Check out the new design

அல்குர்ஆன் மொழிபெயர்ப்பு - யொரூபா மொழிபெயர்ப்பு - அபூ ரஹீமா மிக்கேல் * - மொழிபெயர்ப்பு அட்டவணை

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

மொழிபெயர்ப்பு அத்தியாயம்: தாஹா   வசனம்:

Toohaa

طه
Tọ̄ hā. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
அரபு விரிவுரைகள்:
مَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡقُرۡءَانَ لِتَشۡقَىٰٓ
A kò sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ láti kó wàhálà bá ọ.
அரபு விரிவுரைகள்:
إِلَّا تَذۡكِرَةٗ لِّمَن يَخۡشَىٰ
Bí kò ṣe pé ó jẹ́ ìrántí fún ẹni tó ń páyà (Allāhu).
அரபு விரிவுரைகள்:
تَنزِيلٗا مِّمَّنۡ خَلَقَ ٱلۡأَرۡضَ وَٱلسَّمَٰوَٰتِ ٱلۡعُلَى
(Ó jẹ́) ìmísí tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí Ó dá ilẹ̀ àti àwọn sánmọ̀ gíga.
அரபு விரிவுரைகள்:
ٱلرَّحۡمَٰنُ عَلَى ٱلۡعَرۡشِ ٱسۡتَوَىٰ
Àjọkẹ́-ayé gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá.
அரபு விரிவுரைகள்:
لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا وَمَا تَحۡتَ ٱلثَّرَىٰ
TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀, ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì àti ohunkóhun tó wà lábẹ́ ilẹ̀.
அரபு விரிவுரைகள்:
وَإِن تَجۡهَرۡ بِٱلۡقَوۡلِ فَإِنَّهُۥ يَعۡلَمُ ٱلسِّرَّ وَأَخۡفَى
Tí o bá sọ ọ̀rọ̀ jáde, dájúdájú (Allāhu) mọ ìkọ̀kọ̀ àti ohun tí ó (tún) pamọ́ jùlọ.
அரபு விரிவுரைகள்:
ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ لَهُ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰ
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. TiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ.
அரபு விரிவுரைகள்:
وَهَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ مُوسَىٰٓ
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā dé ọ̀dọ̀ rẹ?
அரபு விரிவுரைகள்:
إِذۡ رَءَا نَارٗا فَقَالَ لِأَهۡلِهِ ٱمۡكُثُوٓاْ إِنِّيٓ ءَانَسۡتُ نَارٗا لَّعَلِّيٓ ءَاتِيكُم مِّنۡهَا بِقَبَسٍ أَوۡ أَجِدُ عَلَى ٱلنَّارِ هُدٗى
(Rántí) nígbà tí ó rí iná kan, ó sọ fún àwọn ará ilé rẹ̀ pé: “Ẹ dúró síbí. Dájúdájú èmi rí iná kan. Ó ṣeé ṣe kí n̄g rí ògúnná mú wá fún yín nínú rẹ̀ tàbí kí n̄g rí ojú ọ̀nà kan nítòsí iná náà.”
அரபு விரிவுரைகள்:
فَلَمَّآ أَتَىٰهَا نُودِيَ يَٰمُوسَىٰٓ
Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pè é “Mūsā,
அரபு விரிவுரைகள்:
إِنِّيٓ أَنَا۠ رَبُّكَ فَٱخۡلَعۡ نَعۡلَيۡكَ إِنَّكَ بِٱلۡوَادِ ٱلۡمُقَدَّسِ طُوٗى
Dájúdájú Èmi ni Olúwa rẹ. Nítorí náà, bọ́ bàtà rẹ méjèèjì sílẹ̀.[1] Dájúdájú ìwọ wà ní àfonífojì mímọ́, Tuwā.
1. Ìdí tí Allāhu - tó ga jùlọ - fi pa á láṣẹ fún Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - láti bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọmọ Mọs‘ūd - kí Allāhu yọ́nú sí i - ṣe gbà á wá ni pé, awọ òkúǹbete kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọn kò pa lósè ni wọ́n fi ṣe bàtà náà.
அரபு விரிவுரைகள்:
 
மொழிபெயர்ப்பு அத்தியாயம்: தாஹா
அத்தியாயங்களின் அட்டவணை பக்க எண்
 
அல்குர்ஆன் மொழிபெயர்ப்பு - யொரூபா மொழிபெயர்ப்பு - அபூ ரஹீமா மிக்கேல் - மொழிபெயர்ப்பு அட்டவணை

அஷ்ஷேய்க். அபூ ரஹீமா மிக்கேள் எக்வீணி மொழிபெயர்த்தார்.

மூடுக