Vertaling van de betekenissen Edele Qur'an - Yoruba vertaling * - Index van vertaling

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Vertaling van de betekenissen Surah: Soerat Al-Monaafiqoen (De Huichelaars)   Vers:

Suuratul-Munaafikuun

إِذَا جَآءَكَ ٱلۡمُنَٰفِقُونَ قَالُواْ نَشۡهَدُ إِنَّكَ لَرَسُولُ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ إِنَّكَ لَرَسُولُهُۥ وَٱللَّهُ يَشۡهَدُ إِنَّ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ لَكَٰذِبُونَ
Nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí bá wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n á wí pé: “À ń jẹ́rìí pé dájúdájú ìwọ, Òjíṣẹ́ Allāhu ni ọ́.” Allāhu sì mọ̀ pé dájúdájú ìwọ, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ọ́. Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, òpùrọ́ ni wọ́n.
Arabische uitleg van de Qur'an:
ٱتَّخَذُوٓاْ أَيۡمَٰنَهُمۡ جُنَّةٗ فَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِۚ إِنَّهُمۡ سَآءَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Wọ́n fi àwọn ìbúra wọn ṣe ààbò (fún ẹ̀mí ara wọn), wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu; dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
Arabische uitleg van de Qur'an:
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ ءَامَنُواْ ثُمَّ كَفَرُواْ فَطُبِعَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ فَهُمۡ لَا يَفۡقَهُونَ
(Wọ́n ṣe) ìyẹn nítorí pé, wọ́n gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, A ti fi èdídí dí ọkàn wọn; wọn kò sì níí gbọ́ àgbọ́yé.
Arabische uitleg van de Qur'an:
۞ وَإِذَا رَأَيۡتَهُمۡ تُعۡجِبُكَ أَجۡسَامُهُمۡۖ وَإِن يَقُولُواْ تَسۡمَعۡ لِقَوۡلِهِمۡۖ كَأَنَّهُمۡ خُشُبٞ مُّسَنَّدَةٞۖ يَحۡسَبُونَ كُلَّ صَيۡحَةٍ عَلَيۡهِمۡۚ هُمُ ٱلۡعَدُوُّ فَٱحۡذَرۡهُمۡۚ قَٰتَلَهُمُ ٱللَّهُۖ أَنَّىٰ يُؤۡفَكُونَ
Nígbà tí o bá rí wọn, ìrísí wọn yóò jọ ọ́ lójú. Tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, ìwọ yóò tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n sì dà bí igi tí wọ́n gbé ti ògiri.¹ Wọ́n sì ń lérò pé gbogbo igbe (ìbòsí) ń bẹ lórí wọn (nípa ìṣọ̀bẹ-ṣèlu wọn).² Ọ̀tá ni wọ́n. Nítorí náà, ṣọ́ra fún wọn. Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
1. Ìyẹn ni pé, kò sí èso kan tí igi wọn máa so. Ó ti di òkú igi.
2. Gbólóhùn yìí jọ sūrah at-Taobah; 9:127.
Arabische uitleg van de Qur'an:
وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ تَعَالَوۡاْ يَسۡتَغۡفِرۡ لَكُمۡ رَسُولُ ٱللَّهِ لَوَّوۡاْ رُءُوسَهُمۡ وَرَأَيۡتَهُمۡ يَصُدُّونَ وَهُم مُّسۡتَكۡبِرُونَ
Àti pé nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ wá kí Òjíṣẹ́ ba yín tọrọ àforíjìn.” Wọ́n á gbúnrí. O sì máa rí wọn tí wọn yóò máa gbúnrí lọ, tí wọn yóò máa ṣègbéraga.
Arabische uitleg van de Qur'an:
سَوَآءٌ عَلَيۡهِمۡ أَسۡتَغۡفَرۡتَ لَهُمۡ أَمۡ لَمۡ تَسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ لَن يَغۡفِرَ ٱللَّهُ لَهُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡفَٰسِقِينَ
