Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba * - Indice Traduzioni

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduzione dei significati Sura: At-Taghâbun   Versetto:

Suuratut-Tagaabun

يُسَبِّحُ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۖ لَهُ ٱلۡمُلۡكُ وَلَهُ ٱلۡحَمۡدُۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ
Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu. TiRẹ̀ ni ìjọba. TiRẹ̀ sì ni ẹyìn. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Esegesi in lingua araba:
هُوَ ٱلَّذِي خَلَقَكُمۡ فَمِنكُمۡ كَافِرٞ وَمِنكُم مُّؤۡمِنٞۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٌ
Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín. Aláìgbàgbọ́ wà nínú yín. Onígbàgbọ́ òdodo sì wà nínú yín. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Esegesi in lingua araba:
خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّ وَصَوَّرَكُمۡ فَأَحۡسَنَ صُوَرَكُمۡۖ وَإِلَيۡهِ ٱلۡمَصِيرُ
Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ya àwòrán yín. Ó sì ṣe àwọn àwòrán yín dáradára. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
Esegesi in lingua araba:
يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَيَعۡلَمُ مَا تُسِرُّونَ وَمَا تُعۡلِنُونَۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ
Ó mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
Esegesi in lingua araba:
أَلَمۡ يَأۡتِكُمۡ نَبَؤُاْ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن قَبۡلُ فَذَاقُواْ وَبَالَ أَمۡرِهِمۡ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Ṣé ìró àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ìṣáájú kò tí ì dé ba yín ni? Nítorí náà, wọ́n tọ́ ìyà ọ̀ràn wọn wò. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
Esegesi in lingua araba:
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُۥ كَانَت تَّأۡتِيهِمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَقَالُوٓاْ أَبَشَرٞ يَهۡدُونَنَا فَكَفَرُواْ وَتَوَلَّواْۖ وَّٱسۡتَغۡنَى ٱللَّهُۚ وَٱللَّهُ غَنِيٌّ حَمِيدٞ
Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ wọn ń wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. Wọ́n sì wí pé: “Ṣé abara l’ó máa fi ọ̀nà mọ̀ wá?” Nítorí náà, wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Wọ́n sì pẹ̀yìndà (sí òdodo). Allāhu sì rọrọ̀ láì sí àwọn. Àti pé Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.
Esegesi in lingua araba:
زَعَمَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَن لَّن يُبۡعَثُواْۚ قُلۡ بَلَىٰ وَرَبِّي لَتُبۡعَثُنَّ ثُمَّ لَتُنَبَّؤُنَّ بِمَا عَمِلۡتُمۡۚ وَذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٞ
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lérò pé A ò níí gbé wọn dìde. Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, mo fi Olúwa mi búra, dájúdájú Wọn yóò gbe yín dìde. Lẹ́yìn náà, Wọn yóò fún yín ní ìró ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.”
Esegesi in lingua araba:
فَـَٔامِنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَٱلنُّورِ ٱلَّذِيٓ أَنزَلۡنَاۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ
Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ tí A sọ̀kalẹ̀. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Esegesi in lingua araba:
يَوۡمَ يَجۡمَعُكُمۡ لِيَوۡمِ ٱلۡجَمۡعِۖ ذَٰلِكَ يَوۡمُ ٱلتَّغَابُنِۗ وَمَن يُؤۡمِنۢ بِٱللَّهِ وَيَعۡمَلۡ صَٰلِحٗا يُكَفِّرۡ عَنۡهُ سَيِّـَٔاتِهِۦ وَيُدۡخِلۡهُ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ
Ní ọjọ́ tí (Allāhu) yóò ko yín jọ fún ọjọ́ àkójọ. Ìyẹn ni ọjọ́ èrè àti àdánù.¹ Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Allāhu gbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, (Allāhu) yóò pa àwọn àṣìṣe rẹ̀ rẹ́ fún un. Ó sì máa mú un wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
1. Lára orúkọ ọjọ́ àjíǹde ni Ọjọ́ Èrè àti Àdánù. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo yó jèrè Ọgbà Ìdẹ̀ra, àwọn aláìgbàgbọ́ sì máa pàdánù rẹ̀.
