[1] Kíyè sí i, Kaabah ni ƙiblah (àdojúkọ) àwa mùsùlùmí lórí ìrun wa, àmọ́ níwọ̀n ìgbà tí a ò bá sí nínú haram Mọkkah, agbègbè yòówù kí àdojúkọ wá bọ́ sí láààrin orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, kì í ṣe ìyẹn ni àdojúkọ wa bí kò ṣe pé ó jẹ́ ọ̀nà tààrà sí Kaabah láti ìlú wa. Àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ ni Allāhu ń júwe àwọn iṣẹ́ rere fún dípò bí wọ́n ṣe sọ ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn nìkan di ògóńgórí iṣẹ́ rere nínú ìlànà ìjọ́sìn wọn.
[1] Àwọn àmì ikú ni kí ẹ̀dá lérò pé ó ṣeé ṣe kí àìsàn kan tàbí ìrìn-àjò kan yọrí sí ikú fún òun. [2] Ìyẹn ni pé, kí onídúkìá fúnra rẹ̀ pín ogún rẹ̀ fún àwọn ẹbí rẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn , àwọn āyah mìíràn sọ̀kalẹ̀ tí ó pa ìdájọ́ yìí rẹ́. Àwọn āyah náà ni āyah tí Allāhu fúnra Rẹ̀ fi pín ogún òkú sūrah an-Nisā’; 7-14.