വിശുദ്ധ ഖുർആൻ പരിഭാഷ - യോറുബൻ വിവർത്തനം * - വിവർത്തനങ്ങളുടെ സൂചിക

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

പരിഭാഷ ആയത്ത്: (9) അദ്ധ്യായം: സൂറത്തുൽ അൻആം
وَلَوۡ جَعَلۡنَٰهُ مَلَكٗا لَّجَعَلۡنَٰهُ رَجُلٗا وَلَلَبَسۡنَا عَلَيۡهِم مَّا يَلۡبِسُونَ
Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe é ní mọlāika ni, Àwa ìbá ṣe é ní ọkùnrin. Àti pé Àwa ìbá tún fi ohun tí wọ́n ń darú mọ́ra wọn lójú rú wọn lójú.¹
1. Ìyẹn ni pé, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ wọ̀nyẹn ti da ọ̀rọ̀ rú mọ́ra wọn lọ́wọ́ lórí ṣíṣà tí Allāhu ṣa Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́ṣà láààrin wọn, ẹni tí àwọn náà jẹ́rìí sí jíjẹ́ olódodo àti olùfọkàntán rẹ̀ ṣíwájú kí ó tó di Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, tí wọ́n sì ń sọ ìsọkúsọ sí i lóríṣiríṣi lọ́nà àìtọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe máa dojú ọ̀rọ̀ rú mọ́ra wọn lọ́wọ́ tí ó bá jẹ́ pé mọlāika kan ni Allāhu ní kí ó jẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ̀ láààrin wọn nítorí pé, àwọn tí wọn kò gbàgbọ́ nínú ènìyàn tí wọ́n mọ ìtàn ìgbésí-ayé rẹ̀ sí òdodo àti ìfọkàntán, wọn kò níí wulẹ̀ gbàgbọ́ pàápàá nínú mọlāika tí wọn kò mọ n̄ǹkan kan nípa ìtàn ìgbésí-ayé rẹ̀.
അറബി ഖുർആൻ വിവരണങ്ങൾ:
 
പരിഭാഷ ആയത്ത്: (9) അദ്ധ്യായം: സൂറത്തുൽ അൻആം
സൂറത്തുകളുടെ സൂചിക പേജ് നമ്പർ
 
വിശുദ്ധ ഖുർആൻ പരിഭാഷ - യോറുബൻ വിവർത്തനം - വിവർത്തനങ്ങളുടെ സൂചിക

വിശുദ്ധ ഖുർആൻ ആശയവിവർത്തനം (യോറുബൻ ഭാഷയിൽ). ശൈഖ് അബൂ റഹീമഃ മീകാഈൽ അയ്കൂബീനീ നടത്തിയ വിവർത്തനം. ഹി 1432 ലെ പതിപ്പ്.

അടക്കുക