Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba * - Indice Traduzioni

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduzione dei significati Sura: Al-Muzzammil   Versetto:

Suuratul-Muzzammil

يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمُزَّمِّلُ
Ìwọ olùdaṣọbora.
Esegesi in lingua araba:
قُمِ ٱلَّيۡلَ إِلَّا قَلِيلٗا
Dìde (kírun) ní òru àyàfi fún ìgbà díẹ̀ (ni kí o fi sùn nínú òru rẹ).
Esegesi in lingua araba:
نِّصۡفَهُۥٓ أَوِ ٱنقُصۡ مِنۡهُ قَلِيلًا
Lo ìlàjì rẹ̀ tàbí dín díẹ̀ kù nínú rẹ̀.
Esegesi in lingua araba:
أَوۡ زِدۡ عَلَيۡهِ وَرَتِّلِ ٱلۡقُرۡءَانَ تَرۡتِيلًا
Tàbí fi kún un. Kí o sì ké al-Ƙur’ān pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.¹
1. Ní ìbámu sí āyah yìí, kí ẹnì kan ké odidi al-Ƙur’ān parí láààrin àsìkò díẹ̀ nípasẹ̀ ìkánjú kò lè mú kí onítọ̀ún gbádùn adùn al-Ƙur’ān. Kò sì lè mú ẹ̀san rẹ̀ kún kẹ́kẹ́. Lára oore tí ó rọ̀ mọ́ kíké al-Ƙur’ān pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ni pé, ó máa fún wa ní àǹfààní láti rí àwọn lẹ́tà (ìró) rẹ̀ pè dáradára. Ó máa ṣe àlékún àgbọ́yé àti àfọkànsí fún wa. Ìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu sì fẹ̀ẹ̀kan ni kíké al-Ƙur’ān pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.
Esegesi in lingua araba:
إِنَّا سَنُلۡقِي عَلَيۡكَ قَوۡلٗا ثَقِيلًا
Dájúdájú Àwa máa gbé ọ̀rọ̀ tó lágbára fún ọ.
Esegesi in lingua araba:
إِنَّ نَاشِئَةَ ٱلَّيۡلِ هِيَ أَشَدُّ وَطۡـٔٗا وَأَقۡوَمُ قِيلًا
Dájúdájú ìdìde kírun lóru, ó wọnú ọkàn jùlọ, ó sì dára jùlọ fún kíké (al-Ƙur’ān).
Esegesi in lingua araba:
إِنَّ لَكَ فِي ٱلنَّهَارِ سَبۡحٗا طَوِيلٗا
Dájúdájú iṣẹ́ púpọ̀ wà fún ọ ní ọ̀sán.
Esegesi in lingua araba:
وَٱذۡكُرِ ٱسۡمَ رَبِّكَ وَتَبَتَّلۡ إِلَيۡهِ تَبۡتِيلٗا
Rántí orúkọ Olúwa rẹ. Kí o sì da ọkàn kọ Ọ́ pátápátá.
Esegesi in lingua araba:
رَّبُّ ٱلۡمَشۡرِقِ وَٱلۡمَغۡرِبِ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ فَٱتَّخِذۡهُ وَكِيلٗا
Olúwa ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn, kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àfi Òun. Nítorí náà, mú Un ní Aláfẹ̀yìntì.
Esegesi in lingua araba:
وَٱصۡبِرۡ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَٱهۡجُرۡهُمۡ هَجۡرٗا جَمِيلٗا
Kí o sì ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí. Pa wọ́n tì ní ìpatì tó rẹwà.
Esegesi in lingua araba:
وَذَرۡنِي وَٱلۡمُكَذِّبِينَ أُوْلِي ٱلنَّعۡمَةِ وَمَهِّلۡهُمۡ قَلِيلًا
Fi Mí dá àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn ọlọ́rọ̀. Kí o sì lọ́ra fún wọn fún ìgbà díẹ̀.
Esegesi in lingua araba:
إِنَّ لَدَيۡنَآ أَنكَالٗا وَجَحِيمٗا
Dájúdájú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ àti Iná Jẹhīm ń bẹ lọ́dọ̀ Wa.
Esegesi in lingua araba:
وَطَعَامٗا ذَا غُصَّةٖ وَعَذَابًا أَلِيمٗا
Oúnjẹ háfunháfun àti ìyà ẹlẹ́ta-eléro (tún wà fún wọn).
Esegesi in lingua araba:
يَوۡمَ تَرۡجُفُ ٱلۡأَرۡضُ وَٱلۡجِبَالُ وَكَانَتِ ٱلۡجِبَالُ كَثِيبٗا مَّهِيلًا
Ní ọjọ́ tí ilẹ̀ àti àwọn àpáta yóò máa mì tìtì. Àwọn àpáta sì máa di yanrìn tí wọ́n kójọ tí wọ́n túká.
Esegesi in lingua araba:
إِنَّآ أَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡكُمۡ رَسُولٗا شَٰهِدًا عَلَيۡكُمۡ كَمَآ أَرۡسَلۡنَآ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ رَسُولٗا
