വിശുദ്ധ ഖുർആൻ പരിഭാഷ - യോറുബൻ വിവർത്തനം * - വിവർത്തനങ്ങളുടെ സൂചിക

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

പരിഭാഷ ആയത്ത്: (34) അദ്ധ്യായം: സൂറത്തുൽ ബഖറഃ
وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ أَبَىٰ وَٱسۡتَكۡبَرَ وَكَانَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ
(Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.”¹ Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àyàfi ’Iblīs.² Ó kọ̀, ó sì ṣe ìgbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́.
1. Ìforíkanlẹ̀-kíni èyí tí Allāhu - subhānahu wa ta‘āla - pa láṣẹ fún àwọn mọlāika Rẹ̀, ó ti di èèwọ̀ fún ìjọ Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Èyí ni pé, kò bá òfin ’Islām mu fún ẹnikẹ́ni láti forí kanlẹ̀ kí ẹlòmíìràn, ẹni yòówù ìbáà jẹ́. Ìdí ni pé, nínú hadīth Abū Huraerah, láti ọ̀dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ó sọ pé: “Èmi ìbá jẹ́ apàṣẹ fún ẹnì kan pé kí ó forí kanlẹ̀ kí ẹlòmíìràn ni, èmi ìbá pa ìyàwó ní àṣẹ pé kí ó forí kanlẹ̀ kí ọkọ rẹ̀.” (Sunan at-Tirmithiy; 1159, ’Abū Dāwud; 2140. Ṣeek Albāniy sọ pé: Hadīth náà dára, ó ní àlàáfíà.) Ipò tí ìforíkanlẹ̀-kíni wà náà ni ìdọ̀bálẹ̀-kíni, ìkúnlẹ̀-kíni àti títẹ̀-kíni. Gbogbo ìwọ̀nyí ni kò lẹ́tọ̀ọ́ mọ́. Àṣà ìkíni tí ẹ̀sìn ’Islām faramọ́ ni sísálámọ̀ (ìyẹn ni, sí sọ pé “as-salām ‘aleekum warahmọtullāh wabarakātuh”) àti bíbọ ọwọ́ ní ibi tí ó ti ní ẹ̀tọ́.
2. ’Iblīs ni àlàjẹ́ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣaetọ̄n. Àwọn kan kà á mọ́ ara àwọn mọlāika. Wọ́n tún lérò pé Ṣaetọ̄n jẹ́ onímọ̀-jùlọ àti olùjọ́sìn-jùlọ láààrin àwọn mọlāika ṣíwájú kí ó tó di ẹni-ẹ̀kọ̀. Àmọ́ sá, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ẹyọ kan nínú àwọn àlùjànnú ni ’Iblīs, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Kahf; 18:50. Allāhu kò sì fi ìmọ̀ àti ìjọ́sìn ròyìn Ṣaetọ̄n rí.
അറബി ഖുർആൻ വിവരണങ്ങൾ:
 
പരിഭാഷ ആയത്ത്: (34) അദ്ധ്യായം: സൂറത്തുൽ ബഖറഃ
സൂറത്തുകളുടെ സൂചിക പേജ് നമ്പർ
 
വിശുദ്ധ ഖുർആൻ പരിഭാഷ - യോറുബൻ വിവർത്തനം - വിവർത്തനങ്ങളുടെ സൂചിക

വിശുദ്ധ ഖുർആൻ ആശയവിവർത്തനം (യോറുബൻ ഭാഷയിൽ). ശൈഖ് അബൂ റഹീമഃ മീകാഈൽ അയ്കൂബീനീ നടത്തിയ വിവർത്തനം. ഹി 1432 ലെ പതിപ്പ്.

അടക്കുക