Përkthimi i kuptimeve të Kuranit Fisnik - Përkthimi në gjuhën joruba * - Përmbajtja e përkthimeve

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Përkthimi i kuptimeve Ajeti: (23) Surja: Suretu Et Tevbe
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَّخِذُوٓاْ ءَابَآءَكُمۡ وَإِخۡوَٰنَكُمۡ أَوۡلِيَآءَ إِنِ ٱسۡتَحَبُّواْ ٱلۡكُفۡرَ عَلَى ٱلۡإِيمَٰنِۚ وَمَن يَتَوَلَّهُم مِّنكُمۡ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّٰلِمُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn bàbá yín àti àwọn arakùnrin yín ní ọ̀rẹ́ àyò bí wọ́n bá gbọ́lá fún àìgbàgbọ́ lórí ìgbàgbọ́ òdodo. Ẹnikẹ́ni tó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò nínú yín, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí.¹
1. Nínú sūrah al-’Isrọ̄’; 17:23 - 24, sūrah Luƙmọ̄n; 31:14 - 15 àti sūrah al-’Ankabūt; 29:8, Allāhu - Subhānahu - pa ọmọ láṣẹ láti ṣe rere sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì, kódà kí àwọn méjèèjì jẹ́ aláìgbàgbọ́ tàbí ọ̀ṣẹbọ. Àmọ́ ìyàtọ̀ wà láààrin ṣíṣe rere sí òbí àti títẹ̀lé àṣẹ òbí lórí ohun tó yapa sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ìdí nìyí tí àwọn sūrah at-Taobah; 9:23 àti sūrah al-Mujādilah; 58:22 fi ń ṣe é ní èèwọ̀ fún àwọn ọmọ láti tẹ̀lé àṣẹ òbí wọn nígbà tí àṣẹ wọn bá ti jẹmọ́ ìbọ̀rìṣà, àìgbàgbọ́ àti ìyapa àṣẹ Òjíṣẹ́ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tàbí ṣíṣe bid'ah. Nítorí náà, ọmọ ní ẹ̀tọ́ láti ṣe rere sí òbí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ní ẹ̀tọ́ láti kọ̀rọ̀ sí òbí rẹ̀ lẹ́nu nígbà tí wọ́n bá páṣẹ tó yapa sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ fún un. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ìṣẹ̀yá-ṣẹbàbá.
Tefsiret në gjuhën arabe:
 
Përkthimi i kuptimeve Ajeti: (23) Surja: Suretu Et Tevbe
Përmbajtja e sureve Numri i faqes
 
Përkthimi i kuptimeve të Kuranit Fisnik - Përkthimi në gjuhën joruba - Përmbajtja e përkthimeve

Përkthimi i kuptimeve të Kuranit në jorubishte - Përkthyer nga Ebu Rahime Ajkojini - Viti i botimit: 1432 h.

Mbyll