Nítorí yíyẹ̀ tí wọ́n fúnra wọn yẹ àdéhùn wọn ni A fi ṣẹ́bi lé wọn. A sì mú ọkàn wọn le koko (nítorí pé), wọ́n ń gbé àwọn ọ̀rọ̀ kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì gbàgbé ìpín kan nínúoore tí A rán wọn létí rẹ̀. O ò níí yé rí oníjàǹbá láààrin wọn àfi díẹ̀ nínú wọn. Nítorí náà, ṣe àmójúkúrò fún wọn, kí o sì foríjìn wọ́n. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe-rere.
Àti pé lọ́dọ̀ àwọn tó wí pé: “Dájúdájú nasọ̄rọ̄ ni àwa.”, A gba àdéhùn lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì gbàgbé ìpín kan nínú oore tí A rán wọn létí rẹ̀. Nítorí náà, A dá ọ̀tá àti ọ̀tẹ̀ sáààrin wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Láìpẹ́ Allāhu máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn tó wí pé: “Dájúdájú Allāhu ni Mọsīh ọmọ Mọryam.” Sọ pé: “Ta ló ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu tí (Allāhu) bá fẹ́ pa Mọsīh ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé run pátápátá?” Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. (Allāhu) ń ṣẹ́dàá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ẹ̀yin onítírà, dájúdájú Òjíṣẹ́ Wa ti dé ba yín, tí ó ń ṣe àlàyé (ọ̀rọ̀) fún yín lẹ́yìn àsìkò tí A ti dá àwọn Òjísẹ́ dúró, nítorí kí ẹ má ṣe wí pé: “Kò sí oníròó ìdùnnú tàbí olùkìlọ̀ kan tí ó wá bá wa.” Nítorí náà, dájúdájú oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ kan ti wá ba yín. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ẹnì kan bí kò ṣe (lórí) ara mi àti arákùnrin mi. Nítorí náà, ya àwa àti ìjọ òbìlẹ̀jẹ́ sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”[1]
1. Ìyẹn ni pé, bí Allāhu bá fẹ́ fi ìyapa-àṣẹ tí wọ́n ṣe gbá wọn mú, má ṣe jẹ wá ní ìyà pẹ̀lú wọn. Àwọn ni wọ́n yapa àsẹ Rẹ, kì í ṣe àwa.
(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú ó ti di èèwọ̀ fún wọn (láti wọnú ìlú náà) fún ogójì ọdún tí wọn yóò fi rin àrìnnù lórí ilẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”[1]
Ka ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam méjèèjì fún wọn pẹ̀lú òdodo. (Rántí) nígbà tí àwọn méjèèjì ṣe ọrẹ àsè (láti fi súnmọ́ Allāhu). A gba ti ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì, A kò sì gba ti ìkejì. (Ẹni tí A kò gba tirẹ̀) wí pé: “Dájúdájú èmi yóò pa ọ́.” (Ìkejì) sì sọ pé: “(Ọrẹ àsè) tàwọn olùbẹ̀rù nìkan ni Allāhu máa gbà.
Dájúdájú tí o bá na ọwọ́ rẹ sí mi láti pa mí, èmi kò sì níí na ọwọ́ mi sí ọ láti pa ọ́, nítorí pé dájúdáju èmi ń bẹ̀rù Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Allāhu sì gbé ẹyẹ kannakánná kan dìde, tí ó ń fi ẹsẹ̀ walẹ̀ nítorí kí ó lè fi bí ó ṣe máa bo òkú[1] arákùnrin rẹ̀ mọ́ inú ilẹ̀ hàn án. Ó wí pé: “Tèmí bá mi o! Ṣé mo kágara ni láti dà bí irú ẹyẹ kannakánná yìí, kí èmi náà sì lè bo òkú arákùnrin mi mọ́lẹ̀?” Ó sì di ara àwọn alábàámọ̀.
1. “sao’ah” túmọ̀ sí ìhòhò, ohun tí ẹ̀dá kò fẹ́ fojú ara rẹ̀ rí. Òkú ti di sao’ah nítorí pé, kò sí ẹni tí ó fẹ́ fojú ara rẹ̀ rí òkú.