Dájúdájú Àwa rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ si yín (tí ó jẹ́) olùjẹ́rìí lórí yín gẹ́gẹ́ bí A ṣe rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ sí Fir‘aon.
Esegesi in lingua araba:
فَعَصَىٰ فِرۡعَوۡنُ ٱلرَّسُولَ فَأَخَذۡنَٰهُ أَخۡذٗا وَبِيلٗا
Ṣùgbọ́n Fir‘aon yapa Òjíṣẹ́ náà. A sì gbá a mú ní ìgbámú líle.
Esegesi in lingua araba:
فَكَيۡفَ تَتَّقُونَ إِن كَفَرۡتُمۡ يَوۡمٗا يَجۡعَلُ ٱلۡوِلۡدَٰنَ شِيبًا
Tí ẹ̀yin bá ṣàì gbàgbọ́, báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe bẹ̀rù ọjọ́ kan tó máa mú àwọn ọmọdé hewú?
Esegesi in lingua araba:
ٱلسَّمَآءُ مُنفَطِرُۢ بِهِۦۚ كَانَ وَعۡدُهُۥ مَفۡعُولًا
Sánmọ̀ sì máa fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú rẹ̀. Àdéhùn Rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó máa ṣẹ.
Esegesi in lingua araba:
إِنَّ هَٰذِهِۦ تَذۡكِرَةٞۖ فَمَن شَآءَ ٱتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ سَبِيلًا
Dájúdájú èyí ni ìrántí. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ojú ọ̀nà kan tọ̀ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.
Esegesi in lingua araba:
۞ إِنَّ رَبَّكَ يَعۡلَمُ أَنَّكَ تَقُومُ أَدۡنَىٰ مِن ثُلُثَيِ ٱلَّيۡلِ وَنِصۡفَهُۥ وَثُلُثَهُۥ وَطَآئِفَةٞ مِّنَ ٱلَّذِينَ مَعَكَۚ وَٱللَّهُ يُقَدِّرُ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَۚ عَلِمَ أَن لَّن تُحۡصُوهُ فَتَابَ عَلَيۡكُمۡۖ فَٱقۡرَءُواْ مَا تَيَسَّرَ مِنَ ٱلۡقُرۡءَانِۚ عَلِمَ أَن سَيَكُونُ مِنكُم مَّرۡضَىٰ وَءَاخَرُونَ يَضۡرِبُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ يَبۡتَغُونَ مِن فَضۡلِ ٱللَّهِ وَءَاخَرُونَ يُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۖ فَٱقۡرَءُواْ مَا تَيَسَّرَ مِنۡهُۚ وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَقۡرِضُواْ ٱللَّهَ قَرۡضًا حَسَنٗاۚ وَمَا تُقَدِّمُواْ لِأَنفُسِكُم مِّنۡ خَيۡرٖ تَجِدُوهُ عِندَ ٱللَّهِ هُوَ خَيۡرٗا وَأَعۡظَمَ أَجۡرٗاۚ وَٱسۡتَغۡفِرُواْ ٱللَّهَۖ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمُۢ
Dájúdájú Olúwa rẹ mọ̀ pé dájúdájú ìwọ ń dìde kírun fún ohun tó kéré sí ìlàta méjì òru tàbí ìlàjì rẹ̀ tàbí ìlàta rẹ̀. Igun kan nínú àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ (náà ń ṣe bẹ́ẹ̀). Allāhu l’Ó ń ṣòdíwọ̀n òru àti ọ̀sán. Ó sì mọ̀ pé ẹ kò lè ṣọ́ ọ.1 Nítorí náà, Ó ti dá a padà sí fífúyẹ́ fún yín. Nítorí náà, ẹ ké ohun tí ó bá rọrùn (fún yín) nínú al-Ƙur’ān. Ó mọ̀ pé àwọn aláìsàn yóò wà nínú yín. Àwọn mìíràn sì ń rìrìn àjò lórí-ilẹ̀, tí wọ́n ń wá nínú oore Allāhu. Àwọn mìíràn sì ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Nítorí náà, ẹ ké ohun tí ó bá rọrùn (fún yín) nínú rẹ̀. Ẹ kírun (ọ̀ran-an-yàn). Ẹ yọ Zakāh. Kí ẹ sì yá Allāhu ní dúkìá tó dára. Ohunkóhun tí ẹ bá tì síwájú fún ẹ̀mí ara yín nínú ohun rere, ẹ̀yin yóò bá a lọ́dọ̀ Allāhu ní ohun rere àti ní ohun tí ó tóbi jùlọ ní ẹ̀san. Ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
1. Ìṣọ́-òru jẹ́ iṣẹ́ tí ẹ̀dá kò lágbára láti ṣe. Ìṣọ́-òru ni kí ẹ̀dá lérò pé òun kò níí fojú kan oorun láti alẹ́ mọ́júmọ́ lójojúmọ́.
Esegesi in lingua araba:
 
Traduzione dei significati Sura: Al-Muzzammil
Indice delle Sure Numero di pagina
 
Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Indice Traduzioni

Traduzione dei significati del Nobile Corano in yoruba, di Shaikh Abu Rahima Mika'il 'Aikweiny, ed. 1432 H.

Chiudi