ការបកប្រែអត្ថន័យនៃគម្ពីរគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

external-link copy
4 : 13

وَفِي ٱلۡأَرۡضِ قِطَعٞ مُّتَجَٰوِرَٰتٞ وَجَنَّٰتٞ مِّنۡ أَعۡنَٰبٖ وَزَرۡعٞ وَنَخِيلٞ صِنۡوَانٞ وَغَيۡرُ صِنۡوَانٖ يُسۡقَىٰ بِمَآءٖ وَٰحِدٖ وَنُفَضِّلُ بَعۡضَهَا عَلَىٰ بَعۡضٖ فِي ٱلۡأُكُلِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ

Ó tún wà nínú ilẹ̀ àwọn abala-abala ilẹ̀ (oníran-ànran) tó wà nítòsí ara wọn[1] àti àwọn ọgbà oko àjàrà, irúgbìn àti igi dàbínù tó pẹka àti èyí tí kò pẹka, tí wọ́n ń fún wọn ní omi ẹyọ kan mu. (Síbẹ̀síbẹ̀) A ṣe àjùlọ fún apá kan rẹ̀ lórí apá kan níbi àwọn èso wọn. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè. info

[1] Bíi ilẹ̀ yanrìn nítòsí ilẹ̀ amọ̀, ilẹ́ yangí nítòsí ilẹ̀ tí kì í ṣe ilẹ̀ yangí, ilẹ̀ tó lọ́ràá nítòsí ilẹ̀ tó sá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

التفاسير: |