Check out the new design

Kilniojo Korano reikšmių vertimas - Vertimas į jorubų k. - Abu Rahima Mikail * - Vertimų turinys

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Reikšmių vertimas Sūra: Al-Ma’idah’   Aja (Korano eilutė):

Al-Maidah

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَوۡفُواْ بِٱلۡعُقُودِۚ أُحِلَّتۡ لَكُم بَهِيمَةُ ٱلۡأَنۡعَٰمِ إِلَّا مَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ غَيۡرَ مُحِلِّي ٱلصَّيۡدِ وَأَنتُمۡ حُرُمٌۗ إِنَّ ٱللَّهَ يَحۡكُمُ مَا يُرِيدُ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ mú àwọn àdéhùn ṣẹ. Wọ́n ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn[1] ní ẹ̀tọ́ fún yín àfi èyí tí wọ́n bá ń kà fún yín (ní èèwọ̀), ẹ má ṣe sọ ìdọdẹ ẹranko di ẹ̀tọ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ húrùmí. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ìdájọ́ ohun tí Ó bá fẹ́.
[1] Àwọn ẹran-ọ̀sìn náà ni ràkúnmí, màálù, àgùtàn àti ewúrẹ́.
Tafsyrai arabų kalba:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تُحِلُّواْ شَعَٰٓئِرَ ٱللَّهِ وَلَا ٱلشَّهۡرَ ٱلۡحَرَامَ وَلَا ٱلۡهَدۡيَ وَلَا ٱلۡقَلَٰٓئِدَ وَلَآ ءَآمِّينَ ٱلۡبَيۡتَ ٱلۡحَرَامَ يَبۡتَغُونَ فَضۡلٗا مِّن رَّبِّهِمۡ وَرِضۡوَٰنٗاۚ وَإِذَا حَلَلۡتُمۡ فَٱصۡطَادُواْۚ وَلَا يَجۡرِمَنَّكُمۡ شَنَـَٔانُ قَوۡمٍ أَن صَدُّوكُمۡ عَنِ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ أَن تَعۡتَدُواْۘ وَتَعَاوَنُواْ عَلَى ٱلۡبِرِّ وَٱلتَّقۡوَىٰۖ وَلَا تَعَاوَنُواْ عَلَى ٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡعُدۡوَٰنِۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۖ إِنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe rú òfin àwọn n̄ǹkan àríṣàmì tí Allāhu gbékalẹ̀ fún ẹ̀sìn Rẹ̀ (nínú iṣẹ́ hajj). Ẹ má ṣe rú òfin oṣù ọ̀wọ̀, àti ẹran ọrẹ (tí wọn kò ṣàmì sí lọ́rùn) àti (àwọn ẹran ọrẹ) tí wọ́n ṣàmì sí lọ́rùn. Ẹ má ṣe ìdíwọ́ fún àwọn tó ń gbèrò láti lọ sí Ilé Haram, tí wọ́n ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Tí ẹ bá sì ti túra sílẹ̀ nínú aṣọ hurumi, nígbà náà ẹ (lè) dọdẹ (ẹranko). Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti tayọ ẹnu-ààlà nítorí pé, wọ́n ṣe yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram. Ẹ ran ara yín lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ má ṣe ran ara yín lọ́wọ́ lórí (ìwà) ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtayọ ẹnu-ààlà. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.
Tafsyrai arabų kalba:
 
Reikšmių vertimas Sūra: Al-Ma’idah’
Sūrų turinys Puslapio numeris
 
Kilniojo Korano reikšmių vertimas - Vertimas į jorubų k. - Abu Rahima Mikail - Vertimų turinys

Išvertė šeichas Abu Rahima Mikail Aikuveini.

Uždaryti