Ẹ̀san àwọn tó ń gbógun ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ ni pé, kí ẹ pa wọ́n tàbí kí ẹ kàn wọ́n mọ́ igi àgbélébùú tàbí kí ẹ gé ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn ní ìpasípayọ tàbí kí ẹ lé wọn kúrò nínú ìlú. Ìyẹn ni ìyẹpẹrẹ fún wọn nílé ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run.
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí ó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé pátápátá jẹ́ tiwọn àti irú rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti fi gba ara wọn sílẹ̀ níbi ìyà Ọjọ́ Àjíǹde, A ò níí gbà á ní ọwọ́ wọn. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sìwà fún wọn.
Ìwọ Òjíṣẹ́, má ṣe jẹ́ kí ó bà ọ́ nínú jẹ́ àwọn tó ń yára lọ sínú àìgbàgbọ́ nínú àwọn tó fi ẹnu ara wọn wí pé: “A gbàgbọ́.” - tí ọkàn wọn kò sì gbàgbọ́ ní òdodo - àti àwọn tó di yẹhudi, tí wọ́n ń tẹ́tí sí irọ́, tí wọ́n sì ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn mìíràn tí kò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, tí wọ́n ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “Tí wọ́n bá fún yín ní èyí ẹ gbà á. Tí wọn kò bá sì fún yín ẹ ṣọ́ra.”[1] Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ fòòró rẹ̀, o ò ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu fún un. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu kò fẹ́ fọ ọkàn wọn mọ́. Ìdójútì ń bẹ fún wọn ní ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run.
1. Àwọn yẹhudi rán ara wọn lọ bá Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láti bi í léèrè nípa ìdájọ́ onísìná tí ó ti ṣe ìgbéyàwó rí. Wọ́n sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ wọn pé tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bá pe ìdájọ́ rẹ̀ ní kòbókò àti kíkun ojú onísìná ní dúdú láti fi ṣẹ̀sín níta, kí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìdájọ́ yẹn. Àmọ́ tí ó bá pe ìdájọ́ rẹ̀ ní lílẹ̀lókòpa, ẹ ṣọ́ra fún un, kí ẹ má ṣe tẹ̀lé e.
Báwo ni wọ́n á ṣe fi ọ́ ṣe adájọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé at-Taorāh wà lọ́dọ̀ wọn. Ìdájọ́ Allāhu sì wà nínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n ń pẹ̀yìndà lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn wọ̀nyẹn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
Dájúdájú Àwa sọ at-Taorāh kalẹ̀. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ ń bẹ nínú rẹ̀. Àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí ń fi ṣe ìdájọ́ fún àwọn tó di yẹhudi. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn amòfin ẹ̀sìn (ń fi ṣe ìdájọ́) nítorí ohun tí A fún wọn ṣọ́ nínú tírà Allāhu. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe páyà ènìyàn. Ẹ páyà Mi. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi ní owó kékeré. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni aláìgbàgbọ́.
A fi ‘Īsā ọmọ Mọryam tẹ̀lé orípa wọn (ìyẹn, àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí); tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú rẹ̀ nínú at-Taorāh. A sì fún un ní al-’Injīl. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ wà nínú rẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú rẹ̀ nínú at-Taorāh. (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti wáàsí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu ní àsìkò tirẹ̀).
Àti pé kí o fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Ṣọ́ra fún wọn kí wọ́n má baà fòòró rẹ kúrò níbi apá kan ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Tí wọ́n bá sì gbúnrí, mọ̀ pé Allāhu kàn fẹ́ fi àdánwò kàn wọ́n ni nítorí apá kan ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Àti pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ènìyàn ni òbìlẹ̀jẹ́.
Sọ pé: “Ẹ̀yin onítírà, ǹjẹ́ ẹ rí àlèébù kan (ǹjẹ́ ẹ sì kórira kiní kan) lára wa bí kò ṣe pé a gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú àti (igbàgbọ́ wa pé) dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ yín ni òbìlẹ̀jẹ́?"
