Check out the new design

அல்குர்ஆன் மொழிபெயர்ப்பு - யொரூபா மொழிபெயர்ப்பு - அபூ ரஹீமா மிக்கேல் * - மொழிபெயர்ப்பு அட்டவணை

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

மொழிபெயர்ப்பு அத்தியாயம்: அல்இஸ்ரா   வசனம்:
عَسَىٰ رَبُّكُمۡ أَن يَرۡحَمَكُمۡۚ وَإِنۡ عُدتُّمۡ عُدۡنَاۚ وَجَعَلۡنَا جَهَنَّمَ لِلۡكَٰفِرِينَ حَصِيرًا
Ó lè jẹ́ pé Olúwa yín máa ṣààánú yín. Tí ẹ bá sì padà (síbi ẹ̀ṣẹ̀), A máa padà (síbi ẹ̀san). A sì ṣe iná Jahanamọ ní ẹ̀wọ̀n fún àwọn aláìgbàgbọ́.
அரபு விரிவுரைகள்:
إِنَّ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانَ يَهۡدِي لِلَّتِي هِيَ أَقۡوَمُ وَيُبَشِّرُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ أَنَّ لَهُمۡ أَجۡرٗا كَبِيرٗا
Dájúdájú al-Ƙur’ān yìí, ó ń fini mọ̀nà sí ọ̀nà tààrà, ó sì ń fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san tó tóbi wà fún wọn.
அரபு விரிவுரைகள்:
وَأَنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ أَعۡتَدۡنَا لَهُمۡ عَذَابًا أَلِيمٗا
Dájúdájú àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́, A ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ dè wọ́n.
அரபு விரிவுரைகள்:
وَيَدۡعُ ٱلۡإِنسَٰنُ بِٱلشَّرِّ دُعَآءَهُۥ بِٱلۡخَيۡرِۖ وَكَانَ ٱلۡإِنسَٰنُ عَجُولٗا
Ènìyàn ń tọrọ aburú bí ó ṣe ń tọrọ ohun rere; ènìyàn sì jẹ́ olùkánjú.[1]
1. Ìyẹn ni pé, ènìyàn ń yára ṣépè lásìkò ìbínú. Ó sì yẹ kó ṣe sùúrù ni.
அரபு விரிவுரைகள்:
وَجَعَلۡنَا ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ ءَايَتَيۡنِۖ فَمَحَوۡنَآ ءَايَةَ ٱلَّيۡلِ وَجَعَلۡنَآ ءَايَةَ ٱلنَّهَارِ مُبۡصِرَةٗ لِّتَبۡتَغُواْ فَضۡلٗا مِّن رَّبِّكُمۡ وَلِتَعۡلَمُواْ عَدَدَ ٱلسِّنِينَ وَٱلۡحِسَابَۚ وَكُلَّ شَيۡءٖ فَصَّلۡنَٰهُ تَفۡصِيلٗا
A ṣe alẹ́ àti ọ̀sán ní àmì méjì; A pa àmì alẹ́ rẹ́, A sì ṣe àmì ọ̀sán ní ìríran[1] nítorí kí ẹ lè wá oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò (àwọn ọjọ́). Gbogbo n̄ǹkan ni A ti ṣàlàyé rẹ̀ ní ìfọ́síwẹ́wẹ́.²
1. Àmì alẹ́ ni òṣùpá, àmì ọ̀sán ni òòrùn. 2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:114.
அரபு விரிவுரைகள்:
وَكُلَّ إِنسَٰنٍ أَلۡزَمۡنَٰهُ طَٰٓئِرَهُۥ فِي عُنُقِهِۦۖ وَنُخۡرِجُ لَهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ كِتَٰبٗا يَلۡقَىٰهُ مَنشُورًا
Ènìyàn kọ̀ọ̀kan, A ti so iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mọ́ ọn lọ́rùn. A sì máa mú ìwé kan jáde fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó máa pàdé rẹ̀ ní ṣíṣí sílẹ̀.
அரபு விரிவுரைகள்:
ٱقۡرَأۡ كِتَٰبَكَ كَفَىٰ بِنَفۡسِكَ ٱلۡيَوۡمَ عَلَيۡكَ حَسِيبٗا
Ka ìwé (iṣẹ́) rẹ. Ìwọ ti tó ní olùṣírò fún ẹ̀mí ara rẹ lónìí.
அரபு விரிவுரைகள்:
مَّنِ ٱهۡتَدَىٰ فَإِنَّمَا يَهۡتَدِي لِنَفۡسِهِۦۖ وَمَن ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيۡهَاۚ وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٞ وِزۡرَ أُخۡرَىٰۗ وَمَا كُنَّا مُعَذِّبِينَ حَتَّىٰ نَبۡعَثَ رَسُولٗا
Ẹnikẹ́ni tó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tó bá sì ṣìnà, ó ń ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn.[1] A ò sì níí jẹ àwọn ẹ̀dá níyà títí A fi máa gbé òjíṣẹ́ kan dìde (sí wọn).
1. Bẹ́ẹ̀ ni àyàfi tí ó bá jẹ́ òun ni onísábàbí rẹ̀ ní ìbámu sí sūrah al-‘Ankabūt; 29:13.
அரபு விரிவுரைகள்:
وَإِذَآ أَرَدۡنَآ أَن نُّهۡلِكَ قَرۡيَةً أَمَرۡنَا مُتۡرَفِيهَا فَفَسَقُواْ فِيهَا فَحَقَّ عَلَيۡهَا ٱلۡقَوۡلُ فَدَمَّرۡنَٰهَا تَدۡمِيرٗا
Nígbà tí A bá sì gbèrò láti pa ìlú kan run, A máa pa àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà láṣẹ (rere). Àmọ́ wọ́n máa ṣèbàjẹ́ sínú ìlú. Ọ̀rọ̀ náà yó sì kò lé wọn lórí. A ó sì pa wọ́n rẹ́ pátápátá.[1]
1. Āyah yìí jọ sūrah al-’Ani‘ām; 6:123.
அரபு விரிவுரைகள்:
وَكَمۡ أَهۡلَكۡنَا مِنَ ٱلۡقُرُونِ مِنۢ بَعۡدِ نُوحٖۗ وَكَفَىٰ بِرَبِّكَ بِذُنُوبِ عِبَادِهِۦ خَبِيرَۢا بَصِيرٗا
Mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parun lẹ́yìn (Ànábì) Nūh! Olúwa rẹ tó ní Alámọ̀tán, Olùríran nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹrúsìn Rẹ̀.
அரபு விரிவுரைகள்:
 
மொழிபெயர்ப்பு அத்தியாயம்: அல்இஸ்ரா
அத்தியாயங்களின் அட்டவணை பக்க எண்
 
அல்குர்ஆன் மொழிபெயர்ப்பு - யொரூபா மொழிபெயர்ப்பு - அபூ ரஹீமா மிக்கேல் - மொழிபெயர்ப்பு அட்டவணை

அஷ்ஷேய்க். அபூ ரஹீமா மிக்கேள் எக்வீணி மொழிபெயர்த்தார்.

மூடுக