[1] “Ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu”, ìyẹn ni pé, ẹni tí Allāhu fi "kunfayakun" ṣẹ̀dá rẹ̀. [2] tàbí ẹni tí kò ju ẹ̀mí ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ìfẹ́-inú àti yòdòyìndìn ayé.
[1] “Àsìkò tirẹ̀” torí pé, àwọn obìnrin mìíran rí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kọdījah ọmọ Kuwaelid.
[1] Olúkùlùkù wọn kọ orúkọ rẹ̀ sára gègé rẹ̀. Wọ́n dá gègé wọn jọ, wọ́n dà wọ́n sínú odò. Odò gbé gbogbo gègé wọn lọ àfi gègé ti Zakariyā’ - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Wọ́n sì gbé Mọryam fún Ànábì Zakariyā’ - kí ọlà Allāhu máa bá a - gẹ́gẹ́ bí alágbàwò rẹ̀.
[1]. Àwọn kan lérò pé sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:45 tako sūrah Mọryam; 19:17 nípa pé “mọlā’ikah” jẹ́ “ọ̀pọ̀” nínú āyah àkọ́kọ́, ó sì jẹ́ ẹyọ “mọlak” nínú āyah kejì. Èsì: Èyí jẹ́ “ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀”, kì í ṣe “ìtakora tóríbẹ́ẹ̀”. Àlàyé rẹ̀ nìyí, nínú āyah ti āli ‘Imrọ̄n, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ń sọ nípa bí àwọn mọlā’ikah ṣe wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bíbi ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Àwọn mọlāika tó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà ju ẹyọ kan lọ. Ìdí nìyí tí “mọlā’ikah” fi jẹ́ ọ̀pọ̀ nínú āyah yẹn. Àmọ́ nínú āyah ti Mọryam, ẹyọ mọlāika kan péré ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fi “ẹ̀mí” ‘Īsā rán níṣẹ́ sí Mọryam. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ “mọlak” ẹyọ fún mọlā’ikah. Pẹ̀lú àlàyé yìí, ọ̀tọ̀ ni àsìkò àsọtẹ́lẹ̀ fún Mọryam nípa bíbí ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ọ̀tọ̀ sì ni àsìkò tí àsọtẹ́lẹ̀ náà wá sí ìmúṣẹ. Bákan náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Nisā’; 4:171 lórí àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ yìí “ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀”.
[2] Àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé, Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - nìkan ni “Ẹni iyì” ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Ẹ wo sūrah al-’Ahzāb; 33:69."