Nígbà tí wọ́n bá wá sí ọ̀dọ̀ yín, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Dájúdájú wọ́n wọlé (tì yín) pẹ̀lú àìgbàgbọ́, wọ́n sì ti jáde pẹ̀lú rẹ̀. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́.[1]
Kí ni kò jẹ́ kí àwọn àlùfáà àti àwọn amòfin ẹ̀sìn máa kọ̀ fún wọn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wọn (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ owó èrú! Dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
Àwọn yẹhudi wí pé: “Ọwọ́ Allāhu wà ní dídì pa.” A di ọwọ́ wọn pa. A sì ṣẹ́bi lé wọn nítorí ohun tí wọ́n wí. Ọ̀rọ̀ kò rí bí wọ́n ṣe sọ ọ́ bí kò ṣe pé, ọwọ́ Rẹ̀ méjèèjì wà ní títẹ́ sílẹ̀. Ó sì ń tọrẹ bí Ó ṣe fẹ́. Ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Rẹ̀ yóò kúkú jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lékún ní ìtayọ ẹnu ààlà àti àìgbàgbọ́ ni. A sì ju ọ̀tá àti ìkórira sáààrin wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá dáná ogun, Allāhu sì máa paná rẹ̀. Wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n lo at-Taorāh àti al-’Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn (ìyẹn, al-Ƙur’ān), wọn ìbá máa jẹ láti òkè wọn àti láti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ wọn. Ìjọ kan ń bẹ nínú wọn tó dúró déédé, (àmọ́) ohun tí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn ń ṣe níṣẹ́ burú.[1]
1. Ọ̀wọ́ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ìpèpè Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dé bá láyé, tí wọ́n sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Wọ́n sì gba ’Islām.
Ìwọ Òjíṣẹ́, kéde gbogbo ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Tí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò jẹ́ iṣẹ́ Rẹ̀ pé. Allāhu yó sì dáàbò bò ọ́ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́ (àwọn tí wọn kò fẹ́ mọ̀nà).
Sọ pé: “Ẹ̀yin onítírà, ẹ ò rí kiní kan ṣe (nínú ẹ̀sìn) títí ẹ máa fi lo at-Taorāh àti al-’Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín (ìyẹn, al-Ƙur’ān).” Ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Rẹ yóò kúkú jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lékún ní ìgbéraga àti àìgbàgbọ́ ni. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ aláìgbàgbọ́.
A kúkú gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. A sì rán àwọn Òjíṣẹ́ kan sí wọn. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ kan bá dé bá wọn pẹ̀lú ohun tí ẹ̀mí wọn kò fẹ́, wọ́n pe igun kan ní òpùrọ́, wọ́n sì ń pa igun kan.
Wọ́n sì lérò pé kò níí sí ìfòòró;[1] wọ́n fọ́jú, wọ́n sì dití (sí òdodo). Lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n fọ́jú, wọ́n tún dití (sí òdodo); ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn (ló ṣe bẹ́ẹ̀). Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Kí ni Mọsīh bí kò ṣe Òjíṣẹ́ kan. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti lọ ṣíwájú rẹ̀. Olódodo sì ni ìyá rẹ̀. Àwọn méjèèjì máa ń jẹ oúnjẹ. Wo bí A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún wọn. Lẹ́yìn náà, wo bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
O máa rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn tó ń bá àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ṣọ̀rẹ́. Ohun tí ẹ̀mí wọn tì síwájú fún wọn sì burú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Allāhu fi bínú sí wọn. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Ìyà.
Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, wọn kò níí mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn ni òbìlẹ̀jẹ́.
Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ náà, o máa rí ẹyinjú wọn tí ó máa damije nítorí ohun tí wọ́n ti mọ̀ nínú òdodo. Wọ́n á sì sọ pé: “Olúwa wa, a gbàgbọ́ ní òdodo, kọ wá mọ́ ara àwọn olùjẹ́rìí (òdodo).
