Check out the new design

Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail * - Indice Traduzioni

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduzione dei significati Sura: Al-Kahf   Versetto:
قَالَ هَٰذَا رَحۡمَةٞ مِّن رَّبِّيۖ فَإِذَا جَآءَ وَعۡدُ رَبِّي جَعَلَهُۥ دَكَّآءَۖ وَكَانَ وَعۡدُ رَبِّي حَقّٗا
Ó sọ pé: “Èyí ni ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi. Nígbà tí àdéhùn Olúwa mi bá dé, (Allāhu) yó sì sọ ọ́ di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Àdéhùn Olúwa mi sì jẹ́ òdodo.”
Esegesi in lingua araba:
۞ وَتَرَكۡنَا بَعۡضَهُمۡ يَوۡمَئِذٖ يَمُوجُ فِي بَعۡضٖۖ وَنُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَجَمَعۡنَٰهُمۡ جَمۡعٗا
A máa fi àwọn (ènìyàn àti àlùjànnú) sílẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, tí apá kan wọn yó sì máa rúpọ̀ mọ́ apá kan. Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. A ó sì kó gbogbo wọn jọ papọ̀ pátápátá.
Esegesi in lingua araba:
وَعَرَضۡنَا جَهَنَّمَ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡكَٰفِرِينَ عَرۡضًا
Ní ọjọ́ yẹn, A ó sì fi iná Jahanamọ han àwọn aláìgbàgbọ́ kedere.
Esegesi in lingua araba:
ٱلَّذِينَ كَانَتۡ أَعۡيُنُهُمۡ فِي غِطَآءٍ عَن ذِكۡرِي وَكَانُواْ لَا يَسۡتَطِيعُونَ سَمۡعًا
(Àwọn ni) àwọn tí ojú wọn wà nínú èbìbò nípa ìrántí Mi. Wọn kò sì lè gbọ́rọ̀.
Esegesi in lingua araba:
أَفَحَسِبَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَن يَتَّخِذُواْ عِبَادِي مِن دُونِيٓ أَوۡلِيَآءَۚ إِنَّآ أَعۡتَدۡنَا جَهَنَّمَ لِلۡكَٰفِرِينَ نُزُلٗا
Ṣé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lérò pé àwọn yóò mú àwọn ẹrúsìn Mi ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Mi ni? Dájúdájú Àwa pèsè iná Jahanamọ sílẹ̀ ní ibùdésí fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Esegesi in lingua araba:
قُلۡ هَلۡ نُنَبِّئُكُم بِٱلۡأَخۡسَرِينَ أَعۡمَٰلًا
Sọ pé: “Ṣé kí Á fún yín ní ìró àwọn ẹni òfò jùlọ nípa iṣẹ́ (ọwọ́ wọn)?
Esegesi in lingua araba:
ٱلَّذِينَ ضَلَّ سَعۡيُهُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَهُمۡ يَحۡسَبُونَ أَنَّهُمۡ يُحۡسِنُونَ صُنۡعًا
(Àwọn ni) àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ nínú ìṣẹ̀mí ayé, (àmọ́ tí) wọ́n ń lérò pé dájúdájú àwọn ń ṣe iṣẹ́ rere.
Esegesi in lingua araba:
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ وَلِقَآئِهِۦ فَحَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ فَلَا نُقِيمُ لَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَزۡنٗا
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa wọn àti ìpàdé Rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ wọn sì bàjẹ́. Nítorí náà, A ò níí jẹ́ kí wọ́n jámọ́ n̄ǹkan kan lórí ìwọ̀n ní Ọjọ́ Àjíǹde.
Esegesi in lingua araba:
ذَٰلِكَ جَزَآؤُهُمۡ جَهَنَّمُ بِمَا كَفَرُواْ وَٱتَّخَذُوٓاْ ءَايَٰتِي وَرُسُلِي هُزُوًا
Jahanamọ, ìyẹn ni ẹ̀san wọn nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́, wọ́n sì sọ àwọn āyah Mi àti àwọn Òjíṣẹ́ Mi di oníyẹ̀yẹ́.
Esegesi in lingua araba:
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ كَانَتۡ لَهُمۡ جَنَّٰتُ ٱلۡفِرۡدَوۡسِ نُزُلًا
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn ọgbà Firdaos ti wà fún wọn ní ibùdésí.
Esegesi in lingua araba:
خَٰلِدِينَ فِيهَا لَا يَبۡغُونَ عَنۡهَا حِوَلٗا
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Wọn kò sì níí fẹ́ kúrò nínú rẹ̀.
Esegesi in lingua araba:
قُل لَّوۡ كَانَ ٱلۡبَحۡرُ مِدَادٗا لِّكَلِمَٰتِ رَبِّي لَنَفِدَ ٱلۡبَحۡرُ قَبۡلَ أَن تَنفَدَ كَلِمَٰتُ رَبِّي وَلَوۡ جِئۡنَا بِمِثۡلِهِۦ مَدَدٗا
Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ibúdò jẹ́ tàdáà fún àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Mi, ibúdò kúkú máa tán ṣíwájú kí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Mi tó tán, kódà kí Á tún mú (ibúdò) irú rẹ̀ wá ní àlékún.”
Esegesi in lingua araba:
قُلۡ إِنَّمَآ أَنَا۠ بَشَرٞ مِّثۡلُكُمۡ يُوحَىٰٓ إِلَيَّ أَنَّمَآ إِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۖ فَمَن كَانَ يَرۡجُواْ لِقَآءَ رَبِّهِۦ فَلۡيَعۡمَلۡ عَمَلٗا صَٰلِحٗا وَلَا يُشۡرِكۡ بِعِبَادَةِ رَبِّهِۦٓ أَحَدَۢا
Sọ pé: “Abara ni èmi bí irú yín. Wọ́n ń fí ìmísí ránṣẹ́ sí mi pé Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Olúwa rẹ̀, kí ó ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì gbọdọ̀ fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ níbi jíjọ́sìn fún Olúwa rẹ̀ (kò gbọ́dọ̀ ṣẹbọ sí Olúwa rẹ̀).”
Esegesi in lingua araba:
 
Traduzione dei significati Sura: Al-Kahf
Indice delle Sure Numero di pagina
 
Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail - Indice Traduzioni

Tradotta dallo Sheikh Abu Rahima Mikail Aikoyini.

Chiudi