ pátápátá.[1]
Wo bí A ṣe fún apá kan wọn lóore àjùlọ lórí apá kan (nílé ayé). Dájúdájú tọ̀run tún tóbi jùlọ ní ipò, ó sì tóbi jùlọ lóore àjùlọ.
Dájúdájú A ti ṣe àlàyé sínú al- Ƙur’ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìṣítí. Síbẹ̀síbẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe sísá (fún ìrántí).
Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń wí, wọn ìbá wá ọ̀nà láti súnmọ́ (Allāhu) Onítẹ̀ẹ́-ọlá ni.”[1]
1. Ìyẹn ni pé, àwọn òrìṣà gan-an ń wá oore sọ́dọ̀ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -.
A fi èbìbò bo ọkàn wọn nítorí kí wọ́n má baà gbọ́ ọ yé. (A tún fi) èdídí sínú etí wọn. Nígbà tí o bá sì dárúkọ Olúwa rẹ nìkan ṣoṣo nínú al-Ƙur’ān, wọ́n máa pẹ̀yìndà tí wọn yóò máa sá lọ.
Tàbí (kí ẹ di) ẹ̀dá kan nínú ohun tí ó tóbi nínú ọkàn yín.” Síbẹ̀síbẹ̀ wọn yóò wí pé: “Ta ni Ó máa dá wa padà (fún àjíǹde)?” Sọ pé: “Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá yín ní ìgbà àkọ́kọ́ ni.” Síbẹ̀síbẹ̀ wọn yóò mi orí wọn sí ọ (ní ti àbùkù). Nígbà náà, wọn yóò wí pé: “Ìgbà wo ni?” Sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé ó ti súnmọ́.”
Àti pé kò sí ohun tí ó dí Wa lọ́wọ́ láti fi àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) ránṣẹ́ bí kò ṣe pé àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti pè é nírọ́. A fún ìjọ Thamūd ní abo ràkúnmí; (àmì) tó fojú hàn kedere ni. Àmọ́ wọ́n ṣàbòsí sí i. A ò sì níí fi àwọn àmì ránṣẹ́ bí kò ṣe fún ìdẹ́rùbà.
(Rántí) nígbà tí A sọ fún ọ pé: “Dájúdájú Olúwa rẹ yí àwọn ènìyàn po (pẹ̀lú agbára Rẹ̀). Àti pé A kò ṣe ìran (wíwò) tí A fi hàn ọ́ àti igi (zaƙūm) tí A ṣẹ́bi lé nínú al-Ƙur’ān ní kiní kan bí kò ṣe pé (ó jẹ́) àdánwò fún àwọn ènìyàn. À ń dẹ́rù bà wọ́n, àmọ́ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìwà àgbéré tó tóbi.[1]
1. Híhù tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - mú igi zaƙūm hù jáde láti inú Iná jẹ́ ohun tí ó tako òye àwọn aláìgbàgbọ́. Wọ́n takò ó. Àtakò wọn sì di àdánwò fún wọn.
Fi ohùn rẹ kó ẹni tí agbára rẹ bá ká nínú wọn láyà jẹ. Fi àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sin rẹ àti ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ rẹ pè wọ́n (sínú ìṣìnà). Kópa pẹ̀lú wọn nínú àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ.[1] Kí o sì ṣe àdéhùn fún wọn.” Aṣ-ṣaetọ̄n kò sì níí ṣe àdéhùn kan fún wọn bí kò ṣe ẹ̀tàn. ²
1. Ìyẹn ni pé, aṣ-ṣaetọ̄n yóò bá wọn lọ́wọ́ sí fífi harām wá owó àti dúkìá. Bákan náà, aṣ-ṣaetọ̄n yóò bá wọn lọ́wọ́ sí bíbí ọmọ ní ìpasẹ̀ ìbàjẹ́ àti àgbèrè ṣíṣe. 2. Ohùn aṣ-ṣaetọ̄n ni orin àlùjó oníran-ànran, eré ṣíṣe àti ayò títa. Àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sin àti àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ tí aṣ-ṣaetọ̄n ń lò fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀ wọ̀nyí ni gbogbo olùpèpè sínú ìyapa àṣẹ Allāhu àti àṣẹ àwọn Ànábì Rẹ̀ (‘aleehim sọlātun wa salām).
