Check out the new design

Vertaling van de betekenissen Edele Qur'an - Yoruba vertaling - Aboe Rahimah Mikail * - Index van vertaling

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Vertaling van de betekenissen Surah: Fussilat   Vers:

Fussilat

حمٓ
Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
Arabische uitleg van de Qur'an:
تَنزِيلٞ مِّنَ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
Ìmísí kan (nìyí) tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Arabische uitleg van de Qur'an:
كِتَٰبٞ فُصِّلَتۡ ءَايَٰتُهُۥ قُرۡءَانًا عَرَبِيّٗا لِّقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ
Tírà kan ni tí wọ́n ṣàlàyé àwọn āyah inú rẹ̀,[1] (ó ń jẹ́) al-Ƙur’ān (tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ ní) èdè Lárúbáwá fún ìjọ tó nímọ̀.
1. Ìtúmọ̀ mìíràn “Tírà kan ni tí wọ́n pín àwọn āyah inú rẹ̀ sínú àwọn sūrah.”
Arabische uitleg van de Qur'an:
بَشِيرٗا وَنَذِيرٗا فَأَعۡرَضَ أَكۡثَرُهُمۡ فَهُمۡ لَا يَسۡمَعُونَ
(Ó jẹ́) ìró-ìdùnnú àti ìkìlọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn gbúnrí kúrò níbẹ̀. Wọn kò sì tẹ́tí sí i.
Arabische uitleg van de Qur'an:
وَقَالُواْ قُلُوبُنَا فِيٓ أَكِنَّةٖ مِّمَّا تَدۡعُونَآ إِلَيۡهِ وَفِيٓ ءَاذَانِنَا وَقۡرٞ وَمِنۢ بَيۡنِنَا وَبَيۡنِكَ حِجَابٞ فَٱعۡمَلۡ إِنَّنَا عَٰمِلُونَ
Wọ́n sì wí pé: “Ọkàn wa wà ní títì pa sí ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí. Èdídí sì wà nínú etí wa. Àti pé gàgá wà láààrin àwa àti ìwọ. Nítorí náà, máa ṣe tìrẹ. Dájúdájú àwa náà ń ṣe tiwa.”
Arabische uitleg van de Qur'an:
قُلۡ إِنَّمَآ أَنَا۠ بَشَرٞ مِّثۡلُكُمۡ يُوحَىٰٓ إِلَيَّ أَنَّمَآ إِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ فَٱسۡتَقِيمُوٓاْ إِلَيۡهِ وَٱسۡتَغۡفِرُوهُۗ وَوَيۡلٞ لِّلۡمُشۡرِكِينَ
Sọ pé: “Abara bí irú yín kúkú ni èmi náà. Wọ́n ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi ni, pé Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin tì Í (nínú ìjọ́sìn), kí ẹ sì tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ègbé sì ni fún àwọn ọ̀ṣẹbọ.
Arabische uitleg van de Qur'an:
ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَهُم بِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ كَٰفِرُونَ
Àwọn tí kò yọ Zakāh, àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.[1]
1. Bí āyah yìí bá sọpọ̀ mọ́ āyah tí ó ṣíwájú rẹ̀, “zakāh” máa dúró fún àfọ̀mọ́ ọkàn àti àfọ̀mọ́ ara. Àmọ́ tí āyah yìí bá dádúró, “zakāh” máa túmọ̀ sí àfọ̀mọ́ dúkìá.
Arabische uitleg van de Qur'an:
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمۡ أَجۡرٌ غَيۡرُ مَمۡنُونٖ
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pẹ̀dín tí kò níí dáwọ́ dúró ń bẹ fún wọn.
Arabische uitleg van de Qur'an:
۞ قُلۡ أَئِنَّكُمۡ لَتَكۡفُرُونَ بِٱلَّذِي خَلَقَ ٱلۡأَرۡضَ فِي يَوۡمَيۡنِ وَتَجۡعَلُونَ لَهُۥٓ أَندَادٗاۚ ذَٰلِكَ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Sọ pé: “Ṣé dájúdájú ẹ̀yin máa ṣàì gbàgbọ́ nínú Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ilẹ̀ fún ọjọ́ méjì, ẹ sì ń sọ (ẹ̀dá Rẹ̀) di akẹgbẹ́ Rẹ̀ (tí ẹ̀ ń bọ wọ́n)?” Ìyẹn (Ẹlẹ́dàá ilẹ̀) sì ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Arabische uitleg van de Qur'an:
وَجَعَلَ فِيهَا رَوَٰسِيَ مِن فَوۡقِهَا وَبَٰرَكَ فِيهَا وَقَدَّرَ فِيهَآ أَقۡوَٰتَهَا فِيٓ أَرۡبَعَةِ أَيَّامٖ سَوَآءٗ لِّلسَّآئِلِينَ
Ó sì fi àwọn àpáta sínú ilẹ̀ láti òkè rẹ̀. Ó fi ìbùkún sínú rẹ̀. Ó sì pèbùbù àwọn arísìkí (àti ohun àmúsọrọ̀) sínú rẹ̀ láààrin ọjọ́ mẹ́rin.[1] (Àwọn ọjọ́ náà) dọ́gba (síra wọn) fún àwọn olùbèèrè (nípa rẹ̀).
1. Bí Allāhu ṣe gbàròyìn pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”, bẹ́ẹ̀ náà l’Ó ṣe gbàròyìn pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, èyí tí í ṣe ìdà kejì ìkánjú. Nítorí náà, Allāhu lágbára láti ṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run láààrin ohun tí ó kéré jùlọ sí ìṣẹ́jú kan. Bí Allāhu bá sì lo òǹkà ọjọ́ kan fún ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé àṣẹ “Jẹ́-bẹ́ẹ̀” kò jẹ́ tiRẹ̀. Ọba Aṣèyí-ó-wù-Ú ni.
Arabische uitleg van de Qur'an:
ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰٓ إِلَى ٱلسَّمَآءِ وَهِيَ دُخَانٞ فَقَالَ لَهَا وَلِلۡأَرۡضِ ٱئۡتِيَا طَوۡعًا أَوۡ كَرۡهٗا قَالَتَآ أَتَيۡنَا طَآئِعِينَ
Lẹ́yìn náà, Allāhu wà ní òkè sánmọ̀, nígbà tí sánmọ̀ wà ní èéfín. Ó sì sọ fún òhun àti ilẹ̀ pé: “Ẹ wá bí ẹ fẹ́ tàbí ẹ kọ̀.” Àwọn méjèèjì sọ pé: “A wá pẹ̀lú ìfínnú-fíndọ̀.”[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Anbiyā’; 21:30.
Arabische uitleg van de Qur'an:
 
Vertaling van de betekenissen Surah: Fussilat
Surah's Index Pagina nummer
 
Vertaling van de betekenissen Edele Qur'an - Yoruba vertaling - Aboe Rahimah Mikail - Index van vertaling

Vertaald door Sheikh Aboe Rahimah Mikail Aikoweini.

Sluit