Bákan náà ni fún wọn; yálà o bá wọn tọrọ àforíjìn tàbí o ò bá wọn tọrọ àforíjìn.¹ Allāhu kò níí foríjìn wọ́n. Dájúdájú Allāhu kò nií fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
1. Fún àlàyé lórí āyah yìí, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah at-Taobah; 9:80.
Arabische uitleg van de Qur'an:
هُمُ ٱلَّذِينَ يَقُولُونَ لَا تُنفِقُواْ عَلَىٰ مَنۡ عِندَ رَسُولِ ٱللَّهِ حَتَّىٰ يَنفَضُّواْۗ وَلِلَّهِ خَزَآئِنُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلَٰكِنَّ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ لَا يَفۡقَهُونَ
Àwọn ni àwọn tó ń wí pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ ná owó fún àwọn tó wà lọ́dọ̀ Ójíṣẹ́ Allāhu títí wọn yóò fi fọ́nká. Ti Allāhu sì ni àwọn ilé ọrọ̀ sánmọ̀ àti ilẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò gbọ́ àgbọ́yé.
Arabische uitleg van de Qur'an:
يَقُولُونَ لَئِن رَّجَعۡنَآ إِلَى ٱلۡمَدِينَةِ لَيُخۡرِجَنَّ ٱلۡأَعَزُّ مِنۡهَا ٱلۡأَذَلَّۚ وَلِلَّهِ ٱلۡعِزَّةُ وَلِرَسُولِهِۦ وَلِلۡمُؤۡمِنِينَ وَلَٰكِنَّ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ لَا يَعۡلَمُونَ
Wọ́n ń wí pé: “Dájúdájú tí a bá padà dé sínú ìlú Mọdīnah, ńṣe ni àwọn alágbára (ìlú) yóò yọ àwọn ẹni yẹpẹrẹ jáde kúrò nínú ìlú.” Agbára sì ń jẹ́ ti Allāhu, àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, ṣùgbọ́n àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò mọ̀.
Arabische uitleg van de Qur'an:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تُلۡهِكُمۡ أَمۡوَٰلُكُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُكُمۡ عَن ذِكۡرِ ٱللَّهِۚ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín kó àìrójú ba yín níbi ìrántí Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kó sínú (àìrójú) yẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò.
Arabische uitleg van de Qur'an:
وَأَنفِقُواْ مِن مَّا رَزَقۡنَٰكُم مِّن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَ أَحَدَكُمُ ٱلۡمَوۡتُ فَيَقُولَ رَبِّ لَوۡلَآ أَخَّرۡتَنِيٓ إِلَىٰٓ أَجَلٖ قَرِيبٖ فَأَصَّدَّقَ وَأَكُن مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ
Ẹ ná nínú ohun tí A pèsè fún yín ṣíwájú kí ikú tó dé bá ẹnì kan yín, kí ó wá wí pé: “Olúwa mi, kí ó sì jẹ́ pé O lọ́ mi lára sí i títí di ìgbà kan tó súnmọ́, èmi ìbá sì lè máa tọrẹ, èmi ìbá sì wà lára àwọn ẹni rere.”
Arabische uitleg van de Qur'an:
وَلَن يُؤَخِّرَ ٱللَّهُ نَفۡسًا إِذَا جَآءَ أَجَلُهَاۚ وَٱللَّهُ خَبِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ
Allāhu kò sì níí lọ́ ẹ̀mí kan lára nígbà tí ọjọ́ ikú rẹ̀ bá dé. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Arabische uitleg van de Qur'an:
 
Vertaling van de betekenissen Surah: Soerat Al-Monaafiqoen (De Huichelaars)
Surah's Index Pagina nummer
 
Vertaling van de betekenissen Edele Qur'an - Yoruba vertaling - Index van vertaling

betekenissen in Yoruba door Abu Rahima Mikhail Aikweiny, gedrukt in 1432 H.

Sluit