Kí ni ó máa dí wa lọ́wọ́ tí a ò fi níí gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí ó dé bá wa nínú òdodo (ìyẹn, al-Ƙur’ān), tí a sì ń jẹ̀rankàn pé kí Olúwa wa fi wá sínú àwọn ẹni-ire.”
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀ wá síbi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. (Ẹ máa bọ̀ wá) sí ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ náà.”[1] Wọ́n á wí pé: “Ohun tí a bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ ti tó wa.” Ṣé pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn bàbá wọn kò nímọ̀ kan kan, tí wọn kò sì mọ̀nà?
Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti mú ẹ̀rí jíjẹ́ wá ní ojú-pọ̀nnà rẹ̀ tàbí láti (lè là nínú) ìpáyà pé wọ́n yóò da ìbúra kan nù (ìbúra ẹni méjì àkọ́kọ́) lẹ́yìn ìbúra tiwọn (ìbúrà ẹni méjì kejì). Ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì gbọ́ràn. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.[1]
1. Òfin yìí, òfin àsọọ́lẹ̀ lórí ogún, igun kan nínú àwọn onímọ̀ sọ pé, wọ́n ti pa ìdájọ́ rẹ̀ rẹ́, àmọ́ igun kejì sọ pé, wọn kò pa ìdájọ́ rẹ̀ rẹ́.
(Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, rántí ìdẹ̀ra Mi lórí rẹ àti lórí ìyá rẹ, nígbà tí Mo fi ẹ̀mí Mímọ́ (mọlāika Jibrīl) ràn ọ́ lọ́wọ́, tí o sì ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà tí o dàgbà. (Rántí) nígbà tí Mo fún ọ ní ìmọ̀ Tírà, òye ìjìnlẹ̀, at-Taorāh àti al-’Injīl. (Rántí) nígbà tí ò ń mọ n̄ǹkan láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ, tí ò ń fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀, tí ó ń di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. Ò ń wo afọ́jú àti adẹ́tẹ̀ sàn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. (Rántí) nígbà tí ò ń mú àwọn òkú jáde (ní alààyè láti inú sàréè) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. (Rántí) nígbà tí Mo dí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lọ́wọ́ fún ọ,[1] nígbà tí o mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn sì wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”
1. Allāhu Alágbára dí àwọn ọmọ Isrọ̄’īl lọ́wọ́ lórí pípa tí wọ́n fẹ́ pa Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Allāhu kò jẹ́ kí wọ́n rí i kàn mọ́ igi àgbélébùú, kò sì jẹ́ kí wọ́n rí i pa. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:157.
(Rántí) nígbà tí Mo fi mọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ[1] nínú ọkàn wọn pé kí wọ́n gbàgbọ́ nínú Èmi àti Òjíṣẹ́ Mi. Wọ́n sọ pé: “A gbàgbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá.”
Èmi kò sọ ohun kan fún wọn bí kò ṣe ohun tí O pa mí láṣẹ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín.” Mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí wọn níwọ̀n ìgbà tí mò ń bẹ láààrin wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí O gbà mí kúrò lọ́wọ́ wọn, Ìwọ ni Olùṣọ́ lórí wọn. Ìwọ sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.[1]
Contents of the translations can be downloaded and re-published, with the following terms and conditions:
1. No modification, addition, or deletion of the content.
2. Clearly referring to the publisher and the source (QuranEnc.com).
3. Mentioning the version number when re-publishing the translation.
4. Keeping the transcript information inside the document.
5. Notifying the source (QuranEnc.com) of any note on the translation.
6. Updating the translation according to the latest version issued from the source (QuranEnc.com).
7. Inappropriate advertisements must not be included when displaying translations of the meanings of the Noble Quran.
തിരയൽ ഫലങ്ങൾ:
API specs
Endpoints:
Sura translation
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/sura/{translation_key}/{sura_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified sura (by its number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114)
Returns:
json object containing array of objects, each object contains the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/aya/{translation_key}/{sura_number}/{aya_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified aya (by its number sura_number and aya_number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114) aya_number: [1-...] (Aya number in the sura)
Returns:
json object containing the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".