Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba * - Indice Traduzioni

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduzione dei significati Versetto: (97) Sura: Al-Baqarah
قُلۡ مَن كَانَ عَدُوّٗا لِّـجِبۡرِيلَ فَإِنَّهُۥ نَزَّلَهُۥ عَلَىٰ قَلۡبِكَ بِإِذۡنِ ٱللَّهِ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَهُدٗى وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُؤۡمِنِينَ
Sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá fún (mọlāika) Jibrīl,¹ (ó ti di ọ̀tá Allāhu) nítorí pé, dájúdájú (mọlāika) Jibrīl ló sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ sínú ọkàn rẹ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Al-Ƙur’ān sì ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wá ṣíwájú rẹ̀. Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
1. Nínú àwọn mọlāika tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - máa ń fi iṣẹ́ ìmísí rán sí àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni mọlaika Jibrīl - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Òun sì ni olórí àwọn mọlāika. Mọlaika Jibrīl tún ní àwọn orúkọ mìíràn nínú al-Ƙur’ān. Nínú àwọn orúkọ rẹ̀ ni “ar-Rūh” - Ẹ̀mí - (sūrah al-Mọ‘ārij; 70:4), “rūhul-ƙudus” - Ẹ̀mí Mímọ́ - (sūrah an-Nahl; 16:102) àti “rūhul-’Amīn” - Ẹ̀mí Ìfàyàbalẹ̀, Ẹ̀mí tí kì í jàǹbá iṣẹ́ tí Allāhu fi rán an. - (sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:193). Àmọ́ yàtọ̀ sí pé, mọlāika Jibrīl ń jẹ́ “ar-rūh”, nínú al-Ƙur’ān “rūh” tún lè túmọ̀ sí “ìmísí tàbí al-ƙur’ān (sūrah an-Nahl; 16:2); “rūh” lè túmọ̀ sí “ẹ̀mí” tí a fi ń jẹ́ abẹ̀mí (sūrah al-’Isrọ̄’; 17:85); àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Esegesi in lingua araba:
 
Traduzione dei significati Versetto: (97) Sura: Al-Baqarah
Indice delle Sure Numero di pagina
 
Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Indice Traduzioni

Traduzione dei significati del Nobile Corano in yoruba, di Shaikh Abu Rahima Mika'il 'Aikweiny, ed. 1432 H.

Chiudi