Check out the new design

Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail * - Indice Traduzioni

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduzione dei significati Sura: Az-Zumar   Versetto:
وَنُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَصَعِقَ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا مَن شَآءَ ٱللَّهُۖ ثُمَّ نُفِخَ فِيهِ أُخۡرَىٰ فَإِذَا هُمۡ قِيَامٞ يَنظُرُونَ
Wọ́n á fọn fèrè oníwo (fún ikú). Àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ sì máa kú àfi ẹni tí Allāhu bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa fọn ọ́n ní ẹ̀ẹ̀ kejì, nígbà náà wọ́n máa wà ní ìdìde. Wọn yó sì máa wò sùn.
Esegesi in lingua araba:
وَأَشۡرَقَتِ ٱلۡأَرۡضُ بِنُورِ رَبِّهَا وَوُضِعَ ٱلۡكِتَٰبُ وَجِاْيٓءَ بِٱلنَّبِيِّـۧنَ وَٱلشُّهَدَآءِ وَقُضِيَ بَيۡنَهُم بِٱلۡحَقِّ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ
Àti pé ilẹ̀ náà yóò máa tàn yànrànyànràn pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ Olúwa rẹ̀. Wọ́n máa gbé ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá lélẹ̀. Wọ́n sì máa mú àwọn Ànábì àti àwọn ẹlẹ́rìí wá. A máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin wọn. A kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Esegesi in lingua araba:
وَوُفِّيَتۡ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا عَمِلَتۡ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِمَا يَفۡعَلُونَ
Àti pé Wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Esegesi in lingua araba:
وَسِيقَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِلَىٰ جَهَنَّمَ زُمَرًاۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءُوهَا فُتِحَتۡ أَبۡوَٰبُهَا وَقَالَ لَهُمۡ خَزَنَتُهَآ أَلَمۡ يَأۡتِكُمۡ رُسُلٞ مِّنكُمۡ يَتۡلُونَ عَلَيۡكُمۡ ءَايَٰتِ رَبِّكُمۡ وَيُنذِرُونَكُمۡ لِقَآءَ يَوۡمِكُمۡ هَٰذَاۚ قَالُواْ بَلَىٰ وَلَٰكِنۡ حَقَّتۡ كَلِمَةُ ٱلۡعَذَابِ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ
Wọn yó sì da àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lọ sínú iná Jahanamọ níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: “Ǹjẹ́ àwọn Òjíṣẹ́ kan kò wá ba yín láti ààrin ara yín, tí wọ́n ń ké àwọn āyah Olúwa yín fún yín, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ ìpàdé ọjọ́ yín òní yìí fún yín?” Wọ́n wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni (wọ́n wá bá wa).” Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìyà kò lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí ni.
Esegesi in lingua araba:
قِيلَ ٱدۡخُلُوٓاْ أَبۡوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ فَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلۡمُتَكَبِّرِينَ
A óò sọ pé: “Ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀nà iná Jahanamọ. Olùṣegbére (ni yín) nínú rẹ̀. Ibùgbé àwọn onígbèéraga sì burú.
Esegesi in lingua araba:
وَسِيقَ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ رَبَّهُمۡ إِلَى ٱلۡجَنَّةِ زُمَرًاۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءُوهَا وَفُتِحَتۡ أَبۡوَٰبُهَا وَقَالَ لَهُمۡ خَزَنَتُهَا سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمۡ طِبۡتُمۡ فَٱدۡخُلُوهَا خَٰلِدِينَ
Àti pé A óò kó àwọn tó bẹ̀rù Olúwa wọn lọ sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: “Kí àlàáfíà máa bá yín. Ẹ̀yin dára (nítorí iṣẹ́ yín tó dára). Nítorí náà, ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, (kí ẹ di) olùṣegbére(nínú rẹ̀).”[1]
[1] Àmọ́ orí afárá Iná ni àwọn mùsùlùmí máa gbà kọjá bọ́ sí inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ní ìbámu sí sūrah Mọryam; 19:71.
Esegesi in lingua araba:
وَقَالُواْ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي صَدَقَنَا وَعۡدَهُۥ وَأَوۡرَثَنَا ٱلۡأَرۡضَ نَتَبَوَّأُ مِنَ ٱلۡجَنَّةِ حَيۡثُ نَشَآءُۖ فَنِعۡمَ أَجۡرُ ٱلۡعَٰمِلِينَ
Wọ́n á sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó mú àdéhùn Rẹ̀ ṣẹ fún wa. Ó tún jogún ilẹ̀ náà fún wa, tí à ń gbé níbikíbi tí a bá fẹ́ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Ẹ̀san àwọn olùṣe-rere mà sì dára.
Esegesi in lingua araba:
 
Traduzione dei significati Sura: Az-Zumar
Indice delle Sure Numero di pagina
 
Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail - Indice Traduzioni

Tradotta dallo Sheikh Abu Rahima Mikail Aikoyini.

Chiudi