[1] Láti ọ̀dọ̀ ’Anas bun Mọ̄lik, ó sọ pé. Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé: “Tí ọ̀kan nínú yín bá sùn tayọ (àsìkò) ìrun tàbí ó gbàgbé (ìrun) rẹ̀, kí ó kí i nígbà tí ó bá rántí rẹ̀, nítorí pé Allāhu sọ pé: “Kírun fún ìrántí Mi.”