Kilniojo Korano reikšmių vertimas - Jorubų k. vertimas * - Vertimų turinys

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Reikšmių vertimas Aja (Korano eilutė): (10) Sūra: Sūra Aš-Šūra
وَمَا ٱخۡتَلَفۡتُمۡ فِيهِ مِن شَيۡءٖ فَحُكۡمُهُۥٓ إِلَى ٱللَّهِۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبِّي عَلَيۡهِ تَوَكَّلۡتُ وَإِلَيۡهِ أُنِيبُ
Ohunkóhun tí ẹ bá yapa-ẹnu lórí rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ di ọ̀dọ̀ Allāhu. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa mi. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí padà sí (ní ti ìronúpìwàdà). ¹
1. Àgbọ́yé méjì ni gbogbo tafsīr mú wá lórí gbólóhùn yìí “Ohunkóhun tí ẹ bá yapa-ẹnu lórí rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ di ọ̀dọ̀ Allāhu.” Ìkíní ni pé, lẹ́yìn tí Allāhu ti mú ìdájọ́ wá pé ’Islām nìkan ṣoṣo ni ẹ̀sìn àṣelà, àmọ́ tí àwọn aláìgbàgbọ́ yapa rẹ̀, kí àwa mùsùlùmí fi wọ́n sílẹ̀ títí di Ọjọ́ àjíǹde tí Allāhu máa fi ìdájọ́ Rẹ̀ mú ìlèrí ìyà Rẹ̀ ṣẹ lórí wọn. Pẹ̀lú àgbọ́yé yìí, āyah yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn āyah tó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú àwọn āyah tó ń pàṣẹ ìgbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ tó ń gbógun ti àwa mùsùlùmí àti āyah tó ń pàṣẹ gbígba owó-orí lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ tí kò gbógun ti àwa mùsùlùmí.
Ní àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ mìíràn, āyah yìí ń pàrọwà sùúrù àti ìfaradà fún èyíkéyìí àwùjọ mùsùlùmí tó wà nípò ọ̀lẹ ní orílẹ̀ èdè tí àwọn kèfèrí bá ti ń lo òfin kèfèrí lé wa lórí. Sùúrù náà máa wà bẹ́ẹ̀ títí di ọjọ́ tí ọwọ́ àwa mùsùlùmí yóò ba èkù-idà, tí agbára sì máa jẹ́ ti ’Islām.
Àgbọ́yé kejì ni pé, kí á ṣẹ́rí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ìyapa-ẹnu bá wáyé lórí wọn sínú al-Ƙur’ān, ọ̀rọ̀ Allāhu àti ìdájọ́ Rẹ̀. Pẹ̀lú àgbọ́yé yìí, āyah yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn āyah tó ń pa wá láṣẹ láti fi al-Ƙur’an àti sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - yanjú àwọn ọ̀rọ̀ ìyapa-ẹnu, gẹ́gẹ́ bí sūrah an-Nisā’; 4:59.
Àṣìgbọ́ l’ó jẹ́ nígbà náà láti lérò pé āyah náà ń pa wá láṣẹ láti má ṣe mú ìdájọ́ wá lórí àwọn ọ̀rọ̀ ìyapa-ẹnu tí al-Ƙur’ān ti yanjú. Èyí sì máa mú ìtúmọ̀ wíwo ìbàjẹ́ níran lọ́wọ́. Nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ ìbàjẹ́ oníran-ànran àti àdádáálẹ̀ ẹ̀sìn nínú ’Islam sì máa gbòde kanrí láààrin àwọn ẹ̀dá. Àṣẹ wíwo ìbàjẹ́ níran títí dọjọ́ àjíǹde kò sì ti ọ̀dọ̀ Allāhu wá nínú tírà sánmọ̀ kan kan.
Tafsyrai arabų kalba:
 
Reikšmių vertimas Aja (Korano eilutė): (10) Sūra: Sūra Aš-Šūra
Sūrų turinys Puslapio numeris
 
Kilniojo Korano reikšmių vertimas - Jorubų k. vertimas - Vertimų turinys

Kilniojo Korano reikšmių vertimas į jorubų kalbą. Išvertė šeichas Abu Rachima Mikael Aikojini. Leidimas 1432 m. po H.

Uždaryti