Esegesi in lingua araba:
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَآ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ
Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìkángun náà sì burú.
Esegesi in lingua araba:
مَآ أَصَابَ مِن مُّصِيبَةٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۗ وَمَن يُؤۡمِنۢ بِٱللَّهِ يَهۡدِ قَلۡبَهُۥۚ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ
Àdánwò kan kò lè ṣẹlẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu ní òdodo, Allāhu máa fi ọkàn rẹ̀ mọ̀nà.¹ Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
1. Ìmọ̀nà ọkàn lórí àdánwò ni gbígba kádàrá, ṣíṣe sùúrù àti níní ìrètí sí ẹ̀san rere.
Esegesi in lingua araba:
وَأَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُواْ ٱلرَّسُولَۚ فَإِن تَوَلَّيۡتُمۡ فَإِنَّمَا عَلَىٰ رَسُولِنَا ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ
Kí ẹ tẹ̀lé ti Allāhu. Kí ẹ sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́. Tí ẹ bá gbúnrí, ìkede ẹ̀sìn tó yanjú ni ojúṣe Òjíṣẹ́ Wa.
Esegesi in lingua araba:
ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۚ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
Esegesi in lingua araba:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِنَّ مِنۡ أَزۡوَٰجِكُمۡ وَأَوۡلَٰدِكُمۡ عَدُوّٗا لَّكُمۡ فَٱحۡذَرُوهُمۡۚ وَإِن تَعۡفُواْ وَتَصۡفَحُواْ وَتَغۡفِرُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٌ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ọ̀tá wà fún yín nínú àwọn ìyàwó yín àti àwọn ọmọ yín. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra fún wọn. Tí ẹ bá ṣàmójúkúrò, tí ẹ ṣàfojúfò, tí ẹ sì ṣàforíjìn (fún wọn), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Esegesi in lingua araba:
إِنَّمَآ أَمۡوَٰلُكُمۡ وَأَوۡلَٰدُكُمۡ فِتۡنَةٞۚ وَٱللَّهُ عِندَهُۥٓ أَجۡرٌ عَظِيمٞ
Ìfòòró ni àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín. Allāhu sì ni ẹ̀san ńlá wà ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Esegesi in lingua araba:
فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ مَا ٱسۡتَطَعۡتُمۡ وَٱسۡمَعُواْ وَأَطِيعُواْ وَأَنفِقُواْ خَيۡرٗا لِّأَنفُسِكُمۡۗ وَمَن يُوقَ شُحَّ نَفۡسِهِۦ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ẹ bá ṣe lágbára mọ. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ (Allāhu), ẹ tẹ̀lé e, kí ẹ sì náwó (fún ẹ̀sìn Rẹ̀) lóore jùlọ fún ẹ̀mí yín. Ẹnikẹ́ni tí A bá ṣọ́ níbi ahun àti ọ̀kánjúà inú ẹ̀mí rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè.
Esegesi in lingua araba:
إِن تُقۡرِضُواْ ٱللَّهَ قَرۡضًا حَسَنٗا يُضَٰعِفۡهُ لَكُمۡ وَيَغۡفِرۡ لَكُمۡۚ وَٱللَّهُ شَكُورٌ حَلِيمٌ
Tí ẹ bá yá Allāhu ní dúkìá tó dára, Ó máa ṣàdìpèlé rẹ̀ fún yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Ọlọ́pẹ́¹, Aláfaradà,
1. Nínú orúkọ àti ìròyìn Allāhu ni “Ṣākir” àti “Ṣakūr”. Ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ méjèèjì ni “ṣukr” (ọpẹ́ / mímọ rírì oore àti sísọ ọ́). Pípe Allāhu ní “Ṣākir” àti “Ṣakūr” sì ń túmọ̀ sí Ẹni tí Ó mọ rírì iṣẹ́ rere tí ẹ̀dá ṣe, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ó fi ń sọ ẹ̀san iṣẹ́ rere náà di àdìpèlé fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Nítorí náà, tí a bá sọ pé, “Allāhu á dúpẹ́ fún ọ.”, ó ń túmọ̀ sí pé, “Allāhu kò níí fi láádá iṣẹ́ rere rẹ dùn ọ́, Allāhu á sì san ọ́ ní ẹ̀san rere àdìpèlé lórí rẹ̀.” Ìtúmọ̀ “Ṣākir” àti “Ṣakūr” sì wà nínú sūrah Fātir; 35:30
Esegesi in lingua araba:
عَٰلِمُ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Esegesi in lingua araba:
 
Traduzione dei significati Sura: At-Taghâbun
Indice delle Sure Numero di pagina
 
Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Indice Traduzioni

Traduzione dei significati del Nobile Corano in yoruba, di Shaikh Abu Rahima Mika'il 'Aikweiny, ed. 1432 H.

Chiudi