Check out the new design

د قرآن کریم د معناګانو ژباړه - یورباوي ژباړه - أبو رحیمة میکائیل * - د ژباړو فهرست (لړلیک)

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

د معناګانو ژباړه آیت: (100) سورت: یوسف
وَرَفَعَ أَبَوَيۡهِ عَلَى ٱلۡعَرۡشِ وَخَرُّواْ لَهُۥ سُجَّدٗاۖ وَقَالَ يَٰٓأَبَتِ هَٰذَا تَأۡوِيلُ رُءۡيَٰيَ مِن قَبۡلُ قَدۡ جَعَلَهَا رَبِّي حَقّٗاۖ وَقَدۡ أَحۡسَنَ بِيٓ إِذۡ أَخۡرَجَنِي مِنَ ٱلسِّجۡنِ وَجَآءَ بِكُم مِّنَ ٱلۡبَدۡوِ مِنۢ بَعۡدِ أَن نَّزَغَ ٱلشَّيۡطَٰنُ بَيۡنِي وَبَيۡنَ إِخۡوَتِيٓۚ إِنَّ رَبِّي لَطِيفٞ لِّمَا يَشَآءُۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ
Ó gbé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì sórí ìtẹ́. Wọ́n sì wó lulẹ̀ fún un, tí wọ́n forí kanlẹ̀ kí i.[1] Ó sọ pé: “Bàbá mi, èyí ni ìtúmọ̀ àlá mi (tí mo lá) ṣíwájú. Dájúdájú Olúwa mi ti sọ ọ́ di òdodo. Ó sì ṣe dáadáa fún mi nígbà tí Ó mú mi jáde kúrò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ó tún mu yín wá (bá mi) láti inú oko lẹ́yìn tí aṣ-Ṣaetọ̄n ti saburú sáààrin èmi àti àwọn ọbà-kan mi. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláàánú fún ohun tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
[1] Ní àsìkò náà, kò lòdì sí òfin tí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - fún Ànábì Ya'ƙūb àti àwọn ọmọ rẹ̀ - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - láti fi ìdọ̀bálẹ̀ àti ìkúnlẹ̀ kí ẹnikẹ́ni. Àmọ́ nínú òfin tí Allāhu fún Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó ti di èèwọ̀ láti fi ìdọ̀bálẹ̀ àti ìkúnlẹ̀ kí ẹnikẹ́ni. Ẹ wọ ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:34.
عربي تفسیرونه:
 
د معناګانو ژباړه آیت: (100) سورت: یوسف
د سورتونو فهرست (لړلیک) د مخ نمبر
 
د قرآن کریم د معناګانو ژباړه - یورباوي ژباړه - أبو رحیمة میکائیل - د ژباړو فهرست (لړلیک)

ژباړوونکی: شیخ أبو رحیمة میکائیل ایکوییني.

بندول