Dájúdájú A ṣe àpọ́nlé fún àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam; A gbé wọn rìn lórí ilẹ̀ àti lórí omi; A fún wọn ní ìjẹ-ìmu nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa; A sì ṣoore àjùlọ fún wọn gan-an lórí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn tí A dá.
Ní ọjọ́ tí A óò máa pe gbogbo ènìyàn pẹ̀lú aṣíwájú wọn[1]. Nígbà náà, ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ìwé (iṣẹ́) rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò máa ka ìwé (iṣẹ́) wọn. A ò sì níí fi ìbójú kóró èso dàbínú ṣàbòsí sí wọn.
Wọ́n fẹ́ẹ̀ kó ìyọnu bá ọ nípa n̄ǹkan tí A mú wá fún ọ ní ìmísí nítorí kí o lè hun n̄ǹkan mìíràn nípa Wa. Nígbà náà, wọn ìbá mú ọ ní ọ̀rẹ́ àyò.
Àti pé nínú òru, fi kíké al-Ƙur’ān (lórí ìrun) ṣàì sùn. (Èyí jẹ́) iṣẹ́ àṣegbọrẹ fún ọ. Láìpẹ́, Olúwa rẹ yóò gbé ọ sí ipò kan tí àwọn ẹ̀dá máa ti yìn ọ́.[1]
1. Ìyẹn ni ibi tí Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - máa ti ṣìpẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lọ́dọ̀ Allāhu - ta‘ālā - ní Ọjọ́ Àjíǹde.
Tàbí kí o ní ilé wúrà kan, tàbí kí o gun òkè sánmọ̀ lọ. A kò sì níí gba gígun-sánmọ̀ rẹ gbọ́ títí o fi máa sọ tírà kan tí a óò máa ké kalẹ̀ fún wa.” Sọ pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa mi, ǹjẹ́ mo jẹ́ kiní kan bí kò ṣe Òjíṣẹ́ abara?”
Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn mọlāika wà lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n ń rìn kiri, (tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀) pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀, A ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀ (láti jẹ́) Òjíṣẹ́.”[1]
1. Ìyẹn ni pé, irọ́ ńlá ni láti ẹnu àwọn nasọ̄rọ̄ láti sọ pé Ọlọ́hun fúnra Rẹ̀ l’ó wá jíṣẹ́ ara Rẹ̀ ní àwòrán ‘Īsā ọmọ Mọryam láààrin àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl! Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń sọ nípa Rẹ̀ ní irọ́.
Ìyẹn ni ẹ̀san wọn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa. Wọ́n sì wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti di egungun, tí a sì ti jẹrà, ṣé wọ́n tún máa gbé wa dìde ní ẹ̀dá titun ni?”
Kí o sì sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu,[1] Ẹni tí kò fi ẹnì kan ṣe ọmọ. Kò sì ní akẹgbẹ́ nínú ìjọba. Kò sì ní ọ̀rẹ́ kan torí àìlágbára.”² Gbé títóbi fún Un gan-an.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Fātihah;1:2. 2. Ìyẹn ni pé, mímú tí Allāhu - tó ga jùlọ - bá mú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ní ọ̀rẹ́ kì í ṣe nítorí ìrànlọ́wọ́ wọn tàbí ìkúnlọ́wọ́ wọn, bí kò ṣe nítorí pé, Allāhu gan-an ní Olùrànlọ́wọ́ wọn, Alágbára àti Olùborí lórí wọn.
Contents of the translations can be downloaded and re-published, with the following terms and conditions:
1. No modification, addition, or deletion of the content.
2. Clearly referring to the publisher and the source (QuranEnc.com).
3. Mentioning the version number when re-publishing the translation.
4. Keeping the transcript information inside the document.
5. Notifying the source (QuranEnc.com) of any note on the translation.
6. Updating the translation according to the latest version issued from the source (QuranEnc.com).
7. Inappropriate advertisements must not be included when displaying translations of the meanings of the Noble Quran.
Risultati della ricerca:
API specs
Endpoints:
Sura translation
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/sura/{translation_key}/{sura_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified sura (by its number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114)
Returns:
json object containing array of objects, each object contains the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/aya/{translation_key}/{sura_number}/{aya_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified aya (by its number sura_number and aya_number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114) aya_number: [1-...] (Aya number in the sura)
Returns:
json